Igboho released in Benin republic: Sunday Igboho gba òmìnira láti lọ tọ́jú ara rẹ̀ nílé ìwòsàn ní Benin Republic

sunday Igboho

Oloye Adeyemo Sunday Igboho gba ìtúsílẹ̀ ní orile-ede Benin Republic

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo sọ pe Gbajumọ aṣiwaju ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho la gbọ pe awọn alaṣẹ orilẹede Benin Republic ti tu silẹ bayii

Wọn tu Igboho silẹ lọjọ Aje nilu Cotonou.

Awọn alaṣẹ orilẹede Benin fa Igboho le olori ẹgbẹilana Ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akinloye ati jọgbọn Wale Adeniran lọwọ.

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, @Sunday Igboho

Kini Agbejoro Yomi Aliyu SAN so pe o sele ati alakale naa?

Nigba ti BBC Yoruba kan si agbejọ́ro agba Yomi Aliyu to je agbejoro fun Oloye Sunday Adeyemo, o sọ̀rọ̀ lori idi ti won se tu Igboho Oosa sile bayii.

Àkọlé fídíò, Láti sẹ́ńtúrì kẹrìnlá ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín Russia àti Ukraine

Aliyu ni pe wọ́n ti fa Sunday Igboho le awon Dokita ara rẹ̀ lọ́wọ́ ni oirle-ede Benin Republ;ic.

O ni pe Igboho Oosa ni wọ́n fa le Ojogbon Banji Akintoye to je alaga egbẹ́ Ilana Omo Oodua lọ́wọ́.

Àkọlé fídíò, Dapo Abiodun ò sọ fún mi pé òun á dupò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì o, èmi nàá ò kẹ̀rẹ̀ nínú òṣèlú láti kékeré - Modele Sarafa-Yusuf

Wọ́n ni pe Sunday Igboho ko gbọ́dọ́ kuro ni orile ede Benin Republic bayii.

Wọ́n ni Oosa ni oore ọ̀fẹ́ lati lọ́ se itoju ara re nibi ti ọ̀rọ̀ de duro yii.