Russia vs Ukraine: ìpín ìdókòwò já wálẹ̀, iye owó epo rọ̀bì búrẹ́kẹ́ síi, kíni k'áwọn aráàlú máa retí ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Tom Espiner
- Role, Business reporter, BBC News
Iye owo epo rọbi lagbaye ti gbera soke kọja ọgọrun dọla barẹli kan lẹyin ti Russia gbe ija koju orileede Ukraine.
Iye owo yi lo ga julọ lati nkan bi ọdun meje sẹyin ti owo epo rọbi ti dẹnukọl.
Lagbaye Russia ni orileede keji to n ta epo rọbi julọ ti wọn si tun jẹ orileede to lewaju nidi tita afẹfẹ gaasi lagbaye.
Ọgọrun le dọla marun ni iye owo ti wọn ta epo rọbi tawọn to si n mojuto iye owo epo bẹntiroo ni ilẹ Gẹẹsi sọ pe o gbowo lori ju atẹyinwa lọ
Ida mẹfa ninu ida ọgọrun epo rọbi ilẹ Gẹẹsi ni wọn maa n ra lati ọwọ Russia.
Bẹẹ lo ri pẹlu afẹfẹ gaasi wọn. Ibẹrubojo wa wi pe bi wọn ba file gbe ijiya le Russia o le mu ki iye owo epo rọbi ati gaasi lọ soke lagbaye.
LỌjọbọ,alekun to fẹ ẹ to ida ọgọta ninu ida ọgọrun ba iye owo gaasi futures ilẹ Gẹẹsi
Awọn araalu n san owo gọbọi bayi gan alara ti o si n gbowo lori si plu ajakalẹ Covid-19 to wa nita.
RAC ati AA to n ṣamojuto iye owo bẹntiroo ati disuu sọ pe lỌjọru, wọn ta jala bẹntiroo ni 149.5p ti wọn si ta disuu ni 152.83p.
RAC sọ pe bi iye owo epo rọbi ba file de $110 barẹli kan, o ṣeeṣe ki wọn ta jala epo kan ni £1.55.
Simon Williams lati RAC ''sọ pe ti iye owo epo rọbiba lọ soke,yoo fa inira fọpọ eeyan to maa n lo ọkọ wọn lati lọ si ibiṣẹ tabi fun kalọ kabọ nitori owo epo le gbera lọ si £85''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi a ba fi isiro iye owo taa n ṣẹ poun si Naira wo, jala epo tawọn eeyan ilẹ Gẹẹsi n ra bayi ti di nkan bi ₦839.68 ti owo disuu si jẹ nkan bi ₦858.38.
Nilẹ Gẹẹsi, ilọsoke tabi wiwalẹ owo epo bẹntiroo ni ṣe pẹlu iye ti owo epo rọbi lagbaye ba jẹ to fi mọ iye ti wọn n parọ dọla si owo poun nitori dọla ni wọn fi n ṣowo epo rọbi.
Iye owo epo rọbi ti lọ soke bayi tori naa poun ti walẹ niye si dọla.
Ko yatọ si nkan to n ṣẹlẹ ni Naijiria wa naa amọ a ko ti ri ki iye owo jala epo bẹntiroo lọ soke si.
Bo tilẹ wu ko lọ soke, awọn onimọ sọ pe owo ẹdinwo 'subsidy' ti ijọba n san ko le jẹ ki araalu mọ lara.

Iroyin igbesẹ Russia yi ṣakoba pupọ koda o mu ki iye owo ipin idokowo lagbaye lọja ibanidokowo dẹnu kọlẹ.
Ni ọja ibanidokowo Yuroopu FTSE owo ilẹ Gẹẹsi walẹ niwọn ida to kọja 3.9%, ti eleyi si jẹ ijawalẹ to pọ julọ lati nkan bi oṣu Keje ọdun 2020.
Dax Index ti ilẹ Germany naa dẹnu kọlẹ niwọn ida 4%.
Dow Jones nilẹ Amẹrika naa dẹnu kọlẹ ni iwọn ida 2% nigba ti S&P 500 naa wale ni iwọn 1%.
Karakata idokoowo ni Moscow Stock Exchange la gbọ pe wọn so rọ fun igba diẹ ṣugbọn nigba ti wọn bẹrẹ pada o dẹnukọlẹ ni iwọn ida mẹta.
Ni ti karakata owo, rouble to jẹ owo Russia dẹnukọlẹ lẹgbẹ d la Amrika.
Niṣe ni iye owo ti wn n ta goolu naa lọ soke niwọn 3%, eleyi ni iye owo r to ga julọ lati nkan bi ọdun kan sẹyin.


Alaye ree lori nkan to n ṣẹlẹ lati nu akọroyin ẹka ọrọ aje wa Theo Leggett
O fẹ ẹ to ida mẹta epo rbi ti Yuroopu n lo to ṣe lati Russia lo ti n wa.Koda afẹfẹ gaasi rẹ naa nkan bi ida 40% lo n wa lati ọdọ Russia.Pupọ awọn ọpa to n gbe epo ta n wi yi gba inu ilẹ Ukraine. Eleyi lo fa ti iye owo epo lagbaye ṣe lọ soke.
Owo epo rọbi taa mọ si Brent crude oilti re kọja $100 fun barẹli kan ti owo gaasi naa si ti gbera ju tatẹyinwa lọ.
Ko jọ pe iyatọ ba iye epo ti Russia n pese nisinyi. Amọ ibẹrubojo wa wi pe iyipada le ba ti eleyi si le mu ki iye owo rẹ lọ soke.

Awọn igbesẹ lati fi ijiya lelẹ n lọ lọwọ
Ni idahun si ikọlu Russia yi, awọn orileede ilẹ Gẹẹsi, Amẹrika ati ẹgbẹ Yuroopu EU ṣetan lati gbe ijiya mii lori Russia.
Ibẹru wa pe ijiya ti wọn n gbero yi ati ipalara ti ikọlu yoo fa le mu ki idaru ba ipese nkan oko ati awọn eelo miran to n wa lati Russia ati Ukraine.
Awọn orileede mejeeji yi lapapọ ni wọn n pese wheat julọ lagbaye ti wn a si maa gbe ọja yi kọja gba ibudokọ ọkọ ojuomi lagbegbe Black Sea.
Bakan naa ni Russia a tun maa pese aluminium, cobalt, copper, diamonds, fatalaisa, goolu, nickel, palladium, platinum, titanium ati irin.
Igbimọ Yuropuu ti ni ijiya to gbọngbọn lawọn yoo gbe le Russia lori tori nkan ti wọn ṣe yi.














