Nollywood: Olaiya Igwe sọ ìrírí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn tó ṣe ayédèrú fíìmú tó sí pàdánú N52m

Olaiya

Oríṣun àwòrán, Instagram

Gbajugbaja oṣere lorilẹede Naijiria, Ẹbun Oloyede ti ọpọ eniyan mọ si Olaiya Igwe ti sọ iriri rẹ nipa awon to n se ayederu fiimu.

O sọrọ́ kikun pẹlu bi awọn to n ṣe ayederu fiimu ṣe sọ oun si oko gbese lẹyin to ṣe fiimu kan ni ọdun 2014.

Olaiya ti o ti n wa ni ẹgbẹ oṣere Nollywood lati bi aadọta ọdun ṣẹyin, bẹrẹ pẹlu ẹgbẹ oṣere Musbau Shodimu Theatre Organisation to wa kalẹ si Abeokuta.

Gbajugbaja oṣere ni pẹlu ila loju ni ọpọlọpọ mọ si awọn ere apanilẹrin to ma n ṣe ninu fiimu, lo sọ iriri rẹ lasiko to ba awọn oniroyin sọrọ.

Bakan naa ni awọn ololufẹ ni Nollywood ka si pe o pẹlu awọn to ni owo julọ ni agbo oṣere.

Olaiya ni ọdun 2008 ni oun ti kọ fiimu gbẹyin, ti o si gbe e jade ni ọdun 2014, eleyii ti wọn pe akọle rẹ ni 'Mystery of Unity', to si ṣe e ni Ede Yoruba ati Ede Gẹẹsi.

Igba kan naa ni wọn ṣe fiimu ohun ni ede mejeeji, ti wọn si gbe e jade ni ọjọ kan naa.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Timi Orokoya ní orin Iléyá tí òun kọ lọ́dún 28 sẹ́yìn, ló padà wá ṣẹ báyìí

O ni: '' Mo na miliọnu mejilelaadọta lori fiimu ọhun ti mo ṣe ni ọdun 2008, amọ ti mọ gbe jade ni ọdun 2014, ti awọn to n ṣe ayederu fiimu si gbe jade, eyi fẹrẹ jami ku lẹ.

''Mo fẹrẹ daku gbọnrangandan ni Ọjọ Isinmi ti awọn olutaja pe mi pe wn ti ṣe ayederu fiimu naa, ti mo si padanu mejilelaadọta miliọnu naiira ti mọ san fun ọpọlọpọ oṣu.''

''Lẹyin naa ni mo gba orilẹede Amerika lọ lati lọ sinmi ni ọdọ ọmọ mi to n ṣiṣẹ orin kikọ ni agbegbe New York.''

Olaiya

Oríṣun àwòrán, Instagram

''Mo salaye ohun to ṣẹlẹ fun ọmọ mi Ridwan nitori mo nilo isinmi.''

''Lati igba naa ni mi o ti gbe sinima jade mọ nitori iṣẹlẹ̀ to ṣẹlẹ si mi nitori fiimu naa ti akọle Yoruba rẹ jẹ Aditu Iṣọkan ni mo gbe jade pẹlu ti Ede Gẹẹsi rẹ ni igba kan naa.''

Amọran mi fun awọn oni fiimu re e

Olaiya to ti kopa ninu fiimu bi Awọn Aladun De ati Ile Alayo ni ẹrọ ayelujara bii social media ti ṣe iṣẹ takuntakun lati ri pe ko si awọn to n ṣe adakọ fiimu mọ bii ti tẹlẹ.

Gbajugbaja oṣere tiata naa wa rọ awọn to ba ṣe fiimu lati gbe e lọ cinema tabi awọn oju opo bii Netflix ti wọn yoo ti ri owo wọn pada daradara.

Amọ, o fikun pe ẹnikẹni to ba gbe fiimu rẹ lọ si ibomiran yoo ri pe awọn to n ṣe ayederu fiimu pọ biba nibẹ.