General Overseer arrested for drugs: NDLEA fi àlùfáà ìjọ tó gbé egbògi olóró sí àhámọ́

Egbògi olóró

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Egbògi olóró

Àjọ tó ń gbógunti lílo egbògi olóró ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, NDLEA ti nawọ́ gán àlùfáà àti olùdásílẹ̀ ilé ìjọsìn Christ Living Hope Church, Ugochukwu Emmanuel fẹ́sùn gbígbé egbògi olóró "cocaine".

Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ àjọ NDLEA, Femi Babafemi fi léde lọ́jọ́ Àìkú ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹta, ọdún 2022 ní pápákọ̀ òfurufú Muritala Muhammed International Airport ni ọwọ́ ti tẹ olórí ìjọ náà.

Babafemi ní ọwọ́ tẹ̀ Ugochukwu ní ọjọ́ Ajé tó kọjá nígbà tó fẹ́ wọ bàálù lọ sí orílẹ̀ èdè Kenya láti lọ kópa níbi ètò ìsọjí ọlọ́sẹ̀ mẹ́ta ní Nairobi.

Ó ṣàlàyé pé nígbà tí àwọn ń ṣe àyẹ̀wò fún àwọn tó fẹ́ wọ bàálù ni àwọn bá egògi tí àlúfàá náà sọ mọ ara lọ́nà mẹ́rìnléláàdọ́ta káàkiri ara rẹ̀.

Àkọlé fídíò, Mi ò kí ń ṣèèyàn burúkú tàbí Babalawo bí ẹ ṣe mọ̀ mí nínú eré - Fadeyi Oloro

Ó fi kun pé Ugochukwu, nígbà tí àwọn ń fi ọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò jẹ́wọ́ pé níbi ètò ìsọjí tí òun ń lọ ní Nairobi fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta náà ni òun ti fẹ́ lo àwọn egbògi náà.

Ní ìlú Isuaniocha, òpópónà Mgbakwu, Awka, ìjọba ìbílẹ̀ Árìwá Akwa, ìpínlẹ̀ ni olú ilé ìjọsìn Christ Living Hope Church wà.

Àkọlé fídíò, Mọrèmi: Ọọ̀ni ní láìsi Mọrèmi, kò leè sí ilẹ̀ Yorùbá

Bákan náà ni wọ́n ní ẹ̀ka ní ìlú Abuja àti ìpínlẹ̀ Eko.