Police shot OPC member in Ibadan: Níbo ni Obasanjo Atoyebi, afurasí ọlọ́pàá tó pa OPC ní Ibadan wà?

Ọlọpaa kan di ibọn mu

Oríṣun àwòrán, NPoliceNG

Awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ni ipinlẹ Ọyọ ti n ke si ijọba ipinlẹ naa pẹlu awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣawari ọlọpaa kan to yinbọn pa olori awọn ọlọdẹ kan nilu Ibadan.

Alaga awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ni ipinlẹ Ọyọ, Alagba Rotimi Olumọ ṣalaye fun BBC pe, awọn n bi awọn alaṣẹ to yẹ ko gbe igbesẹ to tọ, lati dahun ibeere awọn.

Bakan naa ni Olumọ ni awọn ti gba awọn amofin to moye lati fi irinṣẹ ofin ṣawari ọlọpaa naa jade nibi to sa lọ ni kiamọsa.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?

Ni Ọjọbọ ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lagbegbe Imalefalafia nilu Ibadan.

Ọlọpaa kan ti orukọ rẹ n jẹ Ọbasanjọ Atoyebi ni wọn sọ pe o n gbe agbegbe naa ṣugbọn ti wọn ni loruloru lo maa n wọle bi ọrọ.

Awọn aladugbo naa, gẹgẹbi Alagba Rotimi Olumọ ṣe sọ, ni wọn ti pariwo titi nipa bi ọlọ paa naa se maa n fi oru wọlu.

Wọn ni ti yoo tun maa da igboro ru to ba n bọ loru, ṣugbọn ti wọn ni gbogbo igba ti wọn ba ti gbe ọrọ naa ko o loju, lo maa n fi ibọn dunkooko mọ awọn aladugbo naa.

Lọjọ buruku ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, olori awọn ọlọdẹ lagbegbe naa ti orukọ rẹ n jẹ Morufu Ganiyu lo gbe ọrọ ko afurasi ọlọpaa naa loju nigba to tun de torutoru gẹgẹ bi iṣe rẹ.

Amọṣa, wọn ni kaka ki afurasi ọlọpaa naa o tuuba, ko si tọrọ aforiji tabi fi suuru ṣalaye bi irin rẹ ṣe jẹ, agidi lo da ọrọ naa si.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn si ni eebu bayii lo n bu Morufu to jẹ olori awọn ọlọdẹ nibẹ.

Àkọlé fídíò, Aje Games: Eré ayò ọrọ̀ ajé ló ń wá ọ̀nà àbáyọ sáwọn ìṣòro tó ń bá Yorùbá fínra

Ikun ati ẹyin ni ọlọpaa ti yinbn pa ọmọ ẹgbẹ OPC:

Lẹyin tawọn mejeeji yii tahun si ara wọn fun igba diẹ ni wọn ni ọlọpaa naa fa ibọn ilewọ yọ to si yin in fun Morufu Ganiyu niwaju ati ni iku ki o to sa kuro lagbegbe naa.

Awọn eeyan kan fidi rẹ mulẹ pe ọmọ ẹgbẹ OPC ni oloogbe naa, eyi si kun ara idi ti wọn fi gba lati maa ṣe akoso abo lagbegbe Imalefalafia atawọn ibi ti wọn ti n ta ọkọ lagbegbe Ọsọsami.

Wọn ni oun pẹlu gba awọn ọlọdẹ to fi si agbegbe kọọkan ti wọn gba a fun to si n moju to wọn.

Wọn gbe oloogbe naa lọ sileewosan, ki wọn to gbe e lọ si ọdọ awọn oniṣegun ibilẹ to maa n yọ ọta ibọn lara.

"Wọn ri ọta ti ẹyin yọ lẹsẹkẹsẹ, ṣugbọn ọta to yin fun un ni inu yẹn ni wọn ko ri yọ tori o ti wọ ifun rẹ."

Eyi ni wọn ni o ṣokunfa iku rẹ ni alẹ ọjọ Satide mọju ọjọ aiku.

Awọn aladugbo naa ni gbogbo igba ti ọlọpaa naa ba ti n bọ loru lo maa n yinbọn soke, ti awọn aladugbo si ti kilọ fun un lọpọ igba pe ko dẹkun rẹ, ṣugbọn ti ko gbọ.

Iroyin ti a gbọ tun ṣalaye pe awọn aladugbo fi ibinu kọlu ṣọọbu iyawo ọlọpaa, Ọbasanjọ Atoyebi to wa lagbegbe naa ti wọn si ba awọn ọja to wa nibẹ jẹ.

Bakan naa la gbọ pe wọn tun fẹ dana sun ile to n ya gbe nibẹ ki baba onile rẹ atawọn ayalegbe ti wọn jọ wa nibẹ to bẹbẹ.

Àkọlé fídíò, Bukola Odufuwa: Mo ń ta oúnjẹ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́, gbálẹ̀, fọ aṣọ, pọnmi láì tọrọ agbe jẹun

Ki ni awọn ọlọpaa sọ?

Nigba ti BBC kọ si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ lori iṣẹlẹ naa lati mọ boya igbesẹ ti bẹrẹ, ọgbẹni Adewale Oṣifẹsọ ṣalaye pe iwadii n lọ lọwọ.

Nigba ti a tun beere boya wọn ti mu ọlọpaa ti ọrọ kan, O ni: "Iwadii n lọ lọwọ."