Pasuma sacks manager: Ohun tí a mọ̀ nípa ìjà tó ń wáyé láàrín Pasuma Ajibola àti 'Manager' rẹ̀ rèé

Pasuma

Oríṣun àwòrán, Ididowo Mathew

Iroyin to n tẹ wa lọwọ sọ pe ija kan ti bẹ silẹ laarin gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Alabi Pasuma, ati alakoso rẹ, Mathew Ajiboye, ti ọpọ mọ si Mathew Ididowo.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ija naa ko ṣẹyin ọrọ owo kan to yẹ ki ididowo fi ṣọwọ si Pasuma ṣugbọn ti ko ṣe bẹẹ.

Iroyin ni Pasuma n mura lati ṣe awọn akanṣẹ iṣẹ kan, eyii to nilo owo fun, amọ nigba to bere owo lọwọ alakoso rẹ ọhun, alakoso ko ri owo gbe silẹ, bẹẹ si ni ko ṣalaye bi owo Pasuma to wa nmi ikawọ rẹ ṣe poora.

Owo ọhun jẹ ọkan lara awọn owo iṣẹ ode orin kan ti Pasuma ti lọ ṣere, eyii to wa lọwọ Ididowo, gẹgẹ bi alakoso rẹ.

Iroyin ni owo naa, ti iye jẹ ọpọ miliọnu naira ni Ididowo ko le ṣalaye bo ṣe poora ninu banki ti ireti wa pe o yẹ ki owo ọhun wa.

Àkọlé fídíò, Abeokuta murder

Igbesẹ naa ko dun Paso ninu, nitori Ididowo kii kan n ṣe alakoso rẹ nikan, a gbọ pe mọlebi tun ni awọn mejeeji.

Eyii lo mu ki Pasuma fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, to si fẹsun kan Ididowo pe o fi owo oun gbọ bukata ara rẹ.

Àkọlé fídíò, Segun iberu

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ididowo ti jẹwọ pe lootọ ni owo Oganla wa lọwọ oun, amọ oun n fẹ ki Pasuma jeburẹ.

O tun to wa leti pe alakoso naa ti bẹ awọn ẹbi ati ọrẹ Pasuma si i pe ko fi iye denu, amọ Oganla faake kọri pe niṣẹ ko wa owo naa jade, bi bẹẹ kọ, ko ṣetan lati foju wina ofin.

Àkọlé fídíò, OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n...

Ki ni Pasuma sọ lori iṣẹlẹ yii?

Nigba ti ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba kan si Pasuma, o kọ lati sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ naa.

Agbẹnusọ rẹ ti orukọ rẹ n jẹ "Toyin Dimpz" sọ fun BBC pe ọrọ inu ile ni ọrọ naa, kii ṣe eyii ti awọn n fẹ ko lu sita.

Àkọlé fídíò, Ìdíje ata tútù: Jẹ ata 50, ko gba góólù gírámù mẹ́ta

O ni "Ẹ má kọ nnkankan, ẹ jẹ ki a fi gbogbo rẹ silẹ, ọrọ inu ile ni."

Lẹyin naa lo ni "Mi o ni ọrọ kankan lati sọ lori rẹ."

Ta ni Mathew ididowo?

Ididowo kii ṣe ọmọde nidi iṣẹ akoso awọn olorin.

Iroyin ni oun ni alakoso Alhaji Abass Akande Obesere tẹlẹ ko to bẹrẹ si n ba Pasuma ṣiṣẹ lati nnkan bii ogun ọdun sẹyin.

Àkọlé fídíò, Yinka Ayefele: Ìrọ́ ni pé ń kò le ṣe bíi ọkùnrin, mò ń ta pútú dàadáa