Sotitobire: Ẹ wá wo ohun t'Ọ́lọ́run ń ṣe ní ìjọ mi lẹ́yìn tí mo bọ́ ní ẹ̀wọ̀n gbére tẹ́ẹ tì mí lọ

Ijọ Pasitọ Sotitobire

Oríṣun àwòrán, Atorise

Ṣe ni ero n wọ kẹtikẹti ninu agbala ile ijọsin Pasitọ Alfa Babatunde Sotitobire ni ilu Akure, ipinlẹ Ondo nibi to ti ṣagbekalẹ isin orin iyin ọlọgọrun un ọjọ.

Ninu gbọngan ijọ naa eyi to jẹ ile akọku latari iṣẹlẹ bi awọn ọdọ ilu ṣe dana sun Ṣọọsi naa ni ọdun bii meji sẹyin lasiko ti iroyin gbode kan pe ọmọ ọdun kan nni, Gold Kolawole dede di awati ninu ijọ rẹ lasiko ti isin n lọ lọwọ.

Sotitobire ti lọ ẹwọn gbere ri amọ...

Iṣẹlẹ yii nigba ti wọn fa a lọ fa a lọ fa a bọ laarin ijọ Sotitobire, idile Gold Kolawole to fi mọ ijọba ipinlẹ Ondo pada di ero ẹwọn gbere lẹyin atimọle ọpọlọpọ ọjọ ṣaaju idajọ.

Ondo Kidnap

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Mo kàn fẹ́ fi ọmọ tó sọnù gba owó lọ́wọ́ Sọtitobire ni

Ariwo sọ nigba ti wọn dajọ ẹwọn gbere fun Pasitọ Sotitobire latẹnu awọn alatilẹyin rẹ atawọn to tako iwa ati iṣẹ iranṣẹ rẹ.

Ko pẹ pupọ lẹyin ọdun meji ni iroyin tun pada jade pe wọn ti da Sotitobire silẹ lẹwọn wi pe ko jẹbi ẹsun iditẹ ji ọmọ gbe ti wọn fi kan an mọ.

Àkọlé fídíò, A kò tíì dẹ́kun àdúrà pé kí àṣírí àwọn tó jí ọmọ gbé tú - Bisola Alfa Sotitobire

Eyi lo faa to fi ṣe agbekalẹ eto ọlọgọrun un ọjọ yii lati fi fi ẹmi imoore han pe Ọlọrun ko o yọ.

Ninu fidio rẹ to jade sori ayelujara ninu eyi to ti n ba gbajumọ olorin Lanre Teriba ti ọpọ mọ si "Atorise" to pe lati wa kọrin ninu isin naa sọrọ, o ni:

"Ọkunrin ti wọn n pe ni Sotitobire niyii, ti gbogbo agbaye ro ẹjọ rẹ, ti wọn jo ijọ rẹ nina kanlẹ, wọn sọ gbogbo nkan ti mo ni da ilẹ̀ amọ ninu ara ni o".

Àkọlé fídíò, Sotitobire: Ọkọ mi kò mọ̀ Jegede PDP rí, kódà kò fa ẹnikẹ́ni kalẹ̀ dípò Akeredolu- Bisola

O ṣalaye bi wọn ṣe jo dukia rẹ, mọto rẹ, ati bi wọn ṣe ju oun si ẹwọn gbere amọ to ni Ọlọrun mu oun jade nipasẹ ile ẹjọ Kotẹmilọrun lẹyin ọdun meji.

"Wọn ko irọ mọ mi lẹsẹ ni toripe Ọlọrun gba fun mi ninu iṣẹ Oluwa, Oluwa da mi lohun ju ẹgbẹ mi lọ tori wọn ni bawo ni mo ṣe le jẹ ọmọ ilu yii ki n si maa ṣoriire ninu ilu yii gan".

Wolii Sotitobire ni nigba ti ohun ti wa de bayii, idi niyi ti awọn fi n ṣe akanṣe eto orin iyin fun ọgọrun ọjọ ti awọn olorin ẹmi nla nla yoo si wa kọrin nibẹ.

Àkọlé fídíò, Money Ritual: Ǹ kò le bèèrè

O ni lati igba ti oun ti wa ninu ẹwọn ni iyawo oun ti n sọ pe ki awọn pe Atorise lati wa kọrin ni Ṣọọṣi awọn nigba ti oun si ti jade bayii, o ni oun le pe Atorise.

"Awọn to n ba mi fa a gan ti kọ ọ lorin pe Baba ma jẹ n jiya... Ọmọ ale ni Satani".

Bẹẹ naa ni gbajugbaja Olorin naa korin bọ ẹnu pe ẹni ti Ọlọrun yan ti ko sẹni to le koju ija si laye.