Baba Ijesha, Olanrewaju Omiyinka: Wo ibi tí ọ́rọ́ ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha dé dúró báyìí láti osù kẹrin, ọdún 2021

Leyin gbogbo atotonu ni ile ejọ́ lonii ni Adájọ́ sún ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha sí ọjọ́ kínní, oṣù tó ń bọ
Adájọ́ ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹ̀sùn ìfìyàjẹni àti ìbálòpọ̀ tó wà ní Ikeja nílùú Eko, Taiwo Taiwo tún ti sún ìgbẹ́jọ́ òṣèré tíátà James Olanrewaju tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Baba Ijesha sí ọjọ́ kínní, oṣù tó ń bọ ọdún tí a wà yìí.
- Dókítà ní ọdún márùn-ún ló kù fún mi láyé, mo sì ti lò lára rẹ̀ - Òṣèré Kemi Afolabi
- Àwọn gómìnà 'yahooyahoo' ní APC ló ń ti Buni láti da ojú ètò ìdìbò adarí ẹgbẹ́ bolẹ̀ - Gómìnà Rotimi Akeredolu
- Lẹ́yìn tí wọ́n gba ipò alága NURTW lọ́wọ́ rẹ̀, MC Oluomo yapá kúró ní NURTW
- Ìrírí tí Ilana Omo Oodua àti Sunday Igboho rí lósù mẹ́fà yìí tí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ síi- Ojogbon Banji Akintoye
Kini o sele nile ejọ́ lonii?
Níbi ìgbẹ́jọ́ tó wáyé lónìí, àwọn agbẹjọ́rò Baba Ijesha gbé ajẹ́rì Onímọ̀ nipa ihuwasi eda ti oruko rẹ̀ n jẹ́ Olugbemi Olukolade láti wá wo lára àwọn fọ́nrán tó wà nílé ẹjọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí.
Nínú fọ́nrán ọ̀hún tí ilé ẹjọ́ gbé síta fún Ọ̀mọ̀wé Olugbemi láti yẹ̀wọ̀, ọmọdébìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tí wọ́n ní Baba Ijesha bá ṣe aṣemáṣe wà nínú yàrá kan pẹ̀lú Onímọ̀ nipa ihuwasi eda níbi tí wọ́n ti fọ̀rọ̀wálẹ́nuwò lórí nǹkan tó ṣẹlẹ̀ síi.
Ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò Baba Ijesha béèrè lọ́wọ́ Olugbemi gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tó ń ṣe pé ṣó tọ̀nà fún ọmọ ọdún mẹ́rìnlá láti rántí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ sí lọ́dún méji ṣẹ́yìn bí i pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ síi àti pé ṣe ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà tọ ìlànà iṣẹ́ wọn.
Olugbemi sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn nkankan wà nínú fọ́nrán ọ̀hún tí ẹ́ni tó béèré àwọn ìbérè ọ̀hún kookù díẹ̀ káàtọ́ nígbà tó ń ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà.
Olugbemi tún tẹ̀síwájú pé bí ọmọ ọ̀hún ṣe ń ṣàlàyé nǹkan tó ṣẹlẹ̀ síi, ó dàbí pé ò n rọ́ ìtàn àti fún ọjọ́ orí rẹ̀, kó leè rántí gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ ọdún méje sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ̀rọ̀ nínú fọ́nrán náà.
Agbẹjọ́rò Baba Ijesha sọ fún BBC Yorùbá pé àwọn sì ní ajẹ́ri kan síi láti mú wá sí ilé ẹjọ́ ní ọjọ́ kínní, oṣù tó ń bọ̀ ọdún tí a wà yìí tí Adájọ́ Taiwo sún ìgbẹ́jọ́ náà sí.
















