Gani Adams: Àwọn tó yẹ̀ kó gba Nàíjíríà sílẹ̀ lọ́wọ́ ìdààmú ti yẹsẹ̀ lójú òpó

Oríṣun àwòrán, aareganiadams/Instagram
Aarẹ Onakakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti sọ pe awọn ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria fi han inu Ọlọrun ko dun si orilẹ-ede yii.
Adams lo sọ ọrọ naa niluu EKo nibi iṣide ayẹyẹ ọdun Eledumare.
O ni eto naa waye lati bọwọ fun ati lati wa ojurere Ọlọrun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹsẹ̀ mi yẹ̀ gẹ̀rẹ̀, mo la orí mọ́ táísì, mo sì fẹ́ ẹ̀ pàdánù ọpọlọ nígbà tà ń ya fíìmù - Mide Martins
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tẹ afurasí 11 tó dáná sun ọba nílú Agodo
- "Ọ̀pọ̀ èrò ló ń sá padà láti wọnú ọkọ̀ mi torí ń kò ní ẹsẹ̀ méjééjì"
- Ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ! Ìyá ọmọ́ yọjú pé ‘Dispatch Rider’ tí wọn ká ọmọ mọ́ lọ́wọ́, kìí ṣe gbọ́mọ-gbọ́mọ
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí adigunjalè márùn ùn níbi tí wọn ti ń jalè ní Ogere
- Ọ̀nà ti di fáwọn tó kúndùn láti máa yí èsì ìdìbò - Makinde
Gẹgẹ bii ohun to sọ, eto naa lagbara lati mu ayipada ba eto ọrọ aje Naijiria to dẹnukọlẹ, yoo tun mu ilọsiwaju ba orilẹ-ede ti awọn eeyan ba le maa ṣe otitọ ati ododo.
Aarẹ Onakakanfo tun sọ pe akoko ti to fun atunto iṣejọba orilẹ-ede Naijiria ki orilẹ-ede naa ma ba dawo.
O ni "O ṣoro fun wa lati ni itẹsiwaju kankan bi nnkan ṣe ri lọwọ yii… Ojojumọ ni gbogbo nnkan n dagẹgẹ si."
"Gbogbo awọn to yẹ ko yọ Naijiria ninu laasigbo to wa, ni wọn ti yapa kuro loju ọna ti wọn ti fi ẹsẹ le ṣaaju."
Adams, to jẹ ọkan gboogi lara awọn to n lewaju ajọ Olokun Festival Foundation, OFF, rọ ijọba ni ẹlẹkajẹka lati boju aanu wo awọn alaini.
Nigba to n sọrọ nibi eto naa, Muyiwa Osinaike sọ pe ọdun naa ṣe pataki lasiko yii nitori bi nnkan ṣe n lọ.
O ni "Ti wọn ba le maa ya awọn ọjọ sọtọ lati ṣe ayẹsi awọn oriṣa, ko si ohun to ni ki a ma ya ọjọ kan naa sọtọ lati juba Ọlọrun da ọrun ati aye ni ara ọtọ."
Ẹwẹ, kii ṣe igba akọkọ ree ti Iba Gani Adams yoo pe fun atunto iṣejọba Naijiria.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ Yoruba kan sọ pe iyapa lawọn n fẹ, Gani Adams ninu ero rẹ gbagbọ pe atunto ni ọna abayọ si isoro ti orilẹ-ede yii n dojukọ.

Amotekun náwọ́ gán àwọn afurasí ìgárá ọlọ́ṣà mẹ́jọ l'Osun

Oríṣun àwòrán, Others
Ọjọ́ gbogbo ni tolè, ọjọ́ kan báyìí ni ti olóhun.
Ọwọ́ ṣìnkún àjọ ẹ̀ṣọ́ aláàbò Amotekun ti tẹ àwọn afurasí gẹ́gẹ́ bí ìgárá ọlọ́ṣà, a lọ kólóhun kígbe ní ìpínlẹ̀ Osun.
Gẹ́gẹ́ bí adarí ikọ̀ Amotekun ìpínlẹ̀ Osun, Amitolu Shittu ṣe sọ, àwọn afurasí náà ló ti ń ṣọṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Osun àti agbègbè rẹ̀ láti ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ọmọ Yorùbá mẹ́ta àti gbajúmọ̀ míì tó ní Lupus, àrùn tó n bá Kemi Afolabi fínra
- Ọmọdé méje kú, ọ̀pọ̀ farapa nígbà tí ọ̀rọ̀ di bóòlọ, ko yàgò fún mí
- Portable Zazzu pariwo pe wọ́n ti dá ọjọ́ méje pé òun yóò kú
- Wo ọmọ Yorùbá mẹ́ta àti gbajúmọ̀ míì tó ní Lupus, àrùn tó n bá Kemi Afolabi fínra
- Àlùfáà ìjọ gbé egbògi olóró “cocaine”, ó kó sí gbaga NDLEA
- "Èèdì àti ogun ayé ni awọn èèyàn n rò pé ó mú mi bí ìbejì ní ìgbà mẹ́fà"
- Ọjọ́ Ajé la bẹ̀rẹ̀ ìpè fún ìdásílẹ̀ Yoruba Nation padà - Akintoye
- Ìjàmbá ọkọ̀ tún gbẹ̀mí ènìyàn mẹ́tàlá ní òpópónà márosẹ̀ Ilorin sí Ogbomoso
- Mo ṣèlérí pé n kò ní já Ibadan àti Nàìjíríà kulẹ̀- Olúbàdàn tuntun, Ọba Lekan Balogun Ali Okùmádé kejì
- Wo ibi tí ọ́rọ́ ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha dé dúró báyìí láti osù kẹrin, ọdún 2021
Amitolu ṣàlàyé fún àwọn akòròyìn pé àwọn mẹ́jọ ni àwọn afurasí tí ọwọ́ tẹ̀ náà, tí wọ́n sì wá láti ìpínlẹ́ káàkiri orílẹ̀ èdè yìí láti wá ṣe ọṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Osun.
Àwọn afurasí náà ni Adekunle Joseph láti Iragbiji, ìpínlẹ̀ Osun, Uchenna Alom láti Anambra ṣùgbọ́n tó ń gbé ní Idi-Iroko Sasa, ìpínlẹ̀ Ogun, Monday Nweke lati Ebonyi, tó ń gbé ní Ketu ìpínlẹ̀ Eko.
Àwọn yóòkù ni Sikiru Kareem lati Ikire, Oyekanmi Maruf láti Modakeke, Adebayo Tobi láti Iwo, Ifeanyi Njoku láti Ebonyi àti Olanrewaju Emmanuel láti Ipetu-Ijesa.
Báwo ní ọwọ́ ṣe tẹ̀ wọ́n?
Amitolu ṣàlàyé pé ní ilé ìtura kan ní ìlú Modakeke, ìjọba ìbílẹ̀ ìlà oòrùn Ife, ìpínlẹ̀ Osun ni ọwọ́ ti tẹ́ àwọn afurasí náà.
Ó tẹ̀ síwájú pé olobó kan ló ta àwọn pé àwọn afurasí náà ń gbèrò láti lọ ja ilé ìtajà kan ní Ilesa, kí àwọn tó lọ káwọn mọ́ ibi tí wọ́n lúgọ sí láti ṣe iṣẹ́ náà.
Bákan náà ló ní àwọn afurasí náà ti jẹ́wọ́ wí pé àwọn ti jalè ní àwọn agbègbè kan ṣaájú àkókò yìí.
Bẹ́ẹ̀ náà ló ní àwọn ti fi wọ́n lé àwọn agbófinró lọ́wọ́ fún ìwádìí tó péye àti fífi ìyà tó tọ́ jẹ wọ́n.



















