Femi Fani-Kayode: Iléèwòsàn Kubwa l'Abuja wú ẹ̀rí sítà tó fihàǹ pé FFK parọ́

Femi Fani-Kayode

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Awọn alasẹ ile iwosan ijọba to wa ni agbegbe Kubwa niluu Abuja ti ni awọn kò gba Minisita irina ofurufu tẹ́lẹ̀ rí, Femi Fani-Kayode gẹgẹ bi alaarẹ nileewosan awọn.

Oludari ẹ̀ka àkọsílẹ̀ eto ìlera nileewosan náà, Bassey Amah fi èyí lédè fún Adajọ agba Olubunmi ti ilé ẹjọ́ to n gbọ́ ẹjọ́ àkànṣe ni Ikeja nipinle Eko pe Kayode kii ṣe aláìsàn ọdọ awọn kò si ni àkọsílẹ̀ itọju lọdọ àwọn.

Femi Fani-Kayode ń jẹjọ lọwọ lórí ẹ̀sùn mejila to ni ṣe pẹlu lilo iwe yíyí gẹgẹ bii ìwé ẹ̀rí ìlera àtàwọn ìwé míì tí wọn yí.

Àjọ to n rí si ìwà jẹgudujẹra, EFCC tí kanlẹ fi ẹ̀sùn kan an pé ó lo Dokita kan, Ogieva Oziegbe láti kọ ayédèrú ìwé ẹ̀rí ìlera fún un èyí ti ìròyìn ni ó fihan níwájú Adajọ Daniel Osiagor to n dájọ́ rẹ lórí ẹ̀sùn ṣíṣe owó ìlú basubasu amọ tí Fani-Kayode ni òun kò jẹbi ẹ̀sùn náà.

Nigbati tí ìgbẹ́jọ náà yoo fi tesiwaju ni Ọjọbọ, o hande pe dókítà to buwọlu ìwé ẹ̀rí náà kii ṣe oṣiṣẹ ileewosan Kubwa. Àwọn aláṣẹ ileewosan náà nígbà tí ìwádìí wọn jáde, ó fihan pe awọn kan yí ìwé náà ni.

Àkọlé fídíò, Bukola Odufuwa: Mo ń ta oúnjẹ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́, gbálẹ̀, fọ aṣọ, pọnmi láì tọrọ agbe jẹun

Nígbà náà ni Adajọ dá ẹjọ́ náà láti gbé àjọ EFCC lẹyin to sì ni lóòtọ́ bo tilẹ̀ jẹ pe ileewosan Kubwa náà ni ìwé ẹ̀rí yìí tí jáde wá, wọn kò ní aridaju ayafi ti olodani kan ba ṣi aṣọ lójú ẹ atipe Ẹlẹ́rìí tí wọn pé gẹ́gẹ́ bíi asoju ileewosan ohun ni nomba to wà lórí ìwé náà kò tilẹ̀ ki n se tí ileewosan awọn rárá.

Adajọ tí sún ẹjọ́ náà síwájú di ọjọ karundinlogbon oṣù Kejì ọdún 2022.