Sunday Igboho appears in Benin Court: Ìgbẹ́jọ́ ìdákọ́ńkọ́ ni wọ́n ń ṣe fún Sunday Igboho ní Benin Republic lọ́wọ́

Igboho

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Igbẹjọ Sunday Igboho lori ati gba itusilẹ rẹ ti bẹrẹ lorilẹede Benin

Amọṣa idakọnkọ ni igbẹjọ naa n waye

Awọn akọroyin ati ololufẹ rẹ ko lanfani ati wọle.

Àkọlé fídíò, Ọmọ Ìjọ Deeper Life Pọ́ńbélé ni ìyà mi àti bàbá mi, mo sì dàgbà síbẹ̀ àmọ́ bíbọ Èṣù ọ̀dàrà lọ́nà tó tọ́ -

Akọroyin BBC Yoruba to wa nibẹ ni awọn agbẹjọro ati iyawo Igboho nikan lo wọle.

Igbẹjọ naa to bẹrẹ ni nnkan bii agogo marun ku iṣẹju diẹ , agogo orilẹede Naijiria ṣi n lọ lọwọ lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ.

Òní lònìí ń jẹ́! Ìjọba àti Sunday Igboho yóò kójú ára wọn nílé ẹjọ́ lórílẹ̀èdè Cotonou

Oni loni njẹ ẹni a bẹ lọwẹ lo difa fun bi gbogbo eto yoo ṣe lọ lonii nibi ti adari ẹgbẹ ajijagbara fun orilẹede Oduduwa Republic, Sunday Igboho yoo ti kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ.

Igba akọkọ niyii ti Sunday Adeyemo ti gbogbo eeyan mọ si Igboho yoo farahan niwaju ile ẹjọ ti wọn n gbee lọ lonii.

Lati ọsẹ to kọja ti wọn ti fi panpẹ ofin mu oun ati iyawo rẹ Ropo ni wọn ti dee lọwọ lẹsẹ si agọ ọlọpaa wọn nibẹ eyi ti wọ́n n pe ni "brigade criminelle".

Lati igba naa ni ẹni ọdun mejidinlaadọta yii ti ti eeyan ti gbogbo agbaye tilẹ fẹ mọ tabi ka iroyin nipa rẹ.

Awọn lọba lọba Yoruba ti forikori lori ọna ti wọn yoo gba lati dide iranwọ fun un ni ilu Benin eyi to waye lọjọ Aiku pẹlu atilẹkun mọri ṣe.

Bakan naa, awọn ọmọ Yoruba to wa ni orilẹede Cotonou ti ni awọn ni ireti pe obi ni igbẹjọ naa yoo so ati pe boya wọn lee da Sunday igboho silẹ lonii.

Lori igbẹjọ rẹ yii awọn ẹsun loriṣiriṣi ni wọn fi kan an.

Akọkọ ni pe o ko ibọn pamọ sile, o si tun n fi n ṣe fayawọ ibọn.

Wọn tun sọ pe Igboho n lo awọn eeyan lati da ilu ru.

Ẹlẹẹketa ni pe Igboho fẹ pin orilẹede Naijiria si meji tabi mẹta.

Ṣugbọn awọn agbẹjọro Igboho sọ fun ile ẹjọ pe ko si otitọ kankan ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

Wọn ni "ohun to ṣe pataki fun awa agbofinro Igboho julọ ni pe a ko fẹ ki wọn gbe Igboho pada si Naijiria". 'Ó sàn fún wa kí Sunday Igboho kú sí Cotonou ju kí wọ́n dáa padà sí Nàìjíríà lọ'

Àkọlé fídíò, Okunrounmu: Ijọba Buhari jẹ ijiya Ọlọrun fun Naijiria