Police car run over another police: Àṣìṣe ńlá gbáà ni, a ò mọ̀ọ́mọ̀ tẹ ASP ọlọ́pàá pa - Ọlọ̀pàá Ekiti

Oríṣun àwòrán, Ekiti Police
Kọmisọna ọlọpaa ni ipinlẹ Eiti Tunde Mobayo ti fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni mọto ọlọpaa tẹ ọlọpaa to wa lori ọkada ọkada pa ti awọn mẹjọ miiran si dfi ara pa yanayana ninu ijamba ọkọ to kan moto ọlọpaa RRS ẹka ti Ado Ekiti.
Mobayo ni oun ba ẹbi ẹni ti o ku kẹdun ati ọpọ awọn to fara pa ṣugbọn, o ni irọ ti jina si ootọ ni pe ijamba ọkọ naa ṣẹlẹ lasiko ti wọn n le ọmọ YahooYahoo kan gẹgẹ bi awọn iroyin kan ṣe gbe e jade.
Kọmisọna ọlọpaa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ọlọpaa Ekiti Sunday Abutu ṣalaye pe ijamba ọkọ ọhun ṣẹlẹ nitori ojiji ni ọkọ na yọnu lasiko ti awọn RSS gba ipe pajawiri lati wa moju to iṣẹlẹ kan.
- Ìgbẹ́ ìdí ni Ajá fẹ́ lọ jẹ, ǹkan ọmọkùnrin olówó rẹ̀ bá wọ̀ọ́ lójú, bí àjá ṣe bù ú jẹ nìyí
- Àsìkò ìpinnu ọdún tuntun dé! Kíní ìpinnu rẹ̀ fún ọdún 2022 tó ju àwọn ǹkan yìí lọ?
- Ìdí ti Ààrẹ Buhari ṣe kọ̀ láti buwọ́lu àtúnṣe ìwé àbádòfin òṣèlú ọdún 2021 rèé
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé lọdún 2021
- Kí ló dé tí Taliban fí fòfin dè kí àwọn obìnrin máa dá rírìn àjò tó bá ti jiná?
O ni, ní nkan bi aago mẹfa aabọ ni DPO ile iṣẹ ọlọpaa Ikole Ekiti gba ipe lati ọdọ ikọ RRS pe ki wọn wa ran awọn lọwọ lati mu awọn ọmọ ẹgbẹ ọkunkun kan ti wọn ti n dunkoko mọ awọn ara Ikole Ekiti ati agbegbe rẹ
"Lẹyin ti wọn gba ipe yii ni adari ikọ RRS ran ọkọ ọlọpaa mẹta ati awọn ọlọpaa to koju osuwọn lati lọ se isẹ naa"
" O bani lọkan jẹ pe, lasiko ti wón n lọ, iṣẹlẹ aburu ṣẹlẹ, ọkan ninu awọn ọkọ ọlọpaa naa yọnu ti o si tayọ kuro loju popo ti o si kọju si awọn ọkọ to n bọ, ibẹ lo ti lọ gba ọlọpaa to wa lori ọkada, ọlọpaa si n lọle lati ẹnu iṣẹ rẹ fun ọjọ naa nitori naa ko si lara awọn ọlọpaa ti o n lọ fun isẹ naa.
"Wọn sare gbe ọlọpaa na lọ si ile iwosan fun itọju, sugbọn asọ ko ba ọmọyẹ mọ, dokita sọ fun wọn pe ọlọpaa naa ti sọda si ajule ọrun.
Sugbọn awọn mẹjọ ti o ku to jẹ ọlọpaa RRS ninu ọkọ ọlọpaa to yiwọ naa lo farapa loriṣiriṣi ti wọn si wa ni ile iwosan bayii ti wọn n gba itọju."
Abutu tun fi lede pe Mobayo ba ẹbi ọlọpaa to sọ ẹmi nu naa kẹdun ti o si gbadura pe ki Ọlọrun té si aféfé rere
Gẹgẹ bi agbẹnusọ ọlọpaa ṣe sọ, Kọmisọna ọlọpaa ti sabẹwo si awọn ọlọpaa to wa ni ile iwosan bákan naa lo ti lọ si ile ẹbi ọlọpaa ọhun















