Kayode Fayemi: Alágídí àti oníwàkuwà ni Oshatuyi tó fi ókọ̀ gbá mi tó tún ń pariwo pé gómìnà rán agbófinró láti na òun

Oríṣun àwòrán, Kayode Fayemi
Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayemi ti ṣe atẹnumọ ohun to waye lọjọ ti arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Dapo Oshituyi to lọ si kootu ori ayelujara sọ pe awọn ẹṣọ gomina ipinlẹ naa ba ọkọ ayọkẹlẹ oun jẹ.
Ninu abajade iwadii ti ijọba Ipinlẹ naa ṣe gẹgẹ bi ileri rẹ ni kete ti iṣẹlẹ naa waye, gomina Fayẹmi ni arakunrin Oshituyi gbiyanju ati sare ọkọ gomina atawọn ikọ to n kọwọrin pẹlu rẹ lai naani gbogbo awọn ikilọ tawọn oṣiṣẹ alaabo n fun un.
Atẹjade naa ti amugbalẹgbẹ fun gomina Kayode Fayemi lori ọrọ iroyin, Yinka Oyebode fi sita, sọ pe ibi ti arakunrin ọhun ti n gbiyanju ati kọja awọn ọkọ to kọwọrin pẹlu gomina lo ti dojukọ ọkọ ajagbe kan to n bọ lodi keji leyi to mu ko yiwọ kọlu awọn ọkọ to n ba gomina kọwọrin leyi to mu ko kọlu ọkan lara awọn ọkọ ti gomina funrarẹ maa n gun; "Kaka ko duro, n ṣe lo tun tẹ ina ọkọ rẹ gba ọna miran to tun fi da wahala silẹ fawọn araalu to ku".
"Pẹlu bi ọrọ abo si ṣe ri ni lorilẹede yii lọwọ yii, lọna ati fidi ọrọ mulẹ lati mọ boya awakọ naa kan wa iwakuwa ni tabi o n gbiyanju ati ṣe ijamba fun ikọto n kọwọrin pẹlu gomina ni wọn fi ni ki ikọ awọn agbofinro kan gba tẹle nigba ti awọn yoku n tẹsiwaju irinajo wọn."
Nigba ti awọn agbofinro baa, atẹjade baa ni kaka ko bọ silẹ, agidi lo tun lo, ki awọn aradugbo to baa bẹbẹ ti wọn si fi silẹ.
Agbẹnusọ fun gomina Fayẹmi tun ṣalaye pe ko si otitọ ninu ariwo ti Ọgbẹni naa n pa pe awọn agbofinro na oun tabi ba ọkọ oun jẹ.
Ìjọba Ekiti fèsì lórí ọkùnrin tó ní àwọn ẹ̀ṣọ́ Gómìnà Fayemi ba ọkọ̀ òun jẹ́ l'Akure
Ijọba ipinlẹ Ekiti ti fesi lori ọrọ ọkunrin kan, Dapo Oshituyi to sọ pe awọn iṣọmọgbe Gomina Kayode Fayemi ko kọwọ rin pẹlu rẹ ba ọkọ ''Camry Muzzle'' oun jẹ.
Oshituyi ti kọkọ ṣe afihan ninu fidio kan to lu ayelujara pa nibi to ti sọ pe awọn ọmọlẹyin Fayemi ba ọkọ oun jẹ lopopona Oloko si ilu Akure.
Oshutiyi tun sọ pe Gomina Fayemi funra rẹ wa ninu ọkọ nigba tawọn ẹṣọ to ba a rin ba ọkọ oun jẹ.
- Ẹni tó gé orí olóri fi ṣe ògùn owó náá ṣán kú nínú àtìmọ́lé ọlọ́pàá l'Ondo
- Bi mo ṣe fi ọtí, igbó, sìgá mímu sílẹ̀ tí mi ò kó obìnrin tó máa ń ba ayé awọn olórin jẹ́ - J.A Adelakun "Amona tete bo"
- Babatunde lọ bá adari Hoteeli ṣe àjọyo, ó pade iku ọbẹ gbígbóná
- DDS ní kí n di ológbò bíi Sunday Igboho, ojú mi rí tó ní àhámọ́ DSS l'Abuja- Ifasooto
- Kà nípa ìbẹ̀rẹ̀ ìyàwó Ooni Ife, Olórí Silekunola Moronke Náómì, Wòlíì tó di Ayaba Ile Ife
- Ènìyàn Mẹ́ta kú, Mẹrin Farapa bí ọkọ̀ ńlá ṣe rọ́lu àwọn ènìyàn ni Mokola ní Ibadan
- Àwọn wò ló jí àna Gómìnà Okorocha gbé nílé ìjọsìn lọ́jọ́ kejì Kérésìmesì?
O ṣalaye pe oun gan an ni oun duro fun wọn lati kọja bi bẹẹ kọ wọn ko le ba oun ti oun ko ba duro.
Oshutiyi ni o dabi ẹni pe oun n lala ni nigba ti awọn ẹṣọ naa yabo ọkọ oun.
Fidio ọhun bi wọn ṣe fọ gilaasi ẹgbẹẹgbẹ ati ti iwaju jẹ ti gbogbo rẹ si run jege jege.
Ṣugbọn akọwe iroyin si Gomina Fayemi, Yinka Oyebode sọ pe gomina ipinlẹ Ekiti ko mọ ohun kan nipa iṣẹlẹ naa.
Ọgbẹni Oyebode ni Fayemi ko le lọwọ si iru nkan bayẹn laelae.
Oyebode ni ''a kaanu pẹlu Ọgbẹni Oshutiyi, ohun ti a gbagbọ ni pe ko yẹ ki ómọ Naijiria kankan ṣe kongẹ iru iṣẹlẹ bayii.
Iṣẹ iwadii ti bẹrẹ lori ohun to ṣẹlẹ yii, ijọba yoo wadii ohun to ṣẹlẹ gan an.
A n fi asiko yii ke si Ọgbẹni Oshutiyi lati kan si ileeṣẹ ijọba ni agbegbe Oke Bareke, Ado Ekiti lati ran iṣẹ iwadii lọwọ.''















