Imo Uche Nwosu alleged Kidnap: Òhun táa fẹ́ mọ̀ ni ibi tí wọ́n gbé ọkọ ọmọ mí lọ àti bóyá o ṣí wà láàyè- Okorocha

Oríṣun àwòrán, UCHE NWOSU FACEBOOK
Gomina tẹlẹ ri nipinlẹ Imo, Rochas Okorocha ti ke gbajare si awọn agbofinro lati sọ ibi ti wọn gbe ana rẹ lọ fun oun.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC lo ti sọ pe awọn ọlọpaa ji arakunrin Uche Nwosu to jẹ ana rẹ gbe lasiko ijọsin ni St.Peter's Anglican church,Nkwerre.
O ni nigba ti iroyin iṣẹlẹ to pe ni ijinigbe yi waye, oun kan si awọn ọlọpaa ṣugbọn wọn ko gbe ipe.
Okorocha ṣalaye pe Uche Nwosu ati iyawo rẹ ni wọn jijọ wa nile ijọsin ki awọn ọlọpaa to dasọ bo wọn loju ti wọn si yinbọn soke.
Gomina ipinlẹ Imo tẹlri yi wa sọ pe oun nigbagbọ pe ijinigbe yi lọwọ oṣelu ninu.
O ni ''ohun to ṣe pataki bayi ni ki a tiẹ mọ ibi ti wọn ji gbe lọ ati boya o si wa laye''
Ki ni awọn agbofinro sọ?
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo ti sọ pe awọn ko ji ọkọ ọmọ Gomina tẹlẹ ri,Rochas Okorocha.
Yala wọn ni ohun to ṣẹlẹ ni pe awọn mu ni ati pe o wa ni ahamọ lọdọ awọn.
Ninu atẹjade ti Micheal Battam alukoro ọlọpaa fi sita ni alaye yi wa.

Oríṣun àwòrán, BBC Igbo
Desmond Tutu, Àlùfáà tó wú ni lórí àti ajìjàgbara eléyàmẹ̀yà tó jáde láye, ohun tẹ́ẹ ní láti mọ̀ rèé
O tẹsiwaju pe ko si ootọ ninu ọrọ pe awọn agbebọn kan lo ji Uche Nwosu gbe .
Lagbo oṣelu ipinlẹ Imo, odu ni Uche Nwosu jẹ to si dije dupo Gomina ninu idibo to kọja.
Awuyewuye ti n kaakiri bayi wi pe Gomina to wa lori alefa Hope Uzodinnma lo wa nidi bi wọn ti ṣe mu Nwosu yi.
Amọ, agbẹnusọ Gomina Declan Emeluba sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ yi.
Niju fọnran fidio bi wọn ṣe gbe Nwosu nile ijọsin, niṣe la n gbọ iro ibọn kikankikan ti obinrin kan si n ke gbajare ninu rẹ.
BBC ko ribi fidi otitọ fidio yi mulẹ titi di asiko ta fi n ko iroyin yi jọ.














