Visa ban: Àṣìgbọ́ ló ṣe okùnfà àhésọ ìròyìn pé UK kò ní fún ọmọ Nàíjíríà ní físà mọ́

Oríṣun àwòrán, Others
Ìwádìí ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìròyìn tó gbòde wí pé ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti gbégi dínà fífún àwọn ọmọ Nàìjíríà ní visa láti lọ ṣiṣẹ́, kàwé tàbí máa gbé ní orílẹ̀ èdè náà jẹ́ ìròyìn irọ́ tó jìnà sí òótọ́.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ìròyìn ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ló fi ìròyìn kan léde lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù kẹta wí pé àwọn ìjọba UK ti gbégi dínà fífún àwọn ọmọ Nàìjíríà ní "visa" fún ìgbà kan ná.
Ìròyìn yìí ló ti da omi tútù sí ọkàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà, tó sì ti ń fa onírúurú awuyewuye.
Àwọn akọ̀ròyìn Nàìjíríà kò gbọ́ wa ye ni:
Nígbà tí ẹka tó ń rí sí fífi ìdí iroyin òtítọ́ múlẹ̀ nileesẹ BBC, ìyẹn "BBC Disinformation Unit" kàn sí ilé iṣẹ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí Nàìjíríà, agbẹnusọ ilé iṣẹ́ náà, Dean Hurlock ní àwọn akọ̀ròyìn ṣi àtẹ̀jáde tí ilé náà fi léde lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun gbọ́ ni.
Hurlock ní àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣì ní àǹfàní láti máa bèrè fún físà fún gbogbo ìpele ohun tí wọ́n bá fẹ́ lọ ṣe ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lórí ẹ̀rọ ayélujára tàbí ní àwọn àjọ wọn.
Ó ṣàlàyé pé òun tí ó wà nínú àtẹ̀jáde náà ni wí pé àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Ukraine tó bá fẹ́ gba físà ní àwọn ń dá lóhùn ní yàjóyàjó nítorí ogun tó ń kojú orílẹ̀ náà látọwọ́ Russia lọ́wọ́.
Ó fi kun pé ìpinu olú ilé iṣẹ́ náà tó wà ní London ní láti ri pé àwọn ọmọ Ukraine nìkan ni wọ́n ń dá lóhùn ní gbọ̀njẹ̀gbọ̀njẹ̀.
- Woléwolé tó sin òkú Timothy Adegoke jẹ́rìí nílé ẹjọ́ lónìí
- Wọ́n tan bàbá 85 kúrò nílé, fọ́ igi mọ lórí, ju òkú rẹ̀ sétí odò l‘Ogun
- Ọ̀rọ̀ di eré ìtàgé, aya gómìnà àná l'Anambra tahùn sí Bianca Ojukwu níbi ayẹyẹ ìbúra fún gómìnà tuntun
- Àwọn tó ń bá mi du ipò ààrẹ ni kò mọ ohun tó kàn fún Nàìjíríà - Tinubu
- Krìsìtẹ́nì àti Mùsùlùmí, ètò ọba jíjẹ àti ìsìnkú ọba kò kàn yín, ẹ jìnnà si - Oníṣẹ̀ṣe l'Ogun
- Wọ́n fi abẹ dá ọgbẹ́ sí Timothy Adegoke lára ni, kí ẹ̀mí tó bọ́ lára rẹ̀ - Onímọ̀ ìwádìí
- "Sylvester Oromoni tọ̀ mí wá pé itan ń ro òun kó tó kú, mo sì ba fi ọwọ́ ra á pẹ̀lú òògùn ara ríro"
- Ìwà àtakò sí ìjọba ní bí ọlọ́pàá bá da iṣẹ́ sílẹ̀, kò tọ̀nà - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
Ó sọ síwájú pé gbogbo orílẹ̀ èdè yàtọ̀ sí Ukraine ni àwọn kò dá lóhùn ní gbọ̀njẹ̀gbọ̀njẹ̀ kìí ṣe Nàìjíríà nìkan.
Bákan náà ló ní òun kò mọ̀ ìgbà tí ìjọba yóò tún ìpunu náà gbé yẹ̀wò.
Bẹ́ẹ̀ náà ló fi kun pé àwọn ń ṣe ohun gbogbo láti ri pé ètò físà gbígbà lọ ní ìrọ̀rùn fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.

















