Ilorin accident: Èèyàn mẹ́sàn án jóná kọjá mímọ̀ nínú ìjàmbá ọkọ̀ nílùú Ilorin

Ilorin accident

Oríṣun àwòrán, @___communicator

O kere tan, eeyan mẹsan an ti jade laye ninu ijamba ọkọ kan ni ipinlẹ Kwara.

Ijamba naa waye laarọ ọjọ Isinmi niwaju papakọ ofurufu ilu Ilorin to wa loju ọna Ilorin si Eyenkorin.

Adari ileeṣẹ to n ri si irinkerindo oju popo ni Kwara, Jonathan Owoade sọ pe ọkọ akero Toyota Hiace ati ọkọ Toyota Corolla kan ni ọrọ naa kan, nigba ti eeyan mẹtadinlogun fara gba ninu iṣẹlẹ ọhun.

Oṣojumikoro kan sọ fun awọn akọroyin pe ọkọ mejeji fori ṣo ara wọn lasiko ti ọkọ ayọkẹlẹ Toyota to n bọ lati inu papakọ ofurufu fori sọ ọkọ Toyota Hiace akero to n rinrinajọ lọ siluu Eko, lẹyin naa ni ina sọ.

Iroyin ni awọn mẹsan an to jade laye ninu ijamba naa jo kọja mimọ, wọn si ti ko oku wọn lọ si ile iwosan ẹkọṣẹ iṣẹgun ti fasiti Ilorin.

Yatọ si awọn mẹsan an to ku yii, awọn marun un mi tun farapa, amọ wọn ti n gba itọju lọwọ nile iwosan.

Ẹwẹ, awọn okunrin mẹta mii to wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ naa moribọ.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, adari FRSC ni Kwara sọ pe ijamba naa iba ma ti waye ti ko ba si ere asaju loju popo.

Àkọlé fídíò, Segun iberu

O si tun rọ awọn awakọ loju popo lati ṣọra fun ere asapajude.

Owoade tun kilọ fun awọn awakọ lati ṣọra fun kiko epo bẹntiro pamọ sinu ọkọ wọn.

Lẹyin naa lo ba ẹbi awọn to ba ijamba naa lọ kẹdun.

O tun sọ pe FRSC yoo ṣiṣẹ takun-takun lati ri daju pe irufẹ ijamba bẹẹ ko waye mọ.

Àkọlé fídíò, Oja Odan nibi ti wọn ti dáná sún afurasi meji ti wọn ba ori eeyan lọwọ wọn