Ọkùnrin kan kú nígbà tí ọ̀rẹ́ fi ayùn ge ẹsẹ̀ rẹ̀ sọnù ní Queensland

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkunrin kan ti dero agọ ọlọpaa ẹjọ lori ẹsun ipaniyan lẹyin to fi ayun ge ẹsẹ ọkunrin miran ni Australia.
Oloogbe ọhun ku si gbagede igbafẹ kan ni Innisfail, ni apa iha Ariwa Queensland, ki awọn eeyan to n kọja lọ to ri lẹba ọna.
Awọn ọlọpaa gbagbọ pe awọn mejeji ti ta tẹtẹ ṣaaju, wọn si se adehun laarin ara wọn pe ẹni ti ọjọ ori rẹ kere ju ninu awọn mejeji, ni yoo ge ẹsẹ ẹni to dagba ju ninu wọn.
- Aláboyún àti èèyàn mẹ́jọ míì jóná kọjá mímọ̀ nínú ìjàmbá ọkọ̀ n'Ilorin
- Naijiria nílò àwọn ‘Ọlọ̀tẹ̀’ tí yóò máa gbéna wojú ìjọba kó lè tẹ̀síwájú - Obasanjo
- Ẹ wo Bàbá tó pòórá lẹ́ni ọdún 26, àmọ́ tó dédé yọ sí ìlú lẹ́ni ọdún 63
- Ó ṣeéṣe ká ti ẹsẹ̀ òfin bọ èsì ìbò abẹ́nú gómìnà APC l‘Osun - Aregbesola
- "Agbódegbà ní báǹkì àtàwọn míì ló wà nídìí ìdigunjalè ọkọ̀ agbówórìn n‘Ibadan"
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni olubi ọmọ níí ṣe pẹ̀lú àyànmọ́ ọmọ láyé?
- Mo nífẹ̀ẹ́ ìyàwó mi jú ìyá àtàwọn ọmọ mi lọ - Kolawole Ajeyemi
- Wo àwọn obìnrin tó ń bímọ láì sùn ti ọkùnrin ní àgbáyé
- Àwọn alákatakíti ẹ̀sìn pa ọmọ-ogun Mali lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ ti France kó ọmọogun rẹ̀ kúrò
Ẹni ọdun mẹ́rìndínláàdọ́rin ni oloogbe, nigba ti afurasi jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn.
Ọlọpaa ni awọn mejeji ti mọ ara wọn ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.
Gẹgẹ bii ohun ti ọlọpaa sọ, awọn mejeji wa ọkọ lọ si gbagede igbafẹ naa, lẹyin ogun iṣẹju si ni afurasi fi ayun ti wọn fi n ge igi rẹ ẹsẹ oloogbe sọnu.
Lẹyin to ge ẹsẹ rẹ tan, ni afurasi gbe oloogbe naa lọ sinu ọkọ ti wọn gbe wa, to si ba tirẹ lọ.
Ẹnikan to n gba agbegbe naa kọja lo ke si awọn adoola ẹmi, amọ oloogbe dagbere faye lẹyin iṣẹju diẹ si asiko naa.
Ọlọpaa to n ṣewadii ọrọ naa, Gary Hunter sọ pe "Lati nnkan bii ọdun mẹrinlelọgbọn ti mo ti n ṣiṣẹ ọlọpaa, mi o tii ri irufẹ nnkan bayii ri."
Afurasi naa yoo foju bale ẹjọ lọjọ Aje.

















