J.A Adelakun Amona tete bo: Mo ti kọ ọ́ ṣáájú nínú orin nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí ní Nàìjíríà àti ǹkan tí yóò ṣì ṣẹlẹ̀

Àkọlé fídíò, Bi mo ṣe fi Ọtí, Igbó, Sìgá mímu sílẹ̀ tí mi ò kó obìnrin tó máa ń ba ayé awọn olórin jẹ́ - J.A Adelakun tó kọ orin "Amona tete

"Mo maa n sọ ọ pẹlu idaniloju pe mi o ni ọrẹbinrin gẹgẹ bi olorin amọ mo ri i pe kii ṣe agbara mi".

Ajihinrere J.A Adelakun gangan ni orukọ rẹ ṣugbọn ko sẹni to fẹrẹẹ mọ agba olorin ẹmi yii pẹlu orukọ rẹ bikoṣe "Amọna tete bọ" eyi tii ṣe akọle orin to sọ ọ di olokiki laye.

Ajihinrere Adelakun ṣalaye iru igbe aye to maa n gbe tẹlẹ ko to ba Ọlọrun pade to si bẹrẹ iṣẹ orin ẹmi ti awọn eeyan lee ka si ara awọn isọri orin ti kii ku lailai(Evergreen).

Baba Adelakun ni ni ọdun 1972 lasiko to wa lẹnu iṣẹ ologun ni o ba Jesu pade nigba to sin ọrẹ rẹ kan lọ si ijọ CAC ti ọkan rẹ si yi pada lati maa sin Ọlọrun.

"Mo mu Claro (nkan kekere ti a maa n mu fi mu ori ya) dani mo si sọ fun Jesu pe iwọ Jesu ti mo ṣẹ n gba yii, too ba le ṣee ki n ma mu gbogbo nkan ti mo n mu yii mọ, maa sin ọ".

Ajinhinrere yii ni idile Musulumi ni oun ti jade wa, amọ lati igba ti oun ti gba Jesu ni oun ti dara pọ ,ọ ẹgbẹ akọrin ti aye rẹ si yipada.

Lati ibẹ loun naa ti fẹran orin ti wọn si bẹrẹ ẹgbẹ ori "Ayewa" eyi to tun jẹ ọkan lara awọn orin wọn.

"Ologun n bẹ lode, Decree lojoojumọ, Satani Oluwa ba ọ wi o dẹhin lẹyin mi...". Gbogbo ọrọ orin yii ni Ajihinrere Adelakun ni ko si ninu bi awọn ṣe kọkọ kọ orin amọ ẹmi mimọ kan gbe e jade nigba ti wọn de yara orin ti wọn ti fẹ ka a silẹ.