Olusegun Obasanjo: Èèyàn kò lè jẹ́ olótìtọ́ láì jẹ́ alátakò

Olu

Oríṣun àwòrán, @thesunnigeria

Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Olusegun Obasanjo ti sọ pe orilẹ-ede Naijiria nilo ọpọ awọn alatako ti yoo maa sọ oju abẹ niko fun ijọba to ba wa lode.

Obasanjo ni eyii ni ọna kan gboogi ti idagbasoke yoo fi de ba Naijiria.

Baba Iyabo lo sọ ọrọ yii lasiko to n ṣide eto ifilọlẹ iwe itan igbeaye Babanla Adinni ti Egba, Oloye Tayo Sowunmi, niluu Abeokuta, eyii ti wọn fi sami ayẹyẹ ọgọrin ọdun rẹ loke eepẹ.

Lasiko to n sọrọ nibi eto naa, Obasanjo ni ti Naijiria ba fẹ ni ilọsiwaju to lapẹrẹ, awọn ẹgbẹ alatako gbọ

dọ maa sọko ọrọ si ijọba lai wo oju ẹnikẹni.

Àkọlé fídíò, Aremu: Eré ìtàn nípa ìbí, àti jéèyàn pẹ̀lú ìpèníjà Olusegun Aremu Obasanjo

Balogun Owu sọ pe ẹnikẹni to ba fẹ gbe igebaye olootọ ati eyii ti ko ni abawọn gbọdọ jẹ alatako.

Ninu ọrọ rẹ, o ni "Nigba ti mo wo iwe yii, mo bere lọwọ ara mi eredi ti eeyan fi maa pe ara rẹ ni alatako... amọ ohun to dara ni."

"Ootọ to wa nibẹ ni pe ẹnikẹni to ba fẹ gbe igbaye otitọ ati eyii ti ko ni abawọn, ẹni naa gbọdọ jẹ alatako."

"Awọn akoko kan yoo wa ti awọn eeyan yoo fẹ ki irufẹ ẹni bẹẹ ṣe awọn nkankan, amọ ti yoo kọ jalẹ pe rara, mi o ṣe."

Obasanjo pari ọrọ rẹ pe, orilẹ-ede wa ree, ko si orilẹ-ede mii ti a le pe ni tiwa bi ko ṣe eyii ti a wa ninu rẹ yii."

"Naijiria nilo awọn alatako pupọ si, awọn ti yoo soju abẹ niko pe nnkan yii ko dara to fun ilọsiwaju Naijiria, nitori naa, mi o ni darapọ mọ wọn to n ṣe."

Àkọlé fídíò, Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Awọn alatako ijọba lọwọ yii:

Awọn kan ti n gbena woju ẹkun ijọba Naijiria ki Baba Iyawo to fi ọrọ rẹ yii lede, amọ lọpọ igba ni ijọba maa n gbogun ti irufẹ awọn eeyan bẹẹ.

Yatọ si awọn to wa ninu ẹgbẹ oṣelu ti kii ṣe ti ijọba to wa lori alefa, awọn ajijagbara atawọn araalu mii ti n woju ijọba Naijiria.

Lara awọn eeyan naa ni amofin agba, Femi Falana, ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Sunday Igboho, adẹrinpoṣonu, Mr Maccaroni, oloṣelu ati onkọwe, Reno Omokri, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àkọlé fídíò, Oja Odan nibi ti wọn ti dáná sún afurasi meji ti wọn ba ori eeyan lọwọ wọn

Ta ni Olusegun Obasanjo:

Oloye Mattew Olusegun Aremu Okikiola Obasanjo ni aarẹ Naijiria tẹlẹ laarin ọdun 1999 si 2007.

Saaju lo ti dari ijọba ologun ni Naijiria tẹlẹ laarin ọdun 1975 si 1979.

Bakan naa ni Oloye Obasanjo ti se ẹwọn ri laye ijọba Sani Abacha laarin ọdun 1995 si 1998 nitori ẹsun iditẹ mọ ijọba.

Aarẹ ana tẹlẹ naa, tii se ẹni ọdun marundinlaadọrun lo jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ogun, to si fẹran lati maa sọrọ nipa igbesẹ aidaa ti ijọba to ba wa lori aleefa ni Naijiria ba n gbe.