Àwọn ọba Yorùbá l'órílẹ̀èdè Benin Republic ṣe ìpàdé, ohun tí wọ́n fẹnukò láti ṣe lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho nìyí

Awọn ọbaalye iran Yoruba lorilẹede Benin Republic ti ipade laafin aladjohoun tilu Adjohoun ni Benin lọjọ Aiku.
Ohun ti ipade wọn naa da le lori ni ọrọ Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.
Lọjọ aje ni oloye Sunday Igboho yoo pada foju ba ile ẹjọ lorilẹede Benin Republic lati mọ boya wọn yoo tuu silẹ ni tabi ki wọn daa pada sorilẹede Naijiria gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ijọba.
- Ìdájọ́ jáde! Ilé ẹjọ́ ti ní kí Sunday Igboho ṣì wà ní àhámọ́ ní Cotonou!
- Wo àǹfàní tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ fún ìyàwó Sunday Igboho ní Cotonou
- Òní lònìí ń jẹ́! Ìjọba àti Sunday Igboho yóò kójú ára wọn nílé ẹjọ́ lórílẹ̀èdè Cotonou
- 'Ó sàn fún wa kí Sunday Igboho kú sí Cotonou ju kí wọ́n dáa padà sí Nàìjíríà lọ'
- Isó fààá leè jẹ́ kí ẹ kò Covid-19 níbi tí o ba fún pọ̀! Ẹ fura o!
- Pẹ̀lú omijé lójú làwọn òbí akẹ́kọ̀ọ́ 28 Bethel Baptist táwọn ajínigbé tú sílẹ̀ fi pàdé ọmọ wọn
- 'Bàbá tó gbé owó ''ransom'' lọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jígbé, àwọn jàndùkù ajínigbé bá mú òun náà mọ́lẹ̀
- Sanwo-Olu ṣàlàyé ohun táwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
- Ó nira fún Sunday Igboho láti jẹun ní àtìmọ́lé ọlọ́pàá torí wọ́n dè é lọ́wọ́- Agbejọ́rò
- Sunday Igboho gbé DSS àti Abubakar Malami lọ sílé ẹjọ́ láti jà fún ẹ̀tọ́ rẹ̀
Lẹyin ipade naa eyi to pari ni nnkan bi agogo meji ọsan orilẹede Naijiria, awọn ọbalaye naa ṣe lalaye fun ikọ BBC News Yoruba to wa nibi ipade naa pe ipade naa wa lati mọ ọna abayọ ati igbesẹ ti awọn yoo gbe lori ọrọ naa ni. Wọn ni ohun ti awọn fi ẹnu ko le lori ni lati kọ iwe si aarẹ orilẹede Benin pẹlu minisita feto idajọ, minisita fọrọ abẹle ati olori ileegbimọ aṣofin apapọ lorilẹede naa.
Gẹgẹ bi ohun ti wọn sọ, lẹyin ti wọn ba gbe gbogbo igbesẹ wọnyii ni wọn yoo to lanfani ati ba awọn oniroyin sọrọ.
Awọn lọbalọba naa ko ṣalaye fun BBC News Yoruba ohun ti wọn fẹ kọ sinu iwe ti wọn fẹ kọ naa nitori pe gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, titu aṣiri ohun ti wọn fẹ fi ranṣẹ si awọn eekan ijọba orilẹede naa lee pagidina ohun ti wọn fẹ gan an.
Ọba Siyan aladjohoun tilu Adjohoun ṣalaye pe awọn ọbalaye naa pẹlu yoo gbiyanju ati ṣe abẹwo sile ijọba orilẹede naa ni ọjọ Aje bi esi iwe awọn naa ko ba tete jade.








