Sunday Igboho: Ẹ fún mi ní ₦500bn lórí dúkìá mi tẹ bàjẹ́ àti títẹ ẹ̀tọ́ mi lójú mọ́lẹ̀

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho/Instagram
Ajijagbara fun iran Yoruba, Sunday Igboho ti pe ijọba apapọ lẹjọ lori bawọn osisẹ DSS se ya bo ile rẹ ni Ọjọbọ, ọjọ Kinni osu Keje ọdun yii.
Igboho lo pe awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ DSS ati agbẹjọro agba fun ijọba apapọ, Abubakar Malami lẹjọ lori ikọlu sile rẹ naa.
Ajijagbara naa wa n beere biliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta naira lọwọ ijọba lori ọpọ dukia ti DSS bajẹ nile rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho ń bẹ iléẹjọ́ láti ṣe àtìpò òṣèlú nílẹ̀ Benin
- Igun kan PDP ìpínlẹ̀ Ogun kọ̀ lati kopa nínú ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ lónìí
- Gbaga ọlọ́pàá ni Igboho ti ń lo òpin ọ̀sẹ̀, ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Benin kò jókòó lọ́jọ́ Ẹtì
- Ẹgbẹ́ òṣèlú mọ́kànlá forí ṣánpọ̀n nílé ẹjọ́ láti wọ́gilé ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ l‘Eko
- Adájọ́ pàṣẹ pé kí DSS kó èèyàn méjìlá tó kó nílé Igboho wá sílé ẹjọ́
- N kò ṣe ẹlẹ́yà Sunday Igboho, irọ́ ni wọ́n pa mọ́ mi - Olayomi Koiki
- ‘Passport’ Nàíjíríà àti Germany ni wọ́n ká mọ́ Sunday Igboho lọ́wọ́ - Agbẹjọ́rò
- "Ẹni tó bá gba 'Passport Benin Republic' láì ṣe ọmọ onílùú, yóò fi ẹ̀wọ̀n jura"
- Mo kìlọ̀ fún Igboho kó má wá sí ilé mi ní Benin Republic, lẹ́yìn táwọn ọlọ́pàá ń ṣọ́ mi - Alábàṣiṣẹ́pọ̀
Benin Republic ló bẹ́gi dínà aáyan ìjọba àpapọ̀ láti kù gììrì gbé Igboho wá Naijiria -
Bakan naa lo tun n rọ ile ẹjọ pe ko pasẹ fun ijọba atawọn osisẹ agbofinro rẹ lati bọwọ fun awọn ẹtọ to ni labẹ ofin bii ọmọniyan.
Gẹgẹ bi agbẹjọro Igboho ti bẹbẹ ninu iwe ipẹjọ naa, o ni ẹtọ onibara awọn labẹ ofin ọdun 1999m lawọn agbofinro naa ti tẹ loju mọlẹ.
Agba amofin Yomi Aliyu, to n soju fun Sunday Igboho n fẹ ki ileeẹjọ kede pe bawọn agbofinro DSS se ba ọpọ dukia jẹ nile onibara ati bi wọn se ya bo ile naa, lo tẹ ẹtọ rẹ mọlẹ labẹ ofin.
O ni "iwa ika, ifiyajẹni ati titẹ ẹtọ ọmọniyan loju mọlẹ ni bi awọn olujẹjọ naa se kọlu ile Sunday Igboho lai sọ iru eeyan ti wọn jẹ.
Koda, wọn ko beere pe ki onibara oun silẹkun fun awọn amọ wọn kan fi ibọn fagidi wọle, ti wọn si pa eeyan meji, to fi mọ baba agbalagba to n kirun lọwọ ninu isọ oru to n se.
Bakan naa ni wọn tun ba ọpọ dukia jẹ ninu ile naa, to fi mọ awọn ẹranko bii ologbo to n sin ati aja, eyi to tẹ ẹtọ rẹ bii ọmọniyan loju mọlẹ."
O ni wọn mọọmọ n fi ibọn le kiri lati mu ni oku abi aaye nigba ti ko tii maa kede ogun, lọna ati ja fun ominira Yoruba.
Olupẹjọ naa wa n rọ ileẹjọ lati kede pe ete awọn olupẹjọ ti wọn fi ya bo ile rẹ ni lati di lọwọ ninu ipolongo fun idasilẹ orilẹede Yoruba to n se.
Atẹjade naa, ti amofin Aliyu fisita ni ko si orilẹede kankan to laju ni agbaye, tawọn agbofinro yoo ti fi agidi wọle eeyan kan, ti wọn yoo si pa eeyan tabi ba dukia owo iyebiye jẹ.


















