Buhari's visi to Daura: Ẹ má fún mí tabi àwọn olóòṣelú ni ẹ̀bùn kankan mọ́- Buhari sọ fún ọmọ Naijria

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ fun awọn ọmọ Naijiria paapaa julọ awọn onisowo, awọn kọngila àwọn àwọn miiran to ri ọwọ fi họri ni Naijiria lati ri pe wọn se iṣẹ iranwọ fun ara ilu.
O ni ki wọn ṣe eyi kaka ki wọ n ma wa onju rere oloselu kiri ati gbigbe ẹbun rabandẹ fun wọn.
Aarẹ Buhari sọ eyi di mimọ lasiko to ṣe abẹwo si Ọba ilu Daura nipinle Katsina Umar Faruk Umar laafin rẹ.
- Wo ìdí tí àwọ́n ọ̀dọ́ Ghana fi kọ àpò ìrẹsì tí Asofin kan pín fún wọn
- Àwọn tó ń ṣe ayédèrú fíìmù fẹ́rẹ̀ sọ mí di ẹni ilẹ̀ lẹ́yìn tí mo pàdánù N52m- Olaiya Igwe
- Adájọ́ pàṣẹ pé kí DSS kó èèyàn méjìlá tó kó nílé Igboho wá sílé ẹjọ́
- Emir ìlú Taraba fún àwọn Fulani Darandaran ní gbèńdéke ọjọ́ 30 láti kúrò nínú igbó ìpínlẹ̀ òun
"Mi o fẹ ki ẹnikẹni fun mi ni iwe sọwedowo, ẹ lọ ran awọn ara ilu lọwọ, kaka ti ẹ o fi maa fun awọn oṣiṣẹ ijọbna ni owo abẹtẹlẹ"
"A o fẹ sọwedowo lọwọ ẹnikẹnitabi ile iṣẹgẹgẹ bi fifi ẹmi imoore han, ẹ jẹ ki wọn lọ ṣe iranwọ fun awọn agbegbe wọn"
Aarẹ ni o wu oun lati maa ṣe abẹwo si ilu Daura lọpọlọpọ, sugbọn owo ti ile iṣẹ aarẹ n na lati ṣe abẹwo ati ọrọ abo jẹ idiwọ sugbọn ọkan oun wa pẹlu awọn eniyan.
" Iṣẹ agbẹ ni a mọ wa si, mo si ni oko ni ilu yii. Mo le maa wa ni ọsẹ mejimeji, ti ko si si ẹni ti o le di mi lọwọ, sugbọn owo ti ile iṣẹ aarẹ n na ti pọ ju.
Sugbọn aarẹ ni o san lati lo iru owo bẹẹ lati tun ile ẹko ṣe àti lati tun awọn ile iwosan to wa ṣe.
Aarẹ fi kun pe ore ofẹ Ọlọrun lo gbe orilede Naijiria ro de ibi ti o wa bayii, gẹgẹ bi olri;ede ti o fi odidi ọgbọn osun ja ogun abẹle












