Oba Matthew Jegede Deeper life pastor king: Bí ìjọ ṣe kẹ̀yìn sí mi nígbà tí mo fẹ́ di Ọba Ahan Ayegunle àmọ́ tí wọ́n wá fún ìwúyè mi

Àkọlé fídíò, Ṣé ó lòdì sí òfin Ọlọ́run kí Krìstẹ́ni jẹ Ọba ilẹ̀ Yorùba? Pásítọ̀ ìjọ Deeper Life sọ ìran tó rí tó fi gbà láti jẹ Ọba

"Mo kọkọ ro pe o lodi si ilana Ọlọrun lati di Ọba amọ... Mo tun ro pe teeyan ba fẹ de ọrun, yoo nira".

Ọba Mathew Jegede, Alahan ti Ahan Ayegunle, Ekiti jẹ ọmọ ijọ Deeper Life Bible Church koda, Pasitọ ni.

O ṣalaye bo ṣe ya a lẹnu pe gbogbo awọn ọmọ ijọ rẹ to kọkọ lodi si ko jẹ Ọba pada peju sibi ayẹyẹ gbigba pa aṣẹ rẹ.

Ilu Ahan

Gẹgẹ bo ṣe sọ, odidi ọdun mẹwa lo ti fi sa ti ko fẹ bọ sori itẹ nitori ilana ati aṣa inu ijọ to n lọ eyi to ni o lodi si ohun gbogbo to ba ni ṣe pẹlu aṣa ibilẹ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba, Ọba Matthew ni oun pada gba lati di Ọba o si tun sọ iriri rẹ ni asiko ti wọn n ṣe aṣa iṣẹẹṣẹ to yẹ fun Ọba ko to gba ade.

"Ipo ti ilu mi wa nigba naa jẹ ipo to lagbara ti ẹnikẹni ko le dede kori bọọ pe oun fẹ jẹ Ọba".

O ni ipo naa ko mu inu eeyan dun o dẹ n ba ni lẹru torinaa o ba oun naa lẹru.

Ni ede tirẹ bayii, o ni gbogbo Ọba ba n sọ pe ni Ile Ifẹ ni Yoruba ti ṣan wa, oun maa n sọ pe ni toun, Ọlọrun lo ṣẹda rẹ.

Iyalẹnu lo jẹ fun un wipe lọjọ to gba ọpa aṣ ti Gomina Fayemi gbe fun un, gbogbo ọmọ ijọ rẹ lo peju sibẹ.