Ondo Kidnapping: Àgbà oyè sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀ nígbà tí orun kàyéfì gbé àwọn ajínigbé tó mu nígbèkùn

Oríṣun àwòrán, other
Kayefi gbaa ni isẹlẹ kan to waye nipinlẹ Ondo eyi to n se ọpọ eeyan ni haa-hii.
Oloye agba kan ni ilu Igaṣi Akoko ni ipinlẹ Ondo, Ojo Ajagunna ti awọn kan ji gbe lọjọ Ẹti, la gbọ pe o ti fi ẹsẹ ara rẹ rin wọle laisi ọrọ a n san owo itanran kankan.
Agba oye Ajagunna ṣalaye fun awọn eeyan rẹ pe oun lanfani lati sa kuro ni ibuba awọn ajinigbe naa lẹyin ti wọn sun lọ rangbọndan.
O ni oun ko lee sọ boya ogun abẹnugọngọ lo ja wọn tabi asasi.
- Sotitobire: Ẹ wá wo ohun t'Ọ́lọ́run ń ṣe ní ìjọ mi lẹ́yìn tí mo bọ́ ní ẹ̀wọ̀n gbére tẹ́ẹ tì mí lọ
- Ìtàn Àrọ̀gìdìgbà jẹ́ kí ń rò pé bàbá mi yan Yemọ̀ja ní àlè - Ọmọ Fagunwa
- A kò parí ìwádìí wa kí wọn tó tú afurasí akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún lórí ikú Sylvester Oromoni sílẹ̀ - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Donald Trump dá ojú òpó Truth Social tirẹ̀ sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n le kúrò lórí Twitter àti Facebook
- Abba Kyari ní àìsàn ìtọ̀ súgà, ó sì nílò ìtọ́jú ìtọ́jú kíákíá, ẹ tu sílẹ̀ - Agbẹjọ́rò
- Ọ̀pọ̀ òṣèré gbarata bí Mama Rainbow ṣe bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kún àsun-ùn-dákẹ́
- Ẹ̀mí bọ́ nígbà tí ọ̀rẹ́ méjì bẹ́nú fúnra wọn nídìí tẹ́tẹ́, ọ̀kan fi ayùn gé ẹsẹ̀ èkejì
- "Àwa ọ̀dọ́ yóò wa ní ọ̀kan bíi àkókò EndSARS láti kojú àwọn àgbà òṣèlú ní 2023"
- Naijiria nílò àwọn ‘Ọlọ̀tẹ̀’ tí yóò máa gbéna wojú ìjọba kó lè tẹ̀síwájú - Obasanjo
Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ, pupọ awọn eeyan ilu naa ni wọn banujẹ lasiko ti iṣẹlẹ buruku naa ṣẹlẹ si oloye Ajagunna.
Bi okiki ijinigbe rẹ ṣe rinlẹ to ni ilu naa, ni okiki itusilẹ rẹ naa tun ṣe gbalẹkan gẹgẹ bi a ṣe gbọ
Ki ni ọlọpaa sọ?
Gẹgẹ bi ohun ti ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo sọ, iyawo oloye naa lo kọkọ lọ fi iroyin ijinigbe rẹ to awọn ọlọpaa leti ni agọ ọlọpaa to wa ni ilu naa.
Nibi ti awọn ọlọpaa ti n ṣeto iwadii wọn lọwọ, ni iroyin miran tun kan wọn lara pe Oloye Ajagunna ti pada sile rẹ.
Alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Arabinrin Funmilayọ Ọdunlami ṣalaye fun BBC Yoruba pe ohun ti oloye naa sọ fun awọn ni pe, fọnfọn ti awọn to ji oun gbe sun, lo mu ki oun yara sa asala fun ẹmi oun kuro ni akata wọn.
Ṣugbọn ohun to fa orun asunmaparada wọn naa, ṣi jẹ eyi ti ẹnikẹni ko tii lee ṣe alaye rẹ.
















