Dayo Kujore dies: Mọ̀ nìpa àgbà olórin Juju yìí tó dágbére fáyé lẹni ọdún 63

Aworan Dayo Kujore

Oríṣun àwòrán, Dayo Kujore

Dayo Kujore gbajugbaja olorin Juju ni Naijiria ti dagbere faye lẹni ọdun mẹtalelọgọta.

Iwe iroyin Naijiria Punch ati awọn iwe iroyin miran ti kede iku rẹ.

Gẹgẹ bi Punch ti ṣe sọ, ọmọ rẹ Ayinke Dayo Kujore lo fidi ọrọ yi mulẹ fun wọn.

Ọmọ bibi ilu Abeokuta ni Dayo Kujore ti ọpọ si mọ nitori ẹbun ti Eledua fun nipa arokọ ati agbekalẹ orin.

Oludasilẹ orin Sọkọ, Kujore kọṣẹ orin labẹ Prince Adekunle to si n ta gita ninu awọn orin manigbagbe ti Adekunle kọ bi "Aditu ede" ati "Eda n reti eleya".

Ko daju bayi ohun to ṣokunfa iku rẹ ṣugbọn ileeṣẹ iwe iroyin Punch sọ pe awọn mọlẹbi ko ni pẹ kede iku ati eto to ba kan seti araye.

Ọjọ Kẹrin ọdun 1958 ni a bi Kujore ni Abeokuta.

O bẹrẹ si ni ta gita nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹwaa.

Ninu awọn awo orin rẹ to gbajumọ la ti ri Elevation, Wisdom, Joy, Easy Life, ati orin ilumọọka ni ''Soko Xtra.''