Proposed Police Strike: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àhesọ̀ ní pé àwọn òṣìṣẹ́ òun kan fẹ́ da iṣẹ́ sílẹ̀

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti sọrọ lori iroyin kan to gbode pe awọn oṣiṣẹ rẹ n mura lati yan iṣẹ lodi.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọhun, Muyiwa Adejobi, fi lede niluu Abuja, o ni iroyin ẹlẹjẹ ni iroyin naa.
Adejobi ni iroyin iyanṣẹlodi naa jẹ ete awọn kọlọrọsi kan lati mọọmọ ba orukọ rere ileeṣẹ ọhun jẹ loju awọn ọmọ Naijiria ni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Afurasí Fulani gé ọwọ́ Fijilańté méjèèjì ni Iwere Ile ni Ipinle Oyo
- Ọ̀pọ̀ òkú ń sùn ní Ukraine, wọ́n ń sin wọ́n ní àsinpọ̀ sí ibojì kan ṣoṣo*
- Ẹ gbà mi o, àwọn oníjìbìtì ayélujára ti ń bèèrè ìrànwọ́ lórúkọ́ mi - Kemi Afolabi lọgun
- "Ẹgbẹ́ àjẹ́ tí mo wà ní Anambra ló ní kí n pa ọmọ ọ̀gá mi l'Eko"
- Ẹsẹ̀ mi yẹ̀ gẹ̀rẹ̀, mo la orí mọ́ táísì, mo sì fẹ́ ẹ̀ pàdánù ọpọlọ nígbà tà ń ya fíìmù - Mide Martins
- Ẹ wo àwọn obìnrin tí kìí ṣe ọmọ Yorùbá tó jẹ́ ayaba ní ààfin ilẹ̀ Káàárọ̀ oòjíire
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tẹ afurasí 11 tó dáná sun ọba nílú Agodo
- "Ọ̀pọ̀ èrò ló ń sá padà láti wọnú ọkọ̀ mi torí ń kò ní ẹsẹ̀ méjééjì"
- Ohun tó fa wàhálà Hijab ní Ijagbo rèé - Olùkọ́ àgbà
- Ipò tí Naijiria wà fi hàn pé inú Ọlọrun kò dùn sí orílẹ̀-èdè yìí - Gani Adams
O ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpaa jẹ eyii ti wọn ni imọ nipa ojuṣe wọn si awọn araalu, wọn si ni ẹkọ to dantọ nipa iṣẹ wọn pe oniruru ọna ni wọn le fi fẹhonuhan si ijọba, amọ iyanṣẹlodi kii ṣe ọkan lara awọn ọna naa.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, o lodi si ofin to gbe ileeṣẹ naa kalẹ, eyii ti awọn oṣiṣẹ na si mọ pe awọn ko le da iṣẹ silẹ.
O fi kun pe gbogbo ete tabi ero lati da eto aabo ilu ru ni yoo lẹyin, awọn ọlọpaa naa si mọ eyii.
Ọga ọlọpaa n se iwuri to yẹ fun ileesẹ ọlọpaa:
Agbẹnusọ ọlọpaa naa ṣalaye pe eto ti n lọ lọwọ lati ṣe afikun owo oṣu atawọn ajẹmọnu awọn ọlọpaa gẹgẹ bii Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe lero rẹ, eyii ti ile igbimọ aṣofin si ti buwọlu.
O ni Aarẹ Buhari funra rẹ lo kede erongba lati ṣafikun owo oṣu atawọn ajẹmọnu ọlọpaa lai ki ṣe pe awọn ọlọpaa funra wọn lo kọkọ bere lọwọ Aarẹ.
Atẹjade naa ṣalaye pe ọga agba ọlọpaa ni Naijiria, Usman Baba n ṣiṣẹ takun-takun lati ri pe afikun owo oṣu naa wa si imuṣẹ.
Adejobi ni Baba n ṣe iwuri fun awọn ọlọpaa nipa ṣiṣe awọn atunṣe kan nileeṣẹ naa bii rira awọn irinṣẹ igbalode fun wọn, to fi mọ awọn ohun elo idaboboaraẹni ati eto ileegbe.
O pari atẹjade naa pe ileeṣẹ ọlọpaa ti n ṣe atunṣe si awọn ile ẹkọ wọn, wọn n ra ayẹta fun awọn ọlọpaa, bẹẹ naa ni wọn n kọ wọn lẹkọọ nipa imọ ẹrọ igbalode.
Ṣaaju ni awọn iroyin kan ti kọkọ gbode pe awọn ọlọpaa fẹ gunle iyanṣẹlodi kaakiri Naijiria nitori bi ijọba ko ṣe tọju wọn daadaa to.
Ti ẹ ko ba gbagbe, lasiko iwọde EndSARS ni awọn ọmọ Naijiria ken ke pe ijọba lati wọ ọna abayọ si bi iya ṣe n jẹ awọn agbofinro ọhun.

















