Àwọn ọ̀dọ́ agbègbè Busunu ni ẹkùn Savannah ní Ghana ti kọ́ ẹ̀bùn àpò ìrẹsì tí Asofin Samuel Abu pín

Oríṣun àwòrán, Ghana government/others
Wo ìdí tí àwọ́n ọ̀dọ́ Ghana fi kọ àpò ìrẹsì tí Asofin kan pín fún wọn
Fọnran fidio kan lo jade loju opo ayelujara nibi ti awọn ọdọ kan n da apo irẹsi ti wọn fi ransẹ si awọn ara agbegbe naa gẹgẹ bii ẹbun pada.
Awọn ọdọ naa da apo irẹsi naa pada sinu ọkọ Hilux ti wọn fi gbe e wa fun wọn lọjọ Aiku to kọja.
Ariwo: 'isẹ ni a n fẹ kii se ounjẹ, Samuel Jinaper mu ileri too se fun wa lasiko idibo sẹ'ni wọn n pa bi wọn se n da apo irẹsi naa pada.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- N kò ṣe ẹlẹ́yà Sunday Igboho, irọ́ ni wọ́n pa mọ́ mi - Olayomi Koiki
- ‘Passport’ Nàíjíríà àti Germany ni wọ́n ká mọ́ Sunday Igboho lọ́wọ́ - Agbẹjọ́rò
- Gbogbo ajìjàgbara àti oníjàgídíjàgan tó fẹ́ pín Naijiria rugi oyin - Iléeṣẹ́ ọmọ ogun
- Ẹ fura o! Kọ́lẹ́rà ti pa èèyàn 66 ní Abuja, tó sì mú èèyàn 873
- "Ẹni tó bá gba 'Passport Benin Republic' láì ṣe ọmọ onílùú, yóò fi ẹ̀wọ̀n jura"
- Bí mo ṣe jàjàbọ́ rè é lọ́wọ́ àwọn agbẹ́bọ̀n tó jà ọkọ̀ ìjà òfúrúfú mí bọ́ - Ọmọogun Abayomi Dairo sọ ìrírí rẹ̀
Awon ileesẹ iroyin abẹle Zaaradio ni pe saaju ni ọma ile igbimọ asofin naa, Samuel Abu Jinaper ti seleri ipese isẹ lọpọ yanturu fun awọn ọdọ naa lasiko eto idibo.
Eyi ni wọn ni ko musẹ losu meje lẹyin to wọle ko to maa pin irẹsi.
Iroyin ni se ni awọn ọdọ naa ba irẹsi naa jẹ ti wọn si daa pada si ọda Asofin to ko wọn ransẹ si wọn.
Tani ni Samuel Abu Jinapor?
Samuel Abu Jinapor jẹ agbajọrọ.
Odun 2020 lo kọkọ wọile igbimọ Asofin lẹyin to dije dupo pẹlu Adam Mutawakilu ti ẹgbẹ NDC
O ti kọkọ se igbakeji adari ile si Aare Akufo-Addo ni ọdun 2017 si 2020.
O sise gẹgẹ bii minista fun ọrs ilẹ ati nkan alumọni nigba ti Nana Akufo Addo se aare lẹẹkeji.
- Irọ́ ni pé Iléesẹ́ Ọlọ́pàá ń gba àwọn èèyàn sísẹ́ lásìkò yìí- IGP Alkali
- Àwọn tó ń ṣe ayédèrú fíìmù fẹ́rẹ̀ sọ mí di ẹni ilẹ̀ lẹ́yìn tí mo pàdánù N52m- Olaiya Igwe
- Adájọ́ pàṣẹ pé kí DSS kó èèyàn méjìlá tó kó nílé Igboho wá sílé ẹjọ́
- Irọ́ ni pé Iléesẹ́ Ọlọ́pàá ń gba àwọn èèyàn sísẹ́ lásìkò yìí- IGP Alkali
- 'Kò sáyè fún ọ̀lẹ ní ilé Oluwa' Fatoyinbo sọ̀rọ̀ lórí àwọn Pásítọ tí Oyedepo lé













