ASUU strike: Kí ló wáyé níbi ìpàdé NANS àti ìjọba àpapọ̀, àlàyé rèé

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣe ìwọ́de

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣe ìwọ́de

Ní àná ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù kejì ní ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ilẹ̀ Nàìjíríà, NANS, ṣe ìpàdé láti fi ẹ̀hónú wọn hàn lórí ìyanṣẹ́lódì tó ń lọ lọ́wọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì.

Ìpádé ọ̀hún ló forí sọ́pọ́n láì ní ojútùú kan pàtó.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé wọn, Ààrẹ NANS, Sunday Asefon ní Mńísítà fétò ẹ̀kọ́, Mallam Adamu Adamu kàn déédé kúrò níwájú àwọn láì tíì parí ìtàkurọ̀sọ.

Mínísítà fétò ẹ̀kọ́ ní tirẹ̀ ní ohun kan tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ tó ṣe é gbéyẹ̀wò ni wí pé kí àwọn aṣojú akẹ́kọ̀ọ́ máa wà níbi ìjíròrò ASUU àti ìjọba àpapọ̀.

NANS ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónu hàn ni ana nitori idi wonyii:

Ṣaájú ní òwúrọ̀ àná kí ìpàdé tó wáyé láàátín ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti ṣe ìwọ́de káàkìri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ẹ̀hónú wọn hàn lórí ipa tí ìyanṣẹ́lódì ojoojúmọ́ ń kó nínú ìgbésí ayé àwọn.

Àkọlé fídíò, Aáwọ̀ tó ń wáyé láàárín Russia àti Ukraine ti mú àlékún bá iye owó epo rọ̀bì lágbàyé

Ní Abuja ní Unity Fountain ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de gba ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ kí wọ́n tó darí sí ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ètò ẹ̀kọ́.

Ààrẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́, Sunday Asefon ló darí ìwọ́de tí Abuja yìí níbi tí wọ́n ń kọ onírúurú orin pẹ̀lú àkọlé lọ́kan-ò-jọ̀kan lọ́wọ́ wọn.

Asefon ní ẹ̀tọ́ gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni láti kọ́ ẹ̀kọ́ tó yè kooro láìsí ìdíwọ́ irú ìyanṣẹ́lódì gbogbo ìgbà báyìí.

Ó tẹmpẹlẹmọ́ pé ASUU àti ìjọba àpapọ̀ gbọ́dọ̀ wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá ní kíákíá kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ wọn.

Lógò NANS

Oríṣun àwòrán, @NANS

Ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de tako ìyanṣẹ́lódì tí ASUU gùnlé

Àwọn ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà (NANS), tí kéde pé àwọn yóò ṣe ìwọ́de káàkiri ìlú Abuja àti àwọn ìlú mìíràn ní orílẹ̀ èdè yìí láti fi ẹ̀hónú wọn hàn lórí ìyanṣẹ́lódì tí ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ASUU gùnlé.

Ní ọjọ́ Ajé tó kọjá ní ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti fi ìkìlọ̀ síta pé, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì, ní àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de tí ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ fásitì bá kọ̀ láti forí ìkòkò sọ̀ọ̀dúnrín lórí ìfaǹfà tó wà ní àárín wọn.

Kini Aare ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́, Sunday Asefon fi lede?

Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́, Sunday Asefon ní ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ fásitì, ASUU gbọ́dọ̀ parí aáwọ̀ tó wà láàárín wọn ní kíákíá kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè padà sẹ́nu ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn bó se yẹ

Àtẹ̀jáde látọwọ́ NANS ní ìfẹnukò láti gùnlé ìwọ́de yìí wáyé níbi ìpàdé tí ẹgbẹ́ náà ṣe ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìpínlẹ̀ Sokoto.

Asefon wá rọ gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti darapọ̀ mọ́ ìwọ́de yìí kí ó le kẹ́sẹ járí.

Àkọlé fídíò, Khadijat Okunnu:Olùdíje ipò ààrẹ Nàìjíríà tó sọ pé nkán gbódọ̀ dàrú ní Nàìjíríà kò

Nibo ni iwode naa a ti bẹ̀rẹ̀?

Bákan náà ló fi kun pé gbogbo àwọn òpópónà tó ṣe pàtàkì ní olú ìlú ilẹ̀ wa, Abuja ni àwọn yóò dí pa nítorí ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí kìí ṣe ti àwọn ni àwọn ń jẹ.

Ó tẹ̀síwájú pé orí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní gbogbo ìjìyà tó máa ń tẹ̀yìn ìyanṣẹ́lódì jáde máa ń dá lé lórí nítorí gbogbo owó ilé tí àwọn ti san kò ní jẹ́ dídá padà tí ọjọ́ orí náà sì ń dàgbà si.

Àkọlé fídíò, Ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Mc Lively aderinposonu Naijiria

Kini wọ́n fẹ́ ki Minista se?

Asefon tún rọ Mínísítà fọ́rọ̀ òṣìṣẹ́, Chris Ngige àti àwọn adari ẹgbẹ́ láti tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá, kí ìyanṣẹ́lódì náà le wá sópin ní kíá.

Bẹ́ẹ̀ náà ló rọ̀ wọ́n láti máa pe aṣojú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sínú ìpàdé wọn bó ṣe jẹ́ pé àwọn ló máa ń forí fa gbogbo ohun tí ìpinu wọn bá dá lé lórí.