New Year resolution: Wo àwọn ìpinnu tóo lè fi mú ìyípadà bá ìgbésí ayé rẹ̀ ní ọdún 2022

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igba diẹ lo ku taa fi dagbere fun ọdun 2021 ti a o si ki 2022 kaabọ.
Njẹ ẹyin ti ni ipinnu ọdun ti yin abi ẹ ṣi n ro lọwọ?
O ṣeeṣe ki awọn mii ninu yin ti ni ipinnu yala nipa awọn nkan ti fẹ bẹrẹ si ni ṣe ati awọn mii ti ẹ fẹ ju silẹ.
Ẹ maa fi ọkan ba wa bọ lori oju opo yi lati le mọ awọn nkan tẹẹ le yan ni ipinnu ati awọn mii tẹ le ja ju silẹ
1.Ma duro, ma rosẹ
Ijafara lewu ohun taa ba si fi silẹ lewurẹ n gbe.
Ara to ba ji pepe nipa idaraya kan tabi omiran jẹ eleyi ti yoo le ṣamuṣẹ ipinnu to ba yan laayo.

Oríṣun àwòrán, Magnum Photos
O ṣeeṣe ki ẹ fẹ mu ere idaraya kan yala ni ile ẹkọ tabi ni adugbo laayo.
Ẹ wa awọn ti ero ọkan yin ba papọ ki ẹ si ri pe ẹ beere iranwọ bi ẹ ba nilo rẹ lati le ṣamuṣẹ ipinnu yin.
2. Ṣe iranwọ fawọn to nilo rẹ -
Orisirisi ọna la le fi ran ara wa lọwọ-yala ọrẹ tabi mọlẹbi wa.
O le pinnu lati maa ran awọn ara ile rẹ lọwọ ju ti tẹlẹ lọ nipa ṣiṣe awọn iṣẹ inu ile kọọkan.
Bakan naa lole kan si awọn araadugbo rẹ tabi ẹni too mọ ri lati ṣe iranwọ fun wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Koda o le ṣe agbekalẹ atẹ eleyi ti yoo maa jẹ iranti nkan to fẹ ba awọn ara inu ile rẹ se.
Ilẹ gbigba ni, abọ fifọ, titẹ ibusun tabi ko maa ba wọn da idọti nu. Ko si ọna ti eeyan ko le gba ran awọn ara ile lọwọ.
3. Ri pe o jẹun daada
Pupọ wa la nifẹ si awọn ounjẹ ipapate bi ṣọkọleti,suuti ati awọn ounjẹ miran ti kii ṣe ara loore.
Ninu awọn ipinnu taa le ṣe ni ọdun 2022 ni ka ri pe a yago fawn iru ounjẹ bayi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi eeyan kankan ko ba tiẹ dupẹ lọwọ wa,ara wa yoo mọ loore pe iyatọ de ba oun!
4. Pinnu latiṣe atunṣe ayika rẹ
Ayika wa nilo itọju lọdọ emi ati iwọ.
Bo ba ṣe le mọ, ko si eeyan ti ko ni ipa tirẹ lati ko nipa mimu iyipada ba ayika wa.
Lara ipinnu ọdun o le pinnu lati mu adinku ba iye lẹda ti iwọ ati idile rẹ yoo ma lo lati fi ko nkan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dipo awọn lẹda ti o le ṣe akoba fun ayika, o le fi baagi ti wọn si bi paali ṣe lati fi di ẹru rẹ.
Koda bo ba pinnu lati din omi to n lo nile ku, eleyi naa le ṣe anfaani fun ayika rẹ ninu ọdun 2022.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
5. Muadinku ba iye ẹrọ tẹkinọlji to ba n lo
Lootọ tẹkinọlọji a maa mu igbe aye wa dẹrun ṣugbọn apọju rẹ naa ko da.
Riranju mọ oju foonu rẹ tabi ẹrọ amounmaworan tabi kọmputa rẹ naa ko dara to fun alaafia ati ibaṣepọ pẹlu awọn to wa layika rẹ.
O le pinnu pe lọdun 2022 to n bọ yi, mo maa mu adinku ba iye wakati ti mo n lo lori foonu mi tabi kọmputa.

Oríṣun àwòrán, Magnum Photos
Lilo asiko pẹlu mọlẹbi rẹ ati ọrẹ jẹ nkan to da .
O le bẹrẹ nipa yiyan ọjọ kan laayo pe o maa mu adinku ba iye wakati ti wa lo lori foonu rẹ.
Danwo ki oriu iru iyatọ ti yoo mu ba igbe aye rẹ
6.Ṣe daada si awọn eeyan ju ti tẹlẹ lọ
O da ki eeyan ṣe daada jẹ ọrọ ti ọpọ a maa sọ.
Ninu ipinnu rẹ lọdun 2022, ṣe ileri lati se oore tabi daada kan lojumọ kan ki o si da ẹrin pa ẹkẹ awọn to wa layika rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki ni awọn nkan miran ti ẹ lero pe eeyan le mu ni ipinnu lọdun 2022?
Ẹ le jẹ ki a mọ ero ti yin nipa kikan siwa loju opo wa ni bbcnewsyoruba/facebook tabi loju opo wa ni Instagram.
Ọdun ayọ la o ṣe!

















