World Sleeping Day: Bo bá ṣe le è ṣùn tó, ni ẹmí rẹ yóò ṣe gùn sí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ayajọ oorun sunsun lagbaye mii tun ko ni oni ọjọ Ẹti, ọjọ kejidinlogun osu kẹta ọdun 2022.
Akori ayajọ ti ọdun yii ni "Oorun to poju owo, ọkan to pegede ati aye to kun fun ayọ."
To ba fẹ ni ẹmi gigun, ati ilera to peye, o ko gbọdọ yan oorun lodi rara, o si gbọdọ maa ba oorun sisun se ọrẹ ni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Báwo ní àláfíà ara Iyabo Oko, ipò wo ní ìlera rẹ̀ wà?
- Ohun tí mo fẹ́ rèé tí ìkọlù sí Ukraine yóò bá dópin - Putin
- ₦7trn àti díẹ̀ ló gun gbèsè Nàíjíríà láàrin ọdún 2020 sí 2021 - DMO
- Olùdásílẹ̀ ìjọ tí ọlọ́pàá FBI ti ń wá fọ́jọ́ pípẹ̀, kó sí gbaga EFCC lórí ẹ̀sùn wáyá-wayà
- Nàíjíríà ń sún ọjọ́ ìjà síwájú ni, mo gbà pé ìpàdé àpérò gbọdọ̀ wà - Ọba Tejuosho
- "Ọlọ́pàá ló pe mí láti wá gbé òkú Timothy Adegoke lẹ́sẹ̀ títì"
- Wọ́n tan bàbá 85 kúrò nílé, fọ́ igi mọ lórí, ju òkú rẹ̀ sétí odò l‘Ogun
Eyi ni ero onimọ kan nipa ihuwasi ẹda ati imọ sayẹnsi nipa ọpọlọ, Matthew Walker, to wa lọgba fasiti California.
Awọn onimọ isegun naa si ni o kere tan, a gbọdọ sun oorun wakati mẹjọ, o kere tan, ni ọjọ kan, ki agọ ara wa le peye.
Wọn fikun pe ọpọ aisan to n ba awọn eeyan finra lo ni ohun se pẹlu iye wakati ti ẹda kan ba fi n sun lojumọ.
Awọn onimọ isegun naa wa fọwọ gbaya pe aisan yoo dinku lagọ ara ẹni to ba n sun daadaa ju ẹni ti kii sun deede lọ.
Sugbọn bi oorun sisun ti se pataki to yii fun igbe aye to peye, ọpọ eeyan ni kii ri oorun sun bo se yẹ, boya ni ọsan tabi ni oru.
Aisan si ni awọn onisegun pe asa airi oorun sun, ti awọn oloyinbo n pe ni Insomnia
Ki lo n fa a ti awọn eeyan kii fi ri oorun sun:
- Iwadii BBC Yoruba fihan pe ọrọ aje to daju lo n sokunfa bi ọpọ eeyan kii se ri oorun sun bo se yẹ.
- Ironu owo si ni wọn maa n fi ọkan ro lori bi wọn yoo se gbe igbe aye irọrun, ti wọn yoo si ri owo sanwo ile ati owo ile ẹkọ ọm wọn.
- Yatọ si eyi, akoko ti ooru ba mu ni amuju lọsan ati ni oru, ọpọ eeyan ni kii ri oorun sun daadaa, ti iyatọ si maa n wa laarin otutu ati ọyẹ.
- Nigba miran, bi ibudo ti eeyan fẹ sun naa ba tutu ju, otutu yoo mu ni, oorun ko si ni ku oju ẹni.
- Koda, bi ibudo naa ba tun kun fun ariwo to lagbara tabi ti ibi ta fẹ sun ko rọrun rara, bii ko ma si ibusun to dara, oorun ko ni wa.
- Wahala isẹ oojọ kan maa n fa ki oorun salọ loju ẹni nitori akolekan pe bawo ni isẹ naa yoo se lọ.
- Aisan ninu agọ ara tun maa n fa airi oorun sun nitori ẹni ti eyin ba n ro lasan, yoo mọ iyi oorun.
- Aisan ọpọlọ naa ma n fa airi oorun sun, to si wa lara oun to maa n da awọn alarun ọpọlọ laamu.
- Lakotan alakala ni alaalẹ maa n mu ki oorun sa lọ, ti asa mimu oogun oloro kii si jẹ ki eeyan sun deede.Ayajọ oorun sunsun lagbaye mii tun ko ni oni ọjọ Ẹti, ọjọ kejidinlogun osu kẹta ọdun 2022.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bawo la se fẹ ri oorun gidi sun ni alẹ:
Maa ji, ko si maa sun ni akoko kan naa lojoojumọ:
To ba lee maa ji, ko si maa sun ni akoko kan naa lojoojumọ, eyi too ran ọ lọwọ lati maa mọ iye wakati to fi n sun, ti oorun yoo si maa kun ọ, ti akoko to yẹ ko sun ba ti ko.
Fi ara rẹ sinu okunkun:
A nilo lati wa ninu okunkun, ki ara si balẹ, ki omoonu kan, ti wọn n pe ni Release Melatonin, to n fa oorun sisun, lee sisẹ rẹ.
Sugbọn ọpọ wa la n gbe ni ayika ti imọlẹ ti yi wa ka, sugbọ o le seranwọ fun ara rẹ nipa mimu adinku ba imọlẹ to wa ni ayika rẹ, nigba to ba ku wakati kan to fẹ sun.
Fi ara balẹ lori ibusun lai maa yi kaakiri:
- Jẹ ki ibusun rẹ sun nipa ko ma yi kaakiri tabi maa ba irọri rẹ ja
- To ba sun sori ibusun, ti oorun ko ba wa, dide nilẹ, ko maa se nkan miran bii kika iwe tabi rin kaakiri
- Se adinku awọn eroja amu oorun da loju ẹni bii, obi ati 'Coffee', ki orun lee tete wa
- O nilo wakati mejila ki eroja kọffi to lee kuro ni ara rẹ, tori naa, ma mu kọffi tabi jẹ obi lọwọ irọlẹ.
- Sọra fun ọti lile. Lodi si ero ọpọ eeyan, ọti lile kii mu oorun kun eeyan tabi mu ki ara balẹ., o si tun lee se akoba fun ala ati oorun rẹ.
Ewu to wa ninu airi oorun sun:
Iwadi ti wa fidi rẹ mulẹ pe, aisun maa n ni ipa to buru julọ lori ọpọlọ ati ẹya ara wa.
Gbogbo awn aisan bii jẹjẹrẹ, aisan ọkan, ara asanju, atọgbẹ, ironu ati iwa gbigba ẹmi ara ẹni, to maa n tete ran awọn eeyan sọrun ni awọn orilẹede to ti goke agba lagbaye, lo ni nkan se pẹlu oorun sisun.
Amọ, oorun yii gbọdọ wa funra rẹ ni, kii se afioogun pe, eyi to lee sokunfa aisan jẹjẹrẹ, kokoro ti a ko lee fi oju ri ati iku aitọjọ.
Oorun sisun kii se ka gbe ori le irọri nikan, tori kii se ọpọ eeyan lo lee tete sun lati ipasẹ eyi nikan.
Sugbọn awọn onimọ ni ta ba lee mu ayipada ba awọn iwa kan to ti di baraku fun wa, a maa sun bo se yẹ.

















