Sowore kept in abattoire: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti fi Omoyele Sowore sílẹ̀, Ó ti kúrò ní àhámọ́

Oríṣun àwòrán, AFP
Ileeṣẹ ọlọpaa ti tu gbajumọ ajafẹtọ, Ọmọyẹle Ṣoworẹ silẹ lahamọ rẹ.
Soworẹ ṣalaye ninu atẹjade to fi soju opo Twitter rẹ lẹyin to jade pe ileeṣẹ ọlọpaa ti fi oun silẹ.
Ni Ọjọbọ ni wọn iroyin jade pe awọn ọlọpaa nilu Abuja tun fi ofin gbe ajafẹtọ naa.
Ẹsun wo lọlọpaa fi kan Soworẹ?
Gẹgẹ bi ọrọ to fi soju opo Twitter rẹ, Ṣoworẹ ni ẹsun ti awọn agbofinro fi kan oun ni pe oun sọrọ ti ko tọna si Ned Nwoko.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ọkan lara awọn agbẹjọro Soworẹ, Inibehe Effiong ṣalaye loju opo Twitter rẹ pe gbajumọbaba olowo naa to tun jẹ ọkọ gbajumọ oṣere Nollywood, Regina Daniels lo wa nidi bi wọn ṣe mu Soworẹ.
Ki lohun to ṣẹlẹ gangan?
Iroyin to n tẹ wa lọwọ lọjọbọ pe awọn Ọlọpaa ilu Abuja fi ofin gbe ajijagbara ọmọ Naijiria nni, Omoyele Sowore nilu Abuja
Akọwe agba ẹgbẹ oṣelu African Action Congress, Femi Adeyeye lo fi atẹjade kan sita to sọ eyi di mimọ atẹjade kan to fi sita.
Ọlọ́pàá tún gbé Sowore l'Abuja, Ẹ wo bí wọ́n ṣe tì í mọ́ 'Abattoir' àwọn ọ̀daràn
Labẹ Ẹgbẹ yii ni Sowore ti du ipo Aarẹ lọdun 2019.
Bakan naa ni ileeṣẹ Amnesty International naa ti fi iroyin yii sita loju opo Facebook rẹ pe o n kọ oun lominu, bi wn agbofinro ṣe kọlu ajafẹtọ naa nilu Abuja ti wọn si fi panpẹ ofin mu u.
- Ògo ilé wá wọlẹ̀ lójijì! àwọn darandaran ajínigbé pa abúrò mí! - Ọmọyẹle Ṣowore
- Sowore, AAC ti yọ Leonard Ezenwa tó kéde ìyọnípò Ṣòwòrẹ́
- Ṣé lóòtọ́ ni Olubadan tuntun, Lekan Balogun buwọ́lu Tinubu fun ipò arẹ lọdun 2023?
- Omoyele Sowore dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn tó fara gba ọta gáàsì tajútajú l'Abuja
- Sowore tún kó sí àhámọ́ agbófinró torí ìwọ́de àìṣùn ọdún
Atẹjade ẹgbẹ oṣelu AAC fihan pe wọn mu Sowore ni "kete to n jade ni ile ẹjọ nibi ti alaga atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa ti peju lati jẹ ẹlẹri igbẹjọ to waye laarin ẹgbẹ oṣelu naa ati ajọ eleto idibo, INEC.
Sowore to jẹ alakoso ileeṣẹ iroyin ori ayelujara, Sahara Reporters lo kọwe ipẹjọ lodi si idajọ ile ẹjọ giga lorii alaga ẹgbẹ oṣelu naa.
Kini atẹjade naa sọ?
Adeyeye fi kun un pe wọn gbe Sowore lọ si atimọle awọn Ọlọpaa Kogberegbe SARS ti wọn ma n pe ni "Abattoir" lẹẹkọọkan to si ni awọn Ọlọpaa ọhun ko sọ idi ti wọn fi gbe e.
"A n bojuto awọn nkan to n lọ yoo a si fi n da gbogbo ọmọ ẹgbẹ loju pe lemọlemọ iṣẹlẹ ti ko ba ofin mu yii, a o ni jẹ ko fẹsẹ mulẹ, Idi pato ti wọn fi fofin mu u ko tii foju han bayii".

















