Nigeria Debt Profile: Kí ló mú gbèsè Nàìjíría fò láti ₦32.92trn si ₦39.56trn láàrin ọdún kan?

Ẹka ileesẹ to n risi ọrọ gbese ni Naijiria sọ pe apapọ owo gbese ti Naijiria jẹ ti lekun si lati triliọnu mejilelọgbọn naira lọdun 2020 si triliọnu mọkandinlogoji naira lọdun 2021.
Ọga agba ileesẹ naa Patience Oniha lo fidi ọrọ yii mulẹ lasiko to n ba awọn akọroyin Naijiria sọrọ.
Gẹgẹ bo ti se salaye, apapọ alekun owo gbese yii mọ owo ti ijọba apapọ Naijiria ya.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Báwo ní àláfíà ara Iyabo Oko, ipò wo ní ìlera rẹ̀ wà?
- Olùdásílẹ̀ ìjọ tí ọlọ́pàá FBI ti ń wá fọ́jọ́ pípẹ̀, kó sí gbaga EFCC lórí ẹ̀sùn wáyá-wayà
- Ohun tí mo fẹ́ rèé tí ìkọlù sí Ukraine yóò bá dópin - Putin
- Nàíjíríà ń sún ọjọ́ ìjà síwájú ni, mo gbà pé ìpàdé àpérò gbọdọ̀ wà - Ọba Tejuosho
- Olùdásílẹ̀ ìjọ tí ọlọ́pàá FBI ti ń wá fọ́jọ́ pípẹ̀, kó sí gbaga EFCC lórí ẹ̀sùn wáyá-wayà
- Gómìnà ànà ní Anambra, Obiano bọ́ sí gbaga EFCC lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tó gbé ìjọba sílẹ̀
- "Ọlọ́pàá ló pe mí láti wá gbé òkú Timothy Adegoke lẹ́sẹ̀ títì"
- Ẹ wo àṣírí tó wà nìdìí ìròyìn pé ìjọba Gẹ̀ẹ́sì kò fún ọmọ Nàìjíríà ní “visa” mọ́?
- Ogunsua ìlú Modakeke, Ọba Moses Oladejo Oyediran wàjà
Bẹẹ naa lo fidi rẹ mulẹ pe, ninu gbese naa ni ijọba apapọ Naijiria ti gbọ bukata owo isuna awọn isẹ akanse ati eto iranwọ fun igbelarugẹ ọrọ aje.
Oniha sọ pe ''Gbese ti Naijiria jẹ losu kejila ọdun 2021 N39.56tn tabi $95.78bn.
Atupalẹ bi awọn gbese naa se lọ:
Iye yijẹ apapọ gbese abẹlẹ ati ti ilẹ okere ijọba apapọ, awọn ijọba ipinlẹ ati olu ilu Abuja si ni owo gbese naa.
"Ni afiwe, owo gbese taa jẹ ni ọdun 2020 jẹ N32.92tn tabi $86.39bn.
Owo gbese tọdun 2021 ninu rẹ la ti ri owo ti ijọba apapọ sẹsẹ ya.
Ni ti ijọba apapọ, afikun owo isuna ọdun 2021 to fi mọ awọn owo taa ya labẹle ati ni ẹyin odi to jẹ triliọn marun le diẹ taa fi yanju adinku owo yi''
O fi kun pe toun ti alekun owo gbese ti Naijiria jẹ yii, a si wa ni aarin gbedeke owo gbese ti ko gunpa.
Gbedeke yii jẹ ida marun le laadọta ninu ida ọgọrun ti banki agbaye fi lelẹ pe orileede le jẹ ati ida aadọrin ninu ọgọrun ti ajọ Ecowas la kalẹ ni tiwọn naa.
Naijiria na tiriọnu meji naira fún èlé ori gbese ni 2021:
Oniha sọ pe ijọba apapọ ko gbagbe pe ko yẹ ki iye owo gbese orileede kọja agbara tori naa lawọn fi gbe awọn eto kan kalẹ lati le fi mu alekun ba iye owo ori to n wọle fun Naijiria.
Ni pataki, o ni awọn se ifilọlẹ aba eto ọrọ aje taa mọ si Finance Act lati ọdun 2019.
Iwadii fi han pe Naijiria n na triliọnu meji naira le lati lee maa fi gbe ẹmi gbese yii ro lọdun 2021 gẹgẹ bi alaye taa ri lati ọwọ ileesẹ DMO.
Laarin osu Kini ati osu Kẹta ọdun 2021, apapọ owo ti Naijria na lati maa fi gbe ẹmi gbese ro labẹle jẹ bi N612.71bn nigba to si na to biliọnu kan dọla lati maa fi gbe ẹmi gbese to jẹ nita ro.
Lapapọ ele ori gbese labẹle ati lẹyin odi jẹ N1.03tn.
Bẹẹ naa ni ijọba lawọn fi iye owo tabua mii gbẹmi gbese ro laarin osu Kẹrin si osu Kẹfa 2021, N447.06bn
Osu Keje si osu Kẹsan, N1.03tn ni wọn na
Ti osu Kẹwaa si osu Kejila ọdun 2021 si jẹ N429.6bn labẹle ati lẹyin odi ni owo gbẹmi gbese ro ti ijọba Naijira na lapapọ.
Isiro $1 =N415.92 ni wọn fi n san owo pada lati fi gbe ẹmi gbese ti wọn jẹ ro.
Ki lawọn onimọ eto ọrọ aje sọ lori gbese to n lọ soke yi?
Awọn onimọ ọrọ aje ti sọ pe isoro nla ni gbigbe ẹmi gbese yi ro jẹ fun Naijiria nitori pe o n ko ipalara ba eto ọrọ aje Naijiria.
Ọjọgbọn nipa imọ eto ọrọ aje kan ni fasiti Uyo, Akpan Ekpo sọ pe ''bi ẹ ba foj uwo iye gbese ti Naijiria jẹ yi jẹ, inu ewu nla la wa nitori owo taa n pa wọle nise pẹlu owo epo rọbi eleyi ko si jẹ nkan to daju nitori bo se n lọ soke lo n walẹ pada''
''Sugbọn pẹlu ogun Ukraine ati Russia yii, o seese ki owo epo rọbi Naijira lọ soke, taa si le fi owo yii pamọ lati fi san gbese taa jẹ.
Bi eeyan ba n jẹ gbese nisinyi, awọn to n bọ lọjọ ọla laa n da wahala si lọrun. O yẹ ki wọn jẹ ki ọmọ Naijiria mọ nipa awọn gbese yi''
Bakan naa ni olori ileesẹ to n risi itẹsiwaju isẹ aladani Onimọ Muda Yususf sọ pe owo gbese to n lọ soke yii le mu rukerudo wa lagbami ọrọ aje.
Yusuf ni ''bi a ba fi owo gbese ti banki apapọ CBN ati ti AMCON kun, o seese ki iye owo gbese Naijiria kọja triliọnu aadọta Naira.''
O ni nkan to yẹ ki ijọba se ni ki wọn gbe igbesẹ lati din iye owo gbese Naijiria ku nipa owo ina ijọba.

Ọmọdé méje kú, ọ̀pọ̀ farapa nígbà tí ọ̀rọ̀ di bóòlọ, ko yàgò fún mí

Oríṣun àwòrán, Screen shot
O kere tan ọmọde meje ti padanu ẹmi wọn, ti ọpọ si farapa ninu wọduwọdu kan to waye ni abule Shimfida nijọba ibilẹ Jibia, nipinlẹ Katsina.
Awọn ti ọrọ naa soju wọn ni isẹlẹ yii waye lasiko tawọn janduku kan yabo agbegbe naa.
A gbọ pe lỌjọbọ ni wọn ko awọn ikọ aabo to n sọ agbegbe naa kuro.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ọmọ Yorùbá mẹ́ta àti gbajúmọ̀ míì tó ní Lupus, àrùn tó n bá Kemi Afolabi fínra
- Portable Zazzu pariwo pe wọ́n ti dá ọjọ́ méje pé òun yóò kú
- Tẹ̀gbọ́n tàbúrò jí ọmọ ará àdúgbò gbé láti gbowó, àmọ́ wọn fún ní òògùn eku jẹ
- "Èèdì àti ogun ayé ni awọn èèyàn n rò pé ó mú mi bí ìbejì ní ìgbà mẹ́fà"
- Ọjọ́ Ajé la bẹ̀rẹ̀ ìpè fún ìdásílẹ̀ Yoruba Nation padà - Akintoye
- Ohun tó bá kàn ìlú Ibadan, kàn mí - Gómìnà Ganduje
Bẹẹ la tun gbọ pe awọn ọmọ ogun ti wọn ko kuro yi kọkọ duro si ileẹkọ Girama Government Secondary School, Shimfida, to wa ni iwọn kilomita mẹtadinlọgbọn si ilu Jibia.
Sugbọn awọn ara adugbo wa ni iporuru ọkan ni kete ti wọn kẹfin pe awọn wa ninu ewu bayi.
Tori naa awọn ara abule naa ba bẹrẹ si ni ko ẹru wọn, ti wọn si sa lọ sawọn ilu to sunmọ wọn.
Amọ awọn to sẹku sẹyin kan agbako ikọlu awọn janduku yii ti ọmọde meje si padanu ẹmi wọn ninu wọduwọdu to waye.
Titi di akoko taa ko iroyin yi jọ, a ko ti ri atẹjade kankan lọdọ ijọba tabi ileesẹ ọlọpaa.




















