Big Brother Naija 2021: Àwọn olùkópa obìnrin darapọ̀ mọ́ ilé ẹlẹ́gbọ́n àgbà BBNaija, ìyàlẹ́nu ńlá ni wọ́n bá pàdé níbẹ̀

aworan awọn olukopa

Oríṣun àwòrán, BBnaija

Eyi ni aṣigbọ ati aṣitumọ iroyin nipa Sunday Igboho to n lọ laarin awọn oniroyin nilẹ Benin

Awọn olukopa obinrin darapọ mọ ile ẹlẹgbọn agba BBNaija lalẹ ọjọ Aiku bi saa kẹfa eto agbelewo naa ṣe bẹrẹ.

Awọn ọmọbinrin to darapọ ni Angel, Peace, Jackie B, Tega, Arin.

Bakan naa ni Maria, Nini, Princess, Beartrice, Saskay ati Liquorose pẹlu naa wọ ile loni.

Ni ọjọ Abamẹta ni saa kẹfa eto agbelewo naa gbinaya pẹlu ikede awọn olukopa mọkanla to jẹ ọkunrin.

Igba akọkọ si ni yi lori eto naa ti wọn yoo maa kede awọn olukopa skunrin ati obinrin lọtọọtọ.

Awọn olukopa

Oríṣun àwòrán, BBnaija

Amọṣa, iyalẹnu nla lo jẹ fun awọn olukopa obinrin lori eto naa lalẹ ọjọ Aiku ti wọn kede wọn kaabọ sinu ile ẹlẹgbọn agba BBNaija ẹlu bi awọn ọkunrin to ti ṣaaju wọn de inu ile naa ṣe kọ lati fi ariwo ati ays ki wọn kaabọ sinu ile naa.

Ara ere ti awọn ọkunrin fẹ fi ja awọn obinrin naa laya ni eyi.

Amọṣa lẹyin ti wọn kede gbogbo awọn obinrin naa tan lawọn ọkunrin naa ba fo soke lati ki wọn kaabọ.