Sunday Igboho: Olubadan yóò gbèjà Sunday Igboho dandan ni gẹ̀gẹ́ bí ọmọ - Ẹ̀ẹ̀kẹfà Olubadan, Olóyè Lekan Alabi

Sunday Igboho: Olubadan rán àwọn asojú lọ sí ìlú Benin fún ìgbẹ́jọ Sunday Adeyemọ

Kii ṣe tuntun o ti Ibadan ba dide lati gba ilẹ Yoruba silẹ lọwọ awọn amunisin, idi si niyi ti Olubadan ti ilẹ Ibadan fi gbe igbimọ dide lọ si orilẹede Benin lori ọrọ igbẹjọ Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.

Ọrọ ti awọn ọmọ igbimọ ti Olubadan gbe dide naa fi to BBC News Yoruba leti niyi.

Ni ọjọ Aiku ni Ọba Adetunji ti ilu Ibadan gbe igbimọ kan dide lọ si orilẹede Benin gẹgẹ bi iroyin ṣe gbe e sita.

Ẹkẹẹfa Olubadan ti ilẹ Ibadan, Oloye Lekan Alabi ṣalaye pe kii ṣe tori iwọde tawọn ọdọ kan ṣe lọ si ọdọ kabiyesi Olubadan laipẹ yii ni Obalaye naa fi gbe igbesẹ to gbe.

Àkọlé fídíò, Mo fi sánmọ̀ àti ilẹ̀, Mecca àti Medina búra pé Sunday Igboho kò sí nínú ewu níbí - Èèyan Igboho ní Cotonou

"Kii ṣe iṣẹlẹ naa lo ṣẹṣẹ mu ki Kabiyesi da si ọrọ Sunday Igboho. Ọmọ kabiyesi ni Oloye Sunday Igboho ṣugbọn a ko lee maa sọ fun yin gbogbo awọn igbesẹ ti wọn gbe. Ẹnikẹni to ba ti fọwọ si abẹ iya rẹ, ọmọ Ibadan ni, dandan si ni ki a gbeja rẹ."

Bakan naa lo fi kun un pe awọn to n fi ẹsun ọdalẹ kan Yoruba jẹ awọn to ni ẹtanu ilẹ Yoruba.

O ni itan nipa Yoruba ati Naijiria nipa awọn eeyan bii Adegoke Adelabu, Adekunle Fajuyi, Benjamin Adekunle ati bẹẹbẹ ls fihan pe ẹni ti Yoruba ba duro ti, wọn maa n duro tii titi de opin ni.

Ìdí tí Olubadan fi rán àwọn asojú lọ sí ìlú Benin fún ìgbẹ́jọ Sunday Adeyemo Igboho

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Timi Orokoya ní orin Iléyá tí òun kọ lọ́dún 28 sẹ́yìn, ló padà wá ṣẹ báyìí

Lílọ bíbọ lati ilé ẹjọ́ sí pàda nílùú Kotonu ti ṣe díẹ̀ báyìí, nítorí náà ni Olubadan ti ìlú Ibadan Oba Saliu Akanmu Adetunji, Aje Ogungunniso àkọ́kọ́ ti ran awọn ènìyàn lọ ilu Benin.

Kókó ìdí tó fi rán wọn lọ ni láti mójú tó ìgbéjọ ti yóò wáyé nílé ẹjọ́ lónìí lórí Oloye Sunday Adeyemọ ti ìjọba Naijiria fẹ̀sun kan pé ń ko ibọ n wọlé ni Nàìjíríà.

Ọbá alayé náà, ti kò ṣàlàyé irú àwọn tó rá ni iṣẹ náà ṣàlàyé pé lábẹ́ àkóso bi ó ti wù kí o rí, àwọn ènìyàn náà yóò péjú sí ilé ẹjọ lówùrọ́ òní ọjọ́ Aje.

Oba Adetunji ṣàlàyé èyi ni aafin rẹ̀ ni Popoyemoja nílùú Ibadan níbí tó ti n fi ikuluku pẹ̀lú ààrẹ àwọn ọmọ bíbí ilẹ Ibadan Ọmọọba Yemisi Adeaga

À wọn mííràn tó tun wà níbl ni igbakejì ààrẹ akọ́kọ́ ẹgbẹ́ Tirimisiyu Oladimeji, Ekefa Olubadan, olóyè Lekan Alabi, Ajia Olubadan, oloye Wasiu Aderoju lo peju sibẹ̀.

Àtẹjáde náà ni Adeola, Oloko to jẹ́ oluranlọ́wọ́ pàtàkì lórí ìròyìn àti ìpolongo fọwọ́ sí.

Gẹ́gẹ́ bi Olubadan ṣe sọ, o ti wa pọndandan lati sùgbà yí ati lati fi ọkan ara ilu àti àwọn alátilẹyin rẹ ti wọn pé sí iwáju ilé Olubadan lojoojumọ.

Àkọlé fídíò, Okunrounmu: Ijọba Buhari jẹ ijiya Ọlọrun fun Naijiria

O ní Olubadan ko káwọ gbéra, ó sì n gbé ìgbésẹ̀ lóri iṣẹ̀lẹ̀ náà.

O ní, Ilú Ibadan ni Sunday Igboho ti ni ìyàwó, to ti bi ọmọ, Ibadan lo kọle si, nítori idi eyí ó lẹ́tọ̀ ki ṣe aabo lórí rẹ̀ bi wọn yoo se se fun ọmọ bibi ilu Ibadan.

Bákan náà ni oríadé ni, lóòrè-kóòrè ní òun ń kan si àwọn orí-adé tó kù to fi mọ́ kabiyesi ilu Igboho lati dẹkun irui iṣẹ̀lẹ̀ to waye laarin Yoruba ati Fulani lọdun 1814.

Ọba Adetunji, wá rọ ará ilú láti fi ara balẹ̀ ki wọn si maa tẹ̀lé òfin titi ti òtítọ́ yóò fi borí.