Osun APC Primaries: Aregbesola tako èsì ìbò abẹ́nú gómìnà APC l‘Osun torí àwọn akùdé kan

Aregbesola ati Oyetola

O seese ka lọ sile ẹjọ tori awọn akude to waye ninu ibo abẹnu Osun - Aregbesola

Kaka ki ewe agbọn dẹ nidi eto idibo abẹnu gomina to waye ni ipinlẹ Osun lọjọ Satide to kọja, ko ko ko lo tun n le si.

Idi ni pe igun alatako ninu eto idibo naa, to n doju kọ gomina to wa lori oye, Adegboyega Oyekola, ti tako abajade esi ibo naa.

Koda, Minisita fọrọ abẹle, Rauf Aregbesola, tii se alatako gboogi ninu eto idibo naa, ti wa mẹnuba awọn kudiẹ-kudiẹ to waye lasiko ibo naa, ti ko fi jẹ itẹwọgba.

Aregbesola ni igun Adeoti ti oun n tẹle lẹyin, ti n se akojọpọ awọn esi ibo abẹnu naa, kaakiri gbogbo awọn agọ idibo to wa nipinlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Oyetola, Aregbesola àti Tinubu ni ọ̀rọ̀ náà wa láàrin wọn

O ni lẹyin ayẹwo naa, o seese ki awọn gbe igbesẹ lati fi ẹsẹ ofin wo esi naa.

Atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ Aregbesola feto iroyin, Sola Fasure fisita lori abajade esi ibo abẹnu naa lo pe akori rẹ ni 'Gbe ori rẹ soke'.

Awọn akude ti Aregbesola tọka si ninu ibo abẹnu APC ni Osun:

Sola Fasure wa tẹsiwaju lati kede awọn akude ti Aregbesola mẹnuba ninu eto idibo abẹnu naa.

Lara awọn akude naa ni igbesẹ tita ati rira ibo pẹlu aisi iwe akọsilẹ esi ibo.

Awọn akude yoku ni aisi awọn osisẹ ajọ eleto idibo INEC nikalẹ lasiko eto idibo naa pẹlu aisi ẹtọ fun awọn oludibo lati se ojuse wọn.

Aregbesola wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC lati wa ni alaafia, to si n fi ọwọ da wọn loju pe wọn yoo pe abajade esi ibo abẹnu naa nija.

Bẹẹ ba gbagbe, ikayasoke lo ti n waye lori ẹni ti tikẹẹti gomina lati soju ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Osun yoo ja mọ lọwọ ninu ibo abẹnu ti wọn di.

Ifigagbaga naa si lo wa laarin gomina to wa lori oye, Gboyega Oyetola ati akọwe tẹlẹ fun ijọba ipinlẹ Osun, Moshood Adeoti.

Amin iyasọtọ kan

Gboyega Oyetola borí ìbò abẹ̀nú APC láti díje ipò gómìnà Osun lẹ́ẹ̀kejì:

Gboyega Oyetọla

Oríṣun àwòrán, Osun State Government

Wọn ti kede Gboyega Oyetọla gẹgẹ bi oludije ti yoo gbe aṣia ẹgbẹ oṣelu APC nibi idibo gomina nipinlẹ Ọṣun loṣu keje ọdun yii.

Alaga igbimọ to ṣe akoso eto idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, gomina AbdulRahaman AbdulRazaq kede esi idibo naa ni owurọ ọjọ Aiku lolu ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu APC nilu Oṣogbo.

Eto idibo abẹnu oju awo lawo fii gbọbẹ, iyẹn Indirect Primaries ni APC lo ti awọn ọmọ ẹgbẹ si to si ẹyin oludije ti wọn ba fẹ tabi aworan wọn kaakiri wọọdu ọọdunrun o le ọgbọn ati meji to wa ni ipinlẹ naa.

Lapapọ, ibo ẹgbẹrun lọna okoolenigba ati meji o le mọkandinlaadọsan, 222,169 ni Gboyega Oyetọla ni, Moshood Adeoti to ṣe ipo keji ni ibo ẹgbẹrun mejila o lee ẹẹdẹgbẹrun ati mọkalelogun, 12, 921, ti oludije kẹta, iyẹn Lasun Yusuf ni ọtalerinwo (460) ibo

Akojọpọ onka awọn oludibo ti o fi orukọ silẹ jẹ 408, 697, nigba ti ibo ti wọn di si jẹ 235, 550.

fa wọn le Ọlọrun lọwọ - Arẹgbẹṣọla:

Lẹyin ti ikede ti waye pe Gboyega Oyetọla ni ibo rẹ kun ju nibi idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu APC to waye ljọ Abamẹta, gomina ana ni ipinlẹ naa, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ti rọ awọn ololufẹ rẹ ati gbogbo awọn to n tẹlee lati maṣe fa wahala rara ki wọn si fa gbogbo eyi to ku le Ọlọrun lọwọ.

Rauf Aregbesola

Oríṣun àwòrán, Aregbesola

Kii ṣe ohun to pamọ pe Arẹgbẹṣọla to jẹ minisita fọrọ abẹle bayii tako Oyetọla, koda ninu fidio kan to jade laipẹ yii nibi apero to ti fa ọwọ Moshood Adeoti soke gẹgẹbi oludije ti awn igun rẹ fẹ tẹlee ko fi ọr si abẹ ẹnu sọ lori atako rẹ si Oyetọla.

Arẹgbẹṣọla rọ awọn ọmọ igun rẹ lati tọ ọna alaafia ati ofin gbogbo lati lee yanju ẹdun ọkan wọn.

Ninu atẹjade kan eyi ti amugbalẹgb rẹ lori ọr iroyin, Ṣọla Fasure fọwọsi, O ṣalaye pe gbogbo ẹsun aṣemaṣe ti o waye lasiko idibo naa, ṣugbọn ki wọn lọ bu omi suuru mu.

"Ẹmaṣe damu, ẹ maṣe bọkan jẹ. A ṣi n yẹ awọn abọ iroyin wọnyii wo finifini, a o si gbe igbesẹ to loorin laipẹ."

Arumọjẹ patapata gba a ni idibo naa- TOP, igun APC to fara mọ Arẹgbẹṣọla:

Aworan bi esi ibo se l si

Igun ẹgbẹ oṣelu APC to fara ti gomina ana ni ipinlẹ Ọṣun, Rauf Arẹgbẹṣọla, ti tka si ibo abẹnu to waye lẹgbẹ Oṣelu APC lṣun lati yan oludije rẹ fun idibo gomina ti yoo waye loṣu keje gẹgẹ bi arumjẹ lasanlasan.

Alaga igun naa ti ọpọ mọ si 'The Osun Progressives' TOP, iyẹn Họnọrebu Rasaq Salinṣile ṣalaye lasiko to ba n awọn akọroyin sọrọ nilu Iwo pe ofutufẹtẹ ni eto naa.

O ni ṣeni awọn igbimọ apapọ ẹgbẹ oṣelu naa lẹdi apo pọ pẹlu gomina ipinlẹ naa, Gboyega Oyetọla lati ṣe arumọjẹ naa ati pe igun oun yoo gbe igbesẹ lati tako abajade eto idibo abẹnu naa.

O tọka si awọn ẹsun aṣemaṣe bii aisi orukọ ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ to fara ti wọn ninu iwe idibo ti wọn lo ati aifun awọn oludije lanfani ati ni ẹda iwe oruk awọn ọmọ ẹgbẹ to dibo ati awọn ẹsun mii ggẹ bi ara ohun to mu ki igun naa maa gbarata.

Àkọlé fídíò, Oja Odan nibi ti wọn ti dáná sún afurasi meji ti wọn ba ori eeyan lọwọ wọn

Bawo ni eto idibo abẹnu naa ṣe lọ?

Iroyin atawọn aworan to jade kaakiri awọn ibudo idibo to wa nibẹ fihan pe kẹtikẹti lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC jade wa dibo fun ẹni to wu wọn lọkan lati gbe aṣia ẹgbẹ oṣelu naa lasiko ti idibo sipo gomina ni ipinlẹ naa yoo fi waye ni loṣu keje ọdun 2022.

Awọn oludije mẹta lo n lakaka lati di aṣia ẹgbẹ oṣelu na mu nibẹ - Lasun Yusuf, Moshood Adeoti ati gomina ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetla.

Kaakiri awọn wọọdu ọọdunrun o le ọgbọn ati meji to wa ni ipinlẹ naa leto idibo abẹnu naa ti waye.

Ṣe lawọn oludibo to si ẹyin aworan awọn oludije ti wọn fẹ nitori pe eto idibo oju awo lawo fi n gb'ọbẹ 'Direct primaries' lawọn alaṣẹ ẹgbẹ naa fẹnukosi lati lo.

Awọn iroyin to jade ṣalaye pe, ni ibudo idibo rauf Arẹgbẹṣọla to n lewaju igun alatako laarin ẹgbẹ naa ni wọọdu kẹjọ nijọba ibilẹ Ila oorun Ileṣa, ibo ọọdunrun o le mẹsan an, (309) ni Gboyega Oyetọla ni ti Oludije ti Arẹgbẹṣọla fa silẹ, Moshood Adeoti si ni ibo mẹrinlelọgọfa, (124).

Ni wọọdu karun un nilu Ilobu, ti igbakeji olori ile aṣofin-ṣoju tẹlẹ, Họnọrebu lasun Yusuf ti dibo, okooleọdunrun ati mẹta, (323) ni ibo ti Oyetọla ni, Moshood Adeoti ni ibo mejilelọgọta, (62) ti Lasun gan an funrarẹ si ni mẹwaa.