Bamise Ayanwola missing in Lagos BRT: Irọ́ ni pé wọ́n gbé ìbọn sí dẹ́rẹ́bà yẹn léti, oun tó ṣẹlẹ̀ gangan bí Bamise ṣe wọ ọkọ yẹn rèé

Àkọlé fídíò, 'Hááà! Bamise mà jìyà o, ó l'óun á mu mi kúrò nílé àyágbé àmọ́ ó wá di ẹni tí wọ́n yọ pátá lára rẹ̀'

Ọrọ iku Bamise Ayanwola to di awati ninu ọkọ akero ijọba BRT l'Eko ti n di eyi ti gbogbo eeyan n da si tayọ orilẹede Naijiria nikan bayii.

Lẹyin ti ariwo pe wọn n wa a jade lori ayelujara ni oriṣiriṣi nkan ti n ṣẹlẹ.

Ko pẹ, iroyin jade o si de ọdọ awọn ẹbi rẹ pe wọn dede ri oku rẹ loju popo ti wọn ni wọn ti yọ kuro lara ẹya ara rẹ lọ.

Iya Bamise

Oríṣun àwòrán, Yetunde Olugbenga

Kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Abiodun Alabi sọ ninu ọrọ rẹ fun awọn oniroyin pe oun ati mọlẹbi Bamise kan lawọn jọ lọ ṣe ayẹwo ti awọn si ri i pe wọn ko yọ ẹya ara rẹ kankan lọ.

Ẹwẹ, bẹẹ kọ ni ọrọ ri ninu ifọrọwanilẹnuwo BBC Yoruba pẹlu iya, baba ati ẹgbọn rẹ. Ariwo bi wọn ṣe da ẹmi Bamise legbodo ti wọn ko jẹ ko mu ileri rẹ ṣẹ fun iya rẹ ni wọn n pa nile.

"Oluwabamise jẹ ayanfẹ ọmọ mi, ẹni ti inu mi dun si gidigidi, Bamise jẹ iya, Oluwabamise jẹ iya o fara da ohun gbogbo".

Arabinrin Comfort Ayanwola n wa ẹkun mu ni pe awọn ti ro pe awọn yoo ri eso titọ ọmọ ka tori awọn ko tilẹ nile lori.

Ara adugbo Bamise

O banujẹ pe kii ṣe pe Bamise wọ ọkọ sọọlẹ bikose ti ijọba.

Eyi to tun wa mu ki iya Bamise ki ọrọ ti eti ko gbudọ bọ bọ ẹnu to fi n ranṣẹ si awọn to pa ọmọ rẹ ni pe o ṣi gbagbọ ninu iroyin to gbọ pe wọn bọ awọtẹlẹ abẹ ọmọ rẹ.

Ẹgbọn Bamise obinrin ni irọ ni dẹrẹba pa pe wọn gbe ibọn si i lọrun.