Pig Heart Surgery man dies: Kí ló padà fa ikú ọkùnrin àkọ́kọ́ tó ṣàṣeyọrí lílo ọkàn ẹlẹ́dẹ̀ láti mi ti padà kú o!

Oríṣun àwòrán, University of Maryland School of Medicine
Awaye -e -ku kan ko si, ko sẹni ti ko ni lọ!
Ṣe ẹ ranti iroyin to gbode kan nipa ọkunrin kan ti wọn gbe ọkan Ẹlẹdẹ si ipo to yẹ ki ọkan eeyan wa lara rẹ ko baa le mi?
David Beneth ni iku ti papa mu lọ bayii, o ni aisan ti oloyinbo n pe ni terminal disease tẹlẹ amọ ti si ye e lẹyin to ṣe iṣẹ abẹ ni US.
Amọ, aarẹ to muu bẹrẹ si ni buru sii ni bii ọjọ diẹ sẹyin, dokiya rẹ ni Baltimore lo kede pe ọkunrin naa ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin dagbere faye ni ọjọ Kẹjọ oṣu Kẹta.
Ọgbẹni Beneth ti baba mọ ewu to wa ninu iṣẹ abẹ naa eyi to ṣe toun naa si gba ki wọn to dawọ le e pe "ọja okunkun ree o".
Awọn dokita ni Fasiti Maryland ri aaye ati aṣẹ gba latọdọ awn alabojuto eto ilera US pe ki wọn ṣe iṣẹ abẹ naa latari pe Ọgbẹni Bennett ko ni lee gba ọkan ọmọ eniyan sara - iba ti ku bi wọn ko ba lo ti ẹlẹdẹ.
O ti wa lori akete aisan fun ọsẹ mẹfa eyi to fa a to fi ṣe iṣẹ abẹ naa eyi ti wọn gbe si ara ẹrọ oni ina to n ran an lọwọ lati ṣiṣẹ ki arakunrin naa le wa laaye.
Ọjọ Keje oṣu Kini ni Ọgbẹni Bennett ṣe iṣẹ abẹ naa, awn dokita si sọ pe laarin awọn ọsẹ to tẹle iṣẹ naa, arakunrin yii wa pẹlu ẹbi rẹ daadaa, wọn jọ ṣere, wo sinima, to si tilẹ n sọ pe oun fẹ tete dele lọ ri aja oun, Lucky.
Ẹwẹ, nigba ti aisan naa bẹrẹ si ni wọra sii, o fun awọn dokita naa ni idamu ọkan.
"O fihan pe Akin ọkunrin ni to si jẹ alaarẹ to ja fitafita titi de opin", dokita to ṣe iṣẹ abẹ naa, Bartley Griffith sọ ninu atẹjade ti ileewosan naa fi sita.
Ọmọ oloogbe, David Jnr. ni "a dupẹ fun gbogbo akoko to wa to wu ni lori, eyi to fẹ yi eeyan lori, ọjọ ailesun loru ti a la kọja lasiko yii".
Dokita Griffith ti ṣaaju sọ pe iṣẹ abẹ yii yoo tun sun awọn eeyan pẹlu igbesẹ kan si adinku riri ọkan lo. "Lọwọlwọ, eeyan mẹtadinlogun lo n ku lojumọ kan ni US to jẹpe wọn n duro de ati ri kan ti wọn a ṣaa fi maa mi ti o si le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun to ṣi n duro.
Anfani ati lo ọkan ẹranko fun iru nkan bayii lati di alafo to ṣi silẹ jẹ ohun ti wọn ti n gbero tipẹ.
Lọdun 2021, awn dokita ni New York kede pe awn ti ṣe aṣeyọri gbigbe ọkan ẹlẹdẹ si ara eeyan kan torinaa o ti wọpọ bayii
"Iṣoro ta n ri nipa lilo ọkan Ẹya ara nkan mii si omiran ni a n pe ni "hyperacute rejection". Ara ọmọ eniyan n ri ẹya ara mii bii ajoji eyi ti yoo si mu ko maa pa ẹya ara ọtọ naa laarin iṣẹju melo kan".
Amọ ireti wn ni pe mẹwaa ninu ọkan ẹlẹdẹ ti wọn ba gbe si ara eniyan yoo ṣaṣeyọri ti agọ ara ẹni naa yoo si gba a laye.
"Nigba ti mo ba awọn ikọ to ṣiṣẹa bẹ naa sọrọ lẹyin oṣu kan ti Bennett kuro nileewosan, wọn ni ko sohun to jọ pe ara rẹ kọ ọ ti ọkan ẹlẹdẹ ti wn gbe si i lara naa si n ṣiṣẹ daadaa bii ti "ẹnjiini ọkọ Ferrari". Ṣugbọn wọn kilọ pe Ọgbẹni Bennett funrarẹ ṣi n bẹru.
Ohun to ṣẹlẹ tẹlẹ to fa iku Ọgbẹni Bennett gangan ko tii ye. Wọn n ṣe awọn ayẹwo yii lọwọ eyi tii yoo ṣafihan anfani lilo ọkan ẹlẹdẹ pẹlu aṣeyọri lọjọ waju ti ẹlẹdẹ yoo le maa jẹ ọna abayọ fun yiyọ ọkan sira.
Bawo ni wọn ṣe ṣe iṣẹ abẹ ọkan Ẹlẹdẹ naa si ara Bennett?
Ọkunrin ọmọ orileede Amerika kan, David Bennett, ti di ẹni akọkọ l'agbaye ti awọn dokita yoo paarọ ọkan rẹ si ti ẹlẹdẹ lati ipasẹ isẹ abẹ to lagbara.David Bennett, eni odun mẹtadinlọgọta ni ara rẹ ti n m'okun lẹyin ọjọ mẹta ti iṣẹ abẹ oniwakati meje naa waye nilu Baltimore.Awọn dokita nile iwọsan fasiti Maryland gba asẹ lati ọwọ igbimọ to n s'akoso eto ilẹra ki wọn to ṣe iṣẹ abẹ naa.
Idi ni wipe ọgbeni Bennett ni aisan okan aṣekupani to le yọri si iku, ti iṣẹ abẹ naa ko ba waye.Awọn akọṣẹmoṣẹ ti sọ saaju pe alaisan naa ko le gba ọkan eeyan, eleyi to jẹ igbesẹ ti awọn dokita maa n gbe nigbati aisan ọkan alaarẹ kan ba l'agbaraẸlẹdẹ, ti wọn se atunse iseda re pẹlu iwadii imọ isegun igbalode, ni awọn dokita ti yo gbogbo ohun to le tako ẹjẹ Bennett kuro lara rẹ, ki wọn to se ise abẹ naa.
Gẹgẹ bi olori ikọ awọn dokita to ṣe iṣẹ abe naa,Bartley Griffith se wi, aṣeyọri iwadi imọ isegun fun ọpọlọpọ ọdun ni isẹ abẹ naa jẹ, eleyi ti yoo mu ayipada de ba igbesi aye awọn eeyan kaakiri agbaye.Nigba to n ba BBC sọrọ, Griffith sọ pe isẹ abẹ naa yoo tubọ sun iran ọmọniyan mọ wiwa ọna abayọ si isoro aito eya ara fun iwosan awọn alaarẹ.

















