Sunday Igboho: Ó yẹ kí Buhari pé Igboho bíì bàbá s'ọ́mọ ni; Láyé! Kò sẹ́ni tí kò ni jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lórí Sunday Igboho
"Ara aiṣootọ wa ni pe ki wọn mu iru Sunday Igboho si atimọle".
Ọba meji lo wa ni ilu Ikere-Ekiti to wa ni ipinlẹ Ekiti amọ bo tilẹ jẹ pe abẹ sanmọ ilu kan naa ni wọn wa, ero wọn ṣe ọtọọtọ lori ọrọ iijagbara fun Yoruba Nation eyi ti ilumọọka ajijagbara Sunday Igboho n dari.
Ni ti Ọba Adejimi Adu to jẹ Ogoga ti ilu Ikẹrẹ, o gba pe ni tootọ ko si onilu ti yoo fẹ ki ilu rẹ bajẹ torinaa aarẹ Buhari ko fẹ ki Naijiria bajẹ ni.
O ni gẹgẹ bii Baba ti Buhari jẹ fun gbogbo orilẹede, ṣe lo yẹ ko pe Sunday Igboho gẹgẹ bi ọmọ rẹ ko baaa sọrọ lori nkan to n bi i ninu ki wọn si jọ pawọpọ.
Ọba Adejimi gba pe ifọrọjomitoro ọrọ lo yẹ ko waye laarin ijọba ati Sunday Igboho kii ṣe ija.
'Hááà! Bamise mà jìyà o, ó l'óun á mu mi kúrò nílé àyágbé àmọ́ ó wá di ẹni tí wọ́n yọ pátá lára rẹ̀'
Olukẹrẹ ti Ikẹrẹ, Ọba Ayodele Obasoye ni tirẹ duro digbi pe ko yẹ ki Naijiria tilẹ ronu ati fi Sunday Igboho sẹwọn rara.
"Awọn kan wa nilẹ Hausa loni ti wọn n ṣatilẹyin fawọn to n gbebọn". Ọba Ayodele ni ṣebi awọn ijọba naa rii daju pe awọn Fulani wa ninu igbo nigba naa lọhun ti Sunday Igboho ni Yoruba o le laju silẹ ki awọn Fulani maa pa wọn lọ ninu igbo.
O ni Igboho koro oju si ipaniyan ati ifipabanilopọ ni agbegbe rẹ ni, kii ṣe pe o ko ogun si Naijiria ti wọn wa n muu la gbogbo nkan toju rẹ n ri yii kọja.
Awọn Ọba mejeeji yii to n ṣolori lori ilu kan naa ba BBC Yoruba sọrọ nipa idi ti wọn fi ni erongba ọtọọtọ lori ija fun iyapa ẹya Yoruba kuro lara orilẹede Naijiria.

