NDLEA in Ondo: Mary Donejay ní àfẹ́sọ́nà òun ti sálọ tó sì ku òun nìkan ní oko igbó

Oríṣun àwòrán, ndlea/instagram
Ọ̀rọ̀ ifẹ́, wọn ni bi adanwo lo ri, bẹẹ si ni ko si ohun ti ifẹ ko le gba lọwọ ẹnikẹni.
Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu obinrin kan tii se ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, Mary Donejay, ti ifẹ afẹju sọ di afurasi ọdaran.
Obinrin naa, ti ko pari iwe mẹwaa to fi pa ile ẹkọ ti, ni ọwọ ikọ amussẹya ajọ NDLEA to n gbogun ti gbigbe oogun oloro tẹ, lasiko isẹ ti wọn se lọ sawọn oko ọgbin igbo nipinlẹ Ondo
- Aya ọlọ́pàá tó kú sílè Gbenga Daniel ní òun kò gbà pé ọkọ̀ lásán ló pa ọkọ òun
- Làásìgbò níbi ìpàdé PDP l‘Osun mú ẹ̀mí méjì lọ, ọ̀pọ̀ fara pa, dúkìá jóná
- Ìtàn ayé Shina Rambo, adigunjalè tó fi ahọ́n èèyàn 100 mu ẹ̀kọ́, fi oyún 27 gún ọṣẹ
- Ìjà d'ópin, ogun ti tán! Ẹ wo bí Mide Martins àtí Olamide àbúrò rẹ̀ ti ń ṣàjọyọ̀ oríire
- Àwọn aṣòfin àpapọ̀ ń gbèrò owó ìfẹ̀yìntì àgbàdọjọ́ọkú fáwọn adarí wọn
- Irọ gbáà leléyii o! Àwa kọ́ la fún Fani-Kayode ní Sabuké tó fihan ilé ẹjọ́, kò gb'àìsàn wá sọ́dọ̀ wa - Iléèwòsàn Abuja
- Wo ohun tí Jaruma Oníṣòwò “Kayamata” tún ṣe tí wọ́n ń gbé e padà lọ s'ẹ́wọ̀n
Mary yii si ni wọn ko mọ awọn afurasi tawọn osisẹ ajọ NDLEA naa ko ni ọpọ oko igbo ti wọn dana sun nipinlẹ Ondo lọna ati mu adinkun ba ilokulo oogun oloro.
Ki lo sun arẹwa obinrin de ọgbin kukuye?
Yoruba ni ti ko ba si ẹsẹ, ẹsẹ kii dede sẹ, obinrin naa si lo salaye lẹkunrẹrẹ nipa ohun to sun de ibi ti wọn ba ọhun.
Nigba ti wọn n fi ọrọ wa Mary lẹnu wo, o ni aguntan to n ba aja rin gbọdọ jẹ igbẹ ni ọrọ oun, ọrọ ifẹ si lo gbe de oun de oko ọgbin kukuye.
O salaye pe ọrẹkunrin oun, Henry Daniel lo fa oju oun mọra si idi okoowo ọgbin igbo nipinlẹ Ondo.
Obinrin naa sọ pe Daniel yii lo seleri fun oun pe ere ti awọn ba ri nidi ọgbin Gbáná naa, ni awọn yoo fi se ayẹyẹ igbeyawo awọn.
Tọkọtiyawo afẹsọna naa si lo bọ sọwọ sinkun ajọ NDLEA lasiko ti osisẹ NDLEA ba wọn ni alejo ninu oko ọgbin igbo wọn.

Oríṣun àwòrán, ndlea/instagram
Nibo ni Mary ati Daniel ti pade ara wọn:
Obinrin naa salaye pe ilu Oba Ile nibi ti oun ti n sisẹ nile ọti kan ni oun ti se alabapade Daniel.
"Lẹyin osu diẹ ti emi ati Daniel ti n se wọle-wọle lo ni ka gbe ara wa siyawo sile, inu emi naa si dun lati fẹ bii ọkọ mi pẹlu ireti pe igbeyawo wa yoo layọ.
Lootọ lo sọ fun mi pe oun ti lọ si ẹwọn ri nitori pe oun n se okoowo igbo, to si ni ki n dara pọ mọ oun ka jọ maa se okoowo naa, ka si se igbeyawo.
O seleri fun mi pe oun yoo si ibudo itaja kan fun mi ti maa ti maa ta orisirisi nnkan eelo inu ile, inu mi si dun si nitori n ko ni iwe ẹri kankan lọwọ."
Mo ti bimọ meji tẹlẹ fun ọkunrin miran ki n to pade Daniel:
Nigba to n salaye siwaju, Mary ni oun ti bi ọmọ meji fun ọkunrin kan saaju ki oun to se alabapade Daniel.
O ni awọn ọmọ mejeeji naa lo n gbe pẹlu mama oun, isẹ ti oun si n se fun Daniel ninu oko ọgbin igbo naa ni lati maa se ounjẹ fun.
O ni lootọ ni wọn sọ fun awọn pe awọn osisẹ ajọ NDLEA ti de sinu oko awọn, amọ ki oun to sa asala fun ẹmi oun, wọn ti rọgba yi oun ka.
"Ọkọ afẹsọna mi ti salọ n tiẹ, to si fi mi silẹ, mo ti ri nigba meji, to maa n ta igbo fawọn eeyan amọ n ko beere bo se n ta eroja naa."
Ajọ NDLEA ni oun gunle igbesẹ lati ba awọn ewe ọlà naa jẹ lati ibẹrẹ ọgbin rẹ ki awọn olokoowo igbo ma baa ri ọja ta, ti iwa ọdaran yoo si dinku ni awujọ wa.

Owó wọgbó l'Ondo! NDLEA dáná sun oko ìgbó éékà 162 tówó rẹ̀ tó ₦900m

Oríṣun àwòrán, NDLEA
Yoruba ni bi irọ ba lọ titi fun ogun ọdun, ọjọ kan soso pere ni otitọ yoo ba, bẹẹ si ni asegbe kankan ko si, asepamọ lo wa.
Bi ọrọ se ri gan ree pẹlu awọn eeyan kan to n tako ofin ijọba nipa sise okoowo igbo, ti wọn si gbin rẹpẹtẹ sinu oko wọn.
Se ni ariwo ta, ti oju awọn afurasi agbigbo si han sode lasiko ti awọn osisẹ ajọ to n gbogun ti lilo oogun oloro lorilẹede yii, NDLEA, se abẹwo sipinlẹ Ondo.
- Canada sọ igbó mímu àti títà rẹ̀ di ìrọ̀rùn
- Akeredolu, Ọgá NDLEA lọ kọ nípa gbíngbin igbó ní Thailand
- Ó sàn kí ẹ pa mí ju kí ẹ ba oko tí mo gbin igbó sí jẹ́ lọ- Afurasi Clement sí NDLEA
- Wo àwọn ewu àti ànfàní márùn ún tó wà nínú igbó mímu
- Ọwọ́ NDLEA tẹ àádọ́jọ èèyàn tó gbé oògùn olóró l‘Ondo
- Idí tí àwọn dókítà ọpọlọ kò fi faramọ́ lílo igbó fún ìtọ́jú àìsàn
- Ọwọ́ NDLEA tẹ àádọ́jọ èèyàn tó gbé oògùn olóró l‘Ondo
- Ọwọ́ agbófinró tẹ obìnrin tó gbé 'cocaine' sínú ojú ara rẹ̀ l'Abuja
- Ọwọ́ NDLEA tẹ ìyá ẹni ọdún 80 pẹ̀lú oògùn olóró bíi kokeni, heroin, colorado àti skuchies
Ijọba ibilẹ marun nipinlẹ Ondo si ni awọn osisẹ ajọ NDLEA naa ti pitu ọwọ wọn lawọn oko igbo ti wọn gbin yika awọn agbegbe naa.

Oríṣun àwòrán, NDLEA
NDLEA dana sun eeka oko igbo to to ọtalerugba o din marun (255):
Ni ipinlẹ Ondo, iroyin kọ sisọ nigba ti awọn osisẹ ajọ NDLEA ba ipinlẹ naa lalejo, ti wọn si jo awọn oko ti wọn gbin igbo si lọpọ yanturu.
Awọn oko igbo ọhun ni ajọ naa kede pe eekan rẹ to ọtalerugba o din marun.
Bakan naa, apapọ ire oko igbo naa ni wọn sọ pe odiwọn rẹ to miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹrun naira (N900m).
- Wo ohun tí Jaruma Oníṣòwò “Kayamata” tún ṣe tí wọ́n ń gbé e padà lọ s'ẹ́wọ̀n
- Ìtàn ayé Shina Rambo, adigunjalè tó fi ahọ́n èèyàn 100 mu ẹ̀kọ́, fi oyún 27 gún ọṣẹ
- Ẹ̀yìn òfin tó fààyè gba lílo Hijab nílé ẹ̀kọ́ ní mo wà - Gomina Kwara
- Ṣé wọ́n le ṣún ìbò síwájú torí bí Buhari kò ṣe buwọ́lu àtúnṣe òfin ìdìbò 2022?
- Sotitobire: Ẹ wá wo ohun t'Ọ́lọ́run ń ṣe ní ìjọ mi lẹ́yìn tí mo bọ́ ní ẹ̀wọ̀n gbére tẹ́ẹ tì mí lọ
- Kí ni Sajẹ́ńtì Ọlọ́pàá lọ ṣe nílé gómìnà Ogun tẹ́lẹ̀ tó tẹ́rí gba ikú?
Ọwọ kekere kọ ni ajọ NDLEA fi mu isẹ naa nitori lati ileesẹ ajọ naa marun lo parapọ lati se abẹwo si awọn oko igbo naa.
Awọn oko igbo ọhun ni wọn sọ pe wọn gbin kaakiri ipinlẹ Ondo, ti ọwọ si ba olokoowo igbo mẹtala.

Oríṣun àwòrán, NDLEA
Atupalẹ awọn oko igbo ta sọ ina si nilu kọọkan ree:
Nigba to n salaye awọn oko igbo ti wọn sọ ina si, NDLEA ni apapọ iye eeka oko igbo ti wọn dana sun naa jẹ mejilelọgọjọ
Ajọ naa ni aadọta eeka ilẹ ti wọn gbin igbo si lọna aitọ nilu Ogbese ni oun da ina sun.
Bakan naa ni ọmọ sori nilu Ipele nibi ti wọn ti dana sun eeka oko igbo mọkanla.
Eeka oko igbo mejidinlọgọta lo jona raurau lati ọwọ ajọ NDLEA lagbegbe Okeluse ati Ose.
Tun wẹ, eekan ọgbọn ilẹ ti wọn gbin igbo si ni wọn tun sọ ina si lagbegbe Ala.
Oko igbo to to eeka marun miran ti wọn gbin seti odo Ogbese, Omolowo ati Power line si tun jona raurau.

Oríṣun àwòrán, NAFDAC
A ri apo igbo gba pada lọwọ awọn olokoowo igbo:
Se ni ọwọ awọn osisẹ ajọ NDLEA dẹ, ti wọn ko si rinrin ajo lasan tabi san ọwọ pada wale lẹnu irinajo wọn yika ipinlẹ Ondo naa.
Awọn osisẹ naa, ti wọn wa lati awọn ileesẹ ajọ NDLEA to wa nipinlẹ Ondo, Edo, Osun, Oyo ati Ekiti ni igbakeji oludari igbimọ amusẹya ajọ naa, Nnadi Chidi ko sodi.
Lasiko irinajo wọn ọhun ni wọn tun gba apo eso igbo to jẹ ọtalerugba o din mẹwa kilogiramu lagbegbe kan.
Bakan naa ni wọn tun gba kilogiramu ewe igbo tutu mẹtalelọgọta ati ogun kilogiramu ewe igbo gbigbẹ.
Ko tan sibẹ, wọn tun gba ẹrọ meji ti wọn fi maa n fọn omi sori oko igbo ati ọpa onike ti wọn fi n fa omi jade latinu tanki.
Awọn eeyan kan lo ta wa ni olobo pe wọn ti gbin eso igbo yika ipinlẹ Ondo:
Nigba to n salaye eredi itọpinpin ti wọn se naa, ọga to ko ikọ amusẹya NDLEA sodi lọ sipinlẹ Ondo ni igbesẹ naa lo wa nibamu pẹlu ipinnu oludari agba fun ajọ naa, Ajagunfẹyinti Buba Marwa.
O ni ipinnu rẹ ni lati mu adinku ba ọna ti wọn n gba pin oogun oloro kiri yika orilẹede yii,
Gẹgẹ bi Nnadi se wi, awọn eeyan kan lo ta ajọ NDLEA to wa nipinlẹ Ondo ni olobo nipa awọn oko ti wọn gbin igbo si kaakiri ijọba ibilẹ marun nipinlẹ naa.
O salaye pe igbesẹ ọjọ ta ba ri ibi, ni ibi wọlẹ ni awọn fi olobo naa se, ti awọn si tawọn ọmọ igbimọ amusẹya ajọ NDLEA nidi kan, lati lọ ba gbogbo awọn oko igbo ọhun jẹ.



















