Obasanjo: Bí àwọn aṣíwájú ìran Muritala/ Obasanjo bá ṣì ń du ipò òṣèlú, á jẹ́ pé nǹkan míì ti wọ́

Oloye Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, other

Àkọlé àwòrán, Ọbasanjọ ni ki awọn iran Murtala/ Ọbasanjọ o yẹba lo tọna

Aarẹ tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti ke sawọn iran agbagba ni Naijiria lati fi aye silẹ fun awọn ọdọ, ki wọn le e tun orilẹede Naijiria ṣe ki wọn si sọ ọ di ilẹ ogo.

Oloye Ọbasanjọ ni ko si iyi fun baba to n ba ọmọ rẹ du ogun, ohun to yẹ kawọn agbaagba o ṣe ni ki wọn fi omi ọgbọn ati iriri ti wọn ni ran awọn ọdọ Naijiria lọwọ.

O tun ni o yẹ ki wọn tọ awọn ọdọ yii sọna ni pẹlu ọgbọn ati imọ lati ṣe ayipada orilẹede Naijiria.

Nibi idanilẹkọ ajọ idagbasoke ti wọn fi sọ ori Murtala Muhammed pẹlu akori, 'Gbigbogun ti igbesumọmi, iwa janduku ati ijinigbe kaakiri Naijiria' ni Oloye Obasanjọ ti sọ ọrọ naa.

Àkọlé fídíò, Money Ritual: Ǹ kò le bèèrè

Bi awọn eeyan iran Murtala/Obasanjọ ba ṣi n du ipo oṣelu, a jẹ pe nnkan ku diẹ kaato:

Ọrọ aarẹ igbakan naa n fẹ da bii pẹtẹpẹtẹ ta a na ni pọpa si awọn agbaagba oloṣelu ti wọn n gbaradi lati dije fun ipo aarẹ lọdun 2023.

O fi ọrọ rẹ naa ṣe esi si ohun ti oludanilẹkọọ pataki nibi eto naa, Gomina Kayọde Fayẹmi ti ipinlẹ Ekiti sọ, to ni ileewe alakọbẹrẹ loun wa, lasiko ti Oloogbe Murtala Mohammed tukọ ijọba orilẹede Naijiria.

Oloye Ọbasanjọ ni ohun ti Naijiria nilo bayii ni ajọṣepọ laarin iran awọn agbalagba ati iran awọn ọdọ.

"Fayẹmi ni oun ṣi wa nileewe alakọbẹrẹ nigba ti Murtala ati Ọbasanjọ wa nipo.

Nitorinaa, bi awọn eeyan to ti gberi lasiko Murtala/Ọbasanjọ ba ṣi n ba a yin du ipo gẹgẹ bii gomina, a jẹ wi pe nnkan ti buru niyẹn.

Ọbasanjọ ni ki awọn iran Murtala/ Ọbasanjọ o yẹba lo tọna bayii, ki wọn si fi ọgbọn, imọ tabi iriri gbogbo ti wọn ba ni tọ awọn iran to n bọ sọna.

Ki l'Ọbasanjọ sọ lori eto abo to mẹhẹ ni Naijiria?

Ọbasanjọ ni bi awọn ohun ija oloro bi ibọn ati bẹẹbẹẹ lọ ṣe di tọrọfọnkale lẹyin ogun abẹle to waye, ni oun di ẹbi iṣoro eto abo to mẹhẹ bayii ni Naijiria ru.

O fi kun un pe yatọ si wahala ti idasilẹ ofin Sharia da silẹ, aisi iṣẹ fun awọn ọdọ naa da kun bi iwa igbesumọmi ṣe wa gogo bayii lorilẹede Naijiria.

O tun ṣalaye pe ẹru kan ṣoṣo to ba oun nipa ọrọ Boko Haram ti pada wa n ṣẹ bayii pẹlu bi ẹgbẹ agbesummi naa ṣe bẹrẹ si ni ajṣepọ pẹlu awọn ẹgbẹ agbesumọmi miran lagbaye.

Ajọṣepọ Oluṣẹgun Ọbasanjọ pẹlu Murtala Mohammed:

Oloye Ọbasanjọ ni Olori ijọba ologun lorilẹede Naijiria lọdun 1976 si 1979 nigba to gbe ijọba fun alagbada.

Oun naa si ni aarẹ nigba ti ijọba alagbada pada ldun 1999.

Ogagun Murtala Muhammed ni tirẹ ni olori ijọba ologun lọdun 1976, ki awọn ọmọogun to ditẹ gba ijọba lọwọ rẹ labẹ idari Dimka yinbọn pa a ni ilu Eko.

Lẹyin iku rẹ ni awọn ẹbi rẹ atawọn ọrẹ ati ololufẹ rẹ ba gbe ajọ iranti rẹ, Murtala Muhammed Foundation kalẹ.