Admission seeker killed in Osun: Àwọn òbí ọmọ náà ń bèèrè fún okú ọmọ wọn tí wọ́n pa

Ṣé lòótọ́ ni ọtẹlẹmúyẹ́ ìpínlẹ̀ Osun pa ọmọkùnrin tó fẹ wọ ile iwe gíga?

Oríṣun àwòrán, Osun/ Police

Ẹbi ọmọ to fẹ wọ ile iwe giga kan ti iroyin ni awọn ọtẹlẹmusyẹ DSS pa ti bere fun oku ọmọ wọn.

Ọdọmọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Temitope Johnson ni wọn ni awọn ọlọpaa DSS ipinlẹ Osun ni ẹnikan ti wọn n pe ni Bamidele ti n bere pe ki wọn jọwọ oku rẹ fun awọn.

Baba ọmọ naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Segun na ika alebu si ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun nitori wọn fi ẹbi sinu okunkun lori bi ọrọ naa ṣe ri.

Iroyin sọ pe Bamidele ati awọn ọrẹ rẹ lọ si Ayope ni agbegbe Owode, Ede ni ipinlẹ Osun ni ọjọ kẹfa, oṣu kẹwa, ọdun 2021 ti wọn si n yinbọn lakọlakọ lẹyin ti awọn ara adugbo pe wọn lati wa da si ọrọ kan.

Wọn ni ibọn yii lo ba ọmọ ọkunrin kan ẹni ọdun mọkanlelogun Temitope ati awọn ọrẹ rẹ mẹta ti wọn si ko wọn lọ si ile isẹ nilu Osogbo.

Awọn ẹbi ọmọ naa ni wọn le awọn jade nigba ti wọn lọ si agọ awọn DSS lati lọ bẹ ọmọ wọn wo lai mọ pe ọmọ naa tilẹ ti ku.

Baba ọmọ naa ni nigba ti awọn ri pe gbogbo igbiyanju awọn lo ja si pabo, o wa kọ iwe ẹsun si ọlọpaa lodi si DSS.

O salaye pe, lẹyin ti iwe ẹsun naa de ọdọ wọn awọn ọlọpaa ti mu Bamidele ni ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kọkanla ọdun 2021.

Àkọlé fídíò, Odindi ọjọ́ kan ni mo fi wà ní ìhòhò ní Libya tí gbogbo èrò n fi ọwọ́ pa mí lára

Ẹwẹ, baba rẹ ẹni aadọta ọdun sọ pe wọn pada fi ọlọpaa na silẹ lagọ ọlọpaa pe awọn gba ipe lati oke pe ki wọn fi silẹ.

Bakan naa ni baba ọmọ oun Segun salaye pe ile isẹ ọlọpaa kọ lati tun Bamidele mu, o si tun fi kun pe titi di asiko yii oun ri oku ọmọ rẹ.

O ni, " ọlọpaaa ko se nnkankan: a gbọ nkankan lati ọdọ wọn. A fẹ lọ si ọdọ wọn ki wọn fi oju ẹni ti o pa ọmọ awọn han . A o ri nkankan ti awọn ọlọpaa se.

" Ẹ jọwọ ẹba wa bẹ wọn inu okunkun ni wọn n fi wa si".

" Se odidi ọmọ yoo wa lọ bẹẹ naa ni? a o si ri oku rẹ pẹlu, gbogbo ibi ti awọn ọlọpaa ba gbe oku ọmọ naa si ki wọn jẹ ki a mọ."

Iwadii BBC News Yoruba lati ọdọ ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa Yemisi Opalola ni lootọ ni awọn gbọ nipa isẹlẹ naa sugbọn awọn n ṣe iwadii.

Bakan ni agbenusọ ọlọpaa tun fi kun pe awọn ko le fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni pe DSS lo pa ọmọ na ati pe iwadi si n lọ lọwọ

Àkọlé fídíò, Bi mo ṣe fi Ọtí, Igbó, Sìgá mímu sílẹ̀ tí mi ò kó obìnrin tó máa ń ba ayé awọn olórin jẹ́ - J.A Adelakun tó kọ orin "Amona tete