Nnamdi Kanu: Ìgbẹ́jọ́ olórí IPOB Nnamdi Kanu tẹ̀síwájú nílé ẹjọ́ nílùú Abuja

Nnamdi Kanu na ndị ọkaiwu ya

Igbẹjọ ajijagbara to jẹ olori awọn to n ja fun orilẹede Biafra ni iha ẹya Igbo, Nnamdi Kanu si ọj kọkanlelogun oṣu kẹwa ọdun 2021.

Wọn bẹrẹ igbẹjọ naa lowurọ ọjọ Aje nigba ti Nnamdi Kanu ko tilẹ tii de ibẹ.

Nigba ti wọn gbe ẹjọ naa jade, agbẹjọro fun ijọba, M.B. Abubakar fi to ile ẹjọ leti pe wọn ti baba da ọjọ fun ẹjọ naa awọn yoo si tẹsiwaju.

Nigba naa ni agbjọro Nnamdi Kanu, Ifeanyi Ejiofor sọ fun ile ẹjọ naa pe iwe kan wa niwaju ile ẹ́jọ latọdọ onibaara oun ti ile ẹjọ ko tii sọrọ lori rẹ eyi to da lori pe ki wn gbe Kanu kuro ni ahamọ awọn ọtẹlẹmuyẹ DSS lọ si atimọlẹ fun ayipada iwa.

Adajọ binta Nyako pada fi lede pe wọn ko ni le tẹsiwaju ninu ẹjọ naa lai si Nnamdi Kanu nibẹ to yẹ ko wa wi tẹnu rẹ tori akii fari lẹyin olori.

Adajọ Nyako tun funpe si awọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ lati rii pe adari ẹgb IPOB yii yọju si ile ẹj fun igbẹjọ rẹ.

Wọn ti sun ẹjọ naa siwaju di ọjọ kkanlelogun oṣu kẹwaa ọdun 2021 lati tẹsiwaju ninu igbẹjọ naa.

Awọn ẹsun ti wọn fi kan Kanu da lori ifipa doju ijọba orilẹede Naijiria bolẹ.

Ijọba apapọ ti fi ofin de ẹgbẹ IPOB tẹlẹ ni Naijiria pe wọn o gbọdọ ṣe ohun kohun mọ ni Naijiria.

Kanu gbaju gbaja laarin awọn ẹya Igbo, ijọba Naijiria si ti n wa ọna lati fi ọwọ ofin mu un tipẹ ki awọn agbofinro to pada mu un.

Awọn ẹsun ti wọn fi kan Kanu lẹkunrẹrẹ ni ẹsun igbesunmọmi, kiko ohun ijagun pamọ ati ṣiṣe adari ẹgbẹ to tapa si ofin.

Agbẹjọro agba ati minisita eto idajọ ni Naijiria, Abubakar Malami tun fẹsun kan kanu pe o ṣagbatẹru rogbodiyan eyi to mu ẹmi awọn eeyan lọ ti ọpọ dukia si ṣofo.

Kanu ni aṣaaju ẹgbẹ to n pe fun idasilẹ orilẹede Biafra lẹyin aadọta ọdun ti ogun abẹle waye lori ọrọ Biafra ninu eyi ti eeyan to le ni miliọnu kan ti dero ọrun ti ọpọ dukia si bajẹ.

Ni oṣu kẹwaa ọdun 2015 ni ijọba fi ọwọ ofin mu Kanu ti wọn si fi ẹsun kan an.

Amọ, wọn gba beeli Kanu lọdun 2017 ti o si na papa bora kuro ni Naijiria.

Ohun ti Kanu sọ ni pe awọn kan n dunkoko lati gba ẹmi oun.

Ṣugbọn ijọba pada fi ọwọ mu kanu loṣu kẹfa, wọn si da pada si orilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Okunrounmu: Ijọba Buhari jẹ ijiya Ọlọrun fun Naijiria