Sunday Igboho: Ìjọba àpapọ̀ ń fẹ́ kí ilé ẹjọ́ da ìdájọ́ tó ní kí DSS fún Igboho ní ₦20b nù

Oríṣun àwòrán, Igboho instagram/bbc
Ijọba apapọ ti pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo to ni ki ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS san ogun biliọnu naira fun oloye Sunday Igboho.
Owo yii ni ileẹjọ ni ko wa gẹgẹ bii owo ‘gba ma binu’ fun Igboho lori bi wọn ṣe kọlu ile rẹ lọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2021.
Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan an, ọdun 2021 ni adajọ A.I Akintola da ẹjọ naa nilu Ibadan.
Ninu ẹjọ naa ti wọn pe niwaju ile ẹjọ kọtẹmilọrun to wa niluu Ibadan, ijọba apapọ sọ pe idajọ naa ko tẹ oun lọrun.
Awọn to pe ẹjọ naa ni adajọ agba Naijiria, Abubakar Malami, ati ajọ DSS.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Yomi Aliyu tii se agbẹjọro fun Sunday Igboho, lo fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC Yoruba.
- Àwọn ọmọ Naijiria tó wà ní Ukraine ké gbàjarè lórí ìdẹ́yẹsí tí wọ́n ń kojú lẹ́nu ibodè EU
- Ẹ̀bẹ̀ béèlì Abba Kyari kò ba mọ́, yóò lo ọjọ́ mẹ́rìnlá si ní àhámọ́ NDLEA - Iléẹjọ́
- Belarus ní ààyè ìpàdé ìpẹ̀tùsááwọ̀ láàrín Ukraine àti Russia ti wà níkàlẹ̀
- Kí ló dé tí Esabod àti Lizzy Anjorin fi ń ṣépè fúnra wọn?
- Àwọn agbébọn rọ́jò ìbọn fún Ọba aládé l'Ekiti, ó dèrò ilé ìwòsàn
- Ọ̀wọ́ngógó epo bẹntiróòlù le tún peléke síi nítorí làásìgbò Russia àti Ukraine
- Ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de tako ìyanṣẹ́lódì ASUU lónìí
- Wo ìdí pàtàkì mẹ́ta tí Russia se kọlu Ukraine
- Mi ò ní ìkùnsínú sí àwọn tó bá mi du àṣíá ìdíje gómìnà ní APC- Oyetola
- Ọmọ Nàìjíríà tó há sí Ukraine kò nílò físà láti wọ Romania àti Poland- Ìjọba Nàìjíríà
Wọn ṣe akọsilẹ koko mejidinlogun to jẹ idi ti ile ẹjọ kotẹmilọrun naa ṣe gbọdọ da ẹjọ naa nu.
Awọn idi ti ijọba apapọ ṣe fẹ ki ile ẹjọ kọtẹmilọrun da idajọ naa nu
Ninu iwe ipejọ ti ijọba apapọ pe ni wọn ti sọ pe ajọ DSS ko ṣẹ si ofin kankan bo ṣe kọlu ile Igboho loru mọju.
Wọn ni DSS ko tẹ ẹtọ Igboho loju bi wọn kọlu ile rẹ, ati pe ọrọ rirun ni ọrọ ti agbẹjọro Igboho sọ pe wọn da alaafia rẹ̀ laamu bi oṣiṣẹ DSS kan ṣe yinbọn soke ninu ile rẹ, eyii to fa orule ile naa ya.
Ijọba apapọ tun sọ pe eremọde lasan ni awọn agbẹjọro Igboho n ṣe lẹyin ti wọn ni pe irọ ni DSS pa mọ Igboho.
Wọn ni awọn ọmọlẹyin Igboho lo tako afihan awọn oniruru ohun ija oloro atawọn oogun abẹnu gọngọ ti wọn sọ pe DSS ba ninu ile Igboho.
Wọn si lo yẹ ki DSS jẹ ki awọn alabasiṣẹ Igboho yẹ ara wọn wo, ki wọn to yabo ile rẹ.
Ijọba apapọ wa tẹsiwaju pe idajọ ile ẹjọ giga naa ko lẹsẹ nilẹ nitori ẹlẹri Igboho to sọrọ tako DSS nile ẹjọ naa, iyẹn Hamza Bashiru Ariyo, ko mọ ohun to n sọ, ati pe bo ṣe jẹri ọhun gan ko munadoko to.
Lori awọn koko ti wọn gbe lọ siwaju ile ẹjọ naa, ijọba apapọ ni awọn koko ti Ighoho fi tako DSS ko si ninu ori kẹrin iwe ofin Naijiria.
Wọn tun sọ pe aṣiṣẹ ni ile ẹjọ ọhun ṣe bo ṣe gbọ ẹjọ lori ọrọ to kan ijọba apapọ.
Lakotan, ijọba apapọ n fẹ ki ile ẹjọ kotẹmilọrun fidi rẹ mulẹ pe gbogbo ẹsun ti awọn fi kan Sunday Igboho lẹsẹ nilẹ.
Wọn tun n fẹ ki ileẹjọ kede pe DSS ni aṣẹ lati ṣakọlu sile Sunday Igboho bi wọn ṣe ṣe loru ọjọ Kinni, oṣu Keje, ọdun 2021.
Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ:
Ti ẹ ko ba gbabe, nnkan bii aago kan oru ni DSS kọlu ile Igboho to wa lagbegbe Soka, niluu Ibadan, iyẹn lọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun to kọja.
Ikọlu naa lagbara to bẹẹ ti ẹmi eeyan meji sọnu, nigba ti wọn fi ṣikun ofin mu awọn mejila miran, amọ Igboho moribọ.
Ẹwẹ, lati ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun 2021 kan naa ni Igboho ti wa lọgba lorilẹ-ede Cotonou, ti ijọba orilẹ-ede naa ko si fi ẹsun kankan kan an.


















