Wukari monarch death: Kí ló ṣẹ́lẹ̀ sí ẹ̀ṣọ́ ọba tó fi ẹṣin gbé òkú ọba wọn wọ inú igbo lọ?

Ẹlẹṣin atawọn abanisọkun

Oríṣun àwòrán, Tijjani Sale Angyui

Bi wọn se pari gbogbo aṣekagba eto isinku oloogbe ọba Aku-Uka ti ilu Wukari, Ọjọgbọn Shekarau Angyu Masa-Ibi ni ipinlẹ Taraba ni wọn mura lati sin.

Amọ iroyin ara meeriri ni iru eto isinku ti wọn ṣe, eyi to ṣi n fa ori ayelujara ya nitori awọn nkan aṣa ati iṣẹṣe ti wọn dan wo eyi to n kọ agbado haa si gbogbo eeyan lẹnu.

Ọdun marundinlaadọta ni Ọba, ẹni ọdun marundinlaadọrun naa lo lori oye ko to dagbere faye ninu oṣu Kẹwa ọdun 2020.

Ibeere nla ti awọn eeyan wa n beere da lori ẹlẹṣin to gbe oku ọba naa wọ inu igbo lọ, nibi ti wọn ti sin in ni ilana aṣa ibilẹ wọn.

Awọn abanisọkun

Oríṣun àwòrán, Tijjani Sale Angyui

Lọjọ Aiku to kọja yii ni aworan ati fidio bẹrẹ si ni gba ori ayelujara ka to n ṣafihan bi wọn ṣe se isinku naa ati bi ẹlẹsin ṣe gbe oku ọba naa ti wọn ṣe lọṣọọ pọn to si n gun ẹṣin naa lọ.

Ọkan lara awọn Arẹmọ, Musa Ibi Aku-Uka sọ fun BBC nipa awọn iroyin to n gba ori ayelujara kan.

Aṣa gigun ẹṣin sin oku ọba wọ igbo:

Awọn abanisọkun

Oríṣun àwòrán, Tijjani Sale Angyui

Iroyin tan kaakiri pe ẹlẹṣin naa yoo sin ọba wọ inu igbo aginju lọ ti ko si ni pada wa. Amọ Arẹmọ ọba naa sọ fun BBC pe irọ nla ni eyi.

"Ọpọlọpọ iroyin lo tan ka ori ayelujara ti kii ṣe ootọ, wọn ni pe wọn ti fun ẹlẹṣin naa ni miliọnu marun naira pe wọn si sọ fun un pe o gbudọ ku sine igbo ko ma ṣe pada jade rara. Irọ nla gbaa si ni gbogbo eleyi".

"Aṣa ti a ti n ṣe lati ọdun mọdun ni pe ẹlẹṣin ni yoo sin ọba lọ inu igbo, o si gbudọ jẹ akinkanju eniyan lati le ṣe e toripe ohunkohu lo le ṣẹlẹ nibẹ. O lee pade oriṣiriṣi nkan lọna too ba n pada bọ bii ẹranko inu igbo ati bẹẹ bẹẹ lọ".

"Bi mo ṣe n baa yin sọrọ lọwọlọwọ, ẹlẹṣin taa n sọrọ rẹ yii ti pada sile lalafia ko si si ohun to ṣe e torinaa gbogbo nkan ti wọn n sọ kiri yẹn kii ṣe ootọ".

Bakan naa ni Arẹmọ tun ṣalaye nipa awọn aṣa ati iṣẹṣe mii to hande nibi eto isinku ọhun paapaa nipa ti awọn obinrin to dan ori wọn.

Awọn abanisọkun

Oríṣun àwòrán, Tijjani Sale Angyui

Bi iṣipo pada Ọba Wukari ṣe maa n waye:

Ni ilana aṣa ibilẹ ijọba ilu Wukari, Aku kii ku, o kan maa n ṣipo pada ni lati lọ pade awọn baba nla baba rẹ.

Eyi ni Arẹmọ sọ fun BBC. Bakan naa lo ni ni ti aṣa isinku, igbaradi yoo ti bẹrẹ lati bii oṣu mẹta si meje.

Gẹgẹ bi ero ṣe pọ to n woran lori ayelujara, ọpọ ero ni yoo to lati maa ki Ọba ni odigbooṣe.

Awọn obinrin alagbara yoo fa irun ori wọn dan nigba ti awọn ọkunrin yoo duro di igba ti wọn ba sin Aku pada de ki wọn lati fa irun ki wọn to wọ inu ile wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: