Sunday Igboho released: Ìdọ̀bálẹ̀ gbalaja ní Igboho wà tó ń dúpẹ́ pé mo mú ìlérí mi ṣẹ- Oloye Banji Akintoye

Sunday Igboho pẹlu jọgbọn Banji Akintoye

Oríṣun àwòrán, Others

Ojogbon Banji Akintoye alaga Ilana Omo Oodua naa ti sọ̀rọ̀soke lori itusile Oloye Sunday Igboho

Bẹ́ẹ̀ iriri kọ́ja ẹgbẹ́ abewu ni awọn agba n sọ nilẹ̀ Yoruba.

Ninu ọrọ Oloye Banji Akintoye, o kin ọrọ ti amofin Falọla to jẹ ọkan lara awọn agbẹjọro Oloye Adeyemo leyin.

O ni awọn ẹ̀kọ́ ti ọmọ ẹgbẹ́ Ilana Omo Oodua ti kọ́ losu mẹ́fa sẹ́yin ti kọ́ wa pelu Sunday Igboho ni ẹ̀kọ́ to pọ̀.

Ati pe ọ̀pọ̀ alangba lo danu delẹ̀, a ko mọ́ eyi ti inu n run ni awọn agba n sọ.

O ni pe kii ṣe nitori ilera rẹ ni wọn tori rẹ tu u silẹ bikoṣe pe awọn ijọba ilẹ Benin ti rii pe ko lẹṣẹ lọrun tako orilẹede wọn.

Kini Ojogbon Banji Akintoye tun so?

Baba Akintoye ṣalaye siwaju sii pe itusilẹ Sunday Igboho ti tubọ fi imọlẹ han si ibi ti ọna ọmọ iran Oodua yoo gba.

Àkọlé fídíò, Fire Eater: Azonto ní àfojúṣùn òun ni láti lọ fi idán iná yìí pa owó lókè òkun

Olori ẹgbẹ ilana Ọmọ Oodua pẹlu ṣalaye pe iriri pọ laarin oṣu mẹfa ti Sunday Igboho lo ni ahamọ orilẹede benin Republic.

"A ti rí ilé ti à ń lọ lọ́ọ̀kán báyìí díẹ̀ ló kù".

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ó yẹ kí Buhari pé Igboho bíì bàbá s'ọ́mọ ni; Láyé! Kò sẹ́ni tí kò ni jèrè i

A ti rí ilé ti à ń lọ lọ́ọ̀kán báyìí díẹ̀ ló kù - Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye lásíkò àjọyọ̀ ìtúsílẹ̀ Sunday Igboho

O ni bi ilakaka ṣe n lọ lati tu Sunday Igboho silẹ ni ahamọ to wa ni awọn eeyan kan kaakiri agbaye pẹlu n lo orukọ ajafun idasilẹ orilẹede Yoruba naa lati pa owo si apo ara wọn.

Sunday Igboho pẹlu jọgbọn Banji Akintoye ati Ọjọgbọn Wale Adeniran

Oríṣun àwòrán, others

Ọjọgbọn Akintoye ni orukọ rere ati iyi ti awọn agbaagba ilẹ Yoruba kan ni ni wọn lo lati fi ṣeto itusilẹ rẹ lorilẹede Benin republic.

"Awọn eeyan kan n sọ pe ara rẹ ko le, irọ patapata ni, alaafia lo wa."

Àkọlé fídíò, Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà

O ni jijade ti Sunday Igboho jade bayii lẹwọn, idọbalẹ gbalaja lo mu to fi ọrọ sẹnu to si dupẹ fun aduroti oun atawọn agbaagba Yoruba yoku.

Igboho n pe: "Baba mi, O dẹ duro naa lati iye ọjọ́ yii.

O sọ pe oo ni kuro ni ilu yii titi di igba ti wọn ba tu mi silẹ.

Ẹ o dẹ lọ naa lati igba yii wa."

Àkọlé fídíò, 'Hááà! Bamise mà jìyà o, ó l'óun á mu mi kúrò nílé àyágbé àmọ́ ó wá di ẹni tí wọ́n yọ pátá lára rẹ̀'

Agbẹjọro fun Sunday Igboho ilu Bẹnin Republic, Amofin Falola

"Ko si ṣẹkẹṣẹkẹ idiwọ kankan mọ fun eekan aṣiwaju ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho lorilẹede Benin Republic".

Agbẹjọro fun Sunday Igboho ilu Bẹnin Republic, Amofin Falola lo sọ bẹẹ fun awọn akọroyin lọjọ Iṣẹgun.

Amofin Falọla ni lootọ o ṣi wa labẹ abo ijba lorilẹede Benin, ṣugbọn kii ṣe nitori ẹṣẹ kankan bikoṣe nitori a ti daabo bo o titi di igba ti yoo fi fi orilẹede naa silẹ lọ silẹ okeere.

Amofin Falọla, ọkan lara awọn agbẹjọro Igboho lorilẹede Benin, ṣalaye pe kii ṣe itusilẹ lati lo gba itọju ilera ni won fun un.

O ni bikoṣe itusilẹ patapata lẹyin ti ijọba orilẹede naa rii daju pe ko ṣẹ ẹṣẹ kankan nibẹ ko si si idi kan fun wọn lati ṣi maa fi si ahamọ.

Sunday Igboho pẹlu jọgbọn Banji Akintoye ati Ọjọgbọn Wale Adeniran

"Ko lee pada lọ si ilu Naijiria to ti wa lọwọ yii, yoo ṣi maa wa nilu Benin naa titi ti yoo fi tẹsiwaju lọ si ilẹ okeere, iyẹn orilẹede Germany to fẹ lọ."

Àkọlé fídíò, Dapo Abiodun ò sọ fún mi pé òun á dupò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì o, èmi nàá ò kẹ̀rẹ̀ nínú òṣèlú láti kékeré - Modele Sarafa-Yusuf