Retired head teacher found in Lagos: Ìyá tíṣà tó sọnù ní Ajegunle di rírí padà lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Olukọfẹyinti kan ti orukọ rẹ n jẹ Rachael Afolabi to di awati lẹyin to lọ bẹ ọmọ rẹ obinrin wo lagbegbe Ajegunlẹ nilu Eko ti di riri.
Ni ọjọ kejidinlogun osu kejila ni arabinrin Rachael Afọlabi fi agbegbe Orodu ni Ajegunle silẹ lati lọ ki ọkan lara awọn ọmọ rẹ obinrin to n gbe ni agbegbe Oluwa ni Ajegunlẹ kan naa.
Iroyin sọ pe arabinrin ẹni ọdun marundinlaadọrin naa mu ọmọ rẹ obinrin miran lọwọ ni irinajo rẹ naa ṣugbọn ọkada ọtọọtọ ni wọn wọ.
Ikorita Tolu Medical ni awọn ọkada naa ti yapa gba ọna ọtọọtọ ti wọn ko si ri iya naa mọ.
Okan lara awọn ọkọ ọmọ rẹ to ba awọn oniroyin sọrọ ṣalaye pe agbegbe opopona Apapa Expressway ni wọn ti lọ ri mama naa lọjọ Iṣẹgun nibi to ti n rin gberegbere kiri.
O ni wọn ti n tọju rẹ nile bayii ki ara rẹ lee balẹ ki wọn to gbe e lọ si ile iwosan.
Bi iya yii ṣe dede sọnu ti wọ́n n wa a
Awọn mọlẹbi arabinrin kan to jẹ oṣiṣẹfẹyinti olukọni, Rachael Afolabi ni awọn ti wa ninu ibrubojo lẹyin ti wọn rii pe wọn ko ri i mọ nigba to lọ ṣe ibẹwo si ọmọ rẹ obinrin ni agbegbe Ajegunle, ipinlẹ Eko.
Gẹgẹ bi iwe iroyin PUNCH ṣe fi sita, ni ọjọ Kejidinlogun oṣu kejila ni Arabinrin Afolabi kuro ni agbegbe Orodu ni Ajegunle to si lọ si agbegbe Oluwa ni Ajegunle kan naa nibi ti ọmọ rẹ̀ n gbe.
Iroyin ni ẹni ọdun marunlelọgọta ni arabinrin naa to lọ fun ibẹwo ọhun pẹlu ọmọ rẹ obinrin mii.
A gbọ pe wọn gun ọkada ọtọọtọ amọ iroyin ni nigba ti awọn ọkada to gbe iya ati ọnmọ de agbegbe Tolu Medical Junction, wọn ya si ọna ọtọọtọ ni wọn o ba ri iyan agbalagba ọhun mọ.
Ọkọ ọmọ rẹ, Oladokun Babatunde sọ fun iwe iroyin Punch pe gbogbo akitiyan awọn lati ri iya yii ko tii so eso rere.
O ni "o ti ṣe diẹ to ti rẹ iya iyawo mi idi ti a si ṣe gbe wọn wa si Eko niyi lati ilu Oyo fun itọju to peye, o ti to oṣu mẹrin ti wọn ti wa nibi bayii".
Arakunrin yii lo ṣalaye pe ni nkan bii Ọjọ Abamẹta meji sẹyin ni iya naa ati ọmọ rẹ to jẹ aburo iyawo oun fẹ wa ba iyawo oun ni ile itaja rẹ ti wọn si gun ọkada ọtọọtọ lati ọna ile wọn lọ si ṣọọbu rẹ.
"Nigba ti wọn de Tolu Medicals, mo gbọ pe sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ wa loju ọna torinaa ni awọn to wa ọkada ṣe gba ọna ọtọọtọ afi ti aburo iyawo mi de ṣọọbu wa amọ ti a bẹrẹ si ni duro de mama ki wọn de ti wọn o si de".
Wọn ṣalaye pe ọlọkada to gbe e ko si sọ pe oun ko mọ ọna, lẹyin wakati kan ti wọn ko ri i ni wọn tun bẹrẹ si ni wa a.
"Nigba ti a pada ri ẹni to wa ọkada, o mu wa lọ si ibi to ja mama kalẹ si ṣugbọn a ko ri i lati igba naa la si ti n wa wọn. Iṣẹlẹ yii ti pa wa lara gidi gan tori lati igba naa, mi o le lọ ibi iṣẹ. A ti n lọ a ti n bọ lati wa wọn to si ti da iyawo mi ati aburo rẹ laamu gidi gan".
Wọn ni wọn ti fi ẹjọ naa sun ni agọ Ọlọpaa Trinity.















