NEXT Fire Abuja: Dúkìá àti ọjà jóná ráúráú lásìkò tí iná sọ ní ilé ìtajà ní Abuja

Ina nla kan ti ṣẹyọ nile itaja nla NEXT to wa lolu ilu Naijiria Abuja.
Kaakiri oju ayelujara lawọn eeyan n ṣe alabapin aworan ati fọnran fidio ina ati eefin bo ṣe n sọ nile itaja naa.
Adugbo Jahi ni ilu Abuja ni ile itaja yi wa.
Titi di ba ṣe n ṣe akojọpọ iroyin yi, a ko ti ribi fidi ohun to ṣe okunfa ina yi.
Ileeṣẹ iroyin amounmaworan Naijiria Channels TV jabọ pe nkan bi ago mẹwaa owurọ ọj Aiku ni ina yi bẹrẹ.
Ninu ọrọ wọn, a gbọ pe ọga ajọ iṣẹlẹ pajawiri ni Abuja NEMA ti n kesi awọn ajọ miran lati pawọpọ ki wọn ba le mu ina yi dopin.
''Gbogbo NEXT Cash and Carry ni ina ti n jo bayi. A ni ajọ panapana FCT ati tijọba apapọ ni ikalẹ. A n kesi gbogbo awọn ajọ to ni irinsẹ lati koju ina yi pe ki wn wa gburuku ti wa.''
Awọn oju ọna to wa niwaju ile itaja yi lo ti wa ni titi pa tawọn oṣiṣẹ panapana ṣi n gbiyanju lati pa ina yi
Bakan naa la ko ti le sọ boya eeyan kankan ba iṣẹlẹ naa lọ.

Oríṣun àwòrán, Chukwudi Boris Nzogbu
Ninu awọn fọnran fidio taa ri loju ayeluja ina yi ko mọ ni kekere to si n jo bila bila titi di asiko ta fi n ko iroyin yi jọ.
Akọroyin BBC kan to ribi de ibi ti ina yi ti njo sọ pe ileeṣẹ Julius Berger naa ti gbe irinsẹ panapana wọn wa lati ran awọn panapana lọwọ.
Ẹwẹ a gbọ pe awọn agbofinro ti mu awọn janduku kan to wa fi ọkọ ko ọja ile itaja naa lasiko ti ina naa n jo lọwọ.
Niṣe lawọn agbofinro duro wamu nibẹ lati ri pe awọn eeyan ko ji nkan gbe nibi ileeṣẹ yi.
Lẹnu ọjọ mẹta yi iṣẹlẹ ijamba ina fẹ le kenka ni Abuja.
Yatọ si ina to jo ni Next yi, loṣu to kọja ina sọ ni ọja Kubwa taa si gbọ pe eeyan marun ku nibẹ ti awọn mọkanla si farapa.












