Yollywood. Olanrewaju James Omiyinka: Ajẹ́rìí Bàbá Ijesha sọ fún ilé ẹjọ́ pé òun ò gbà pé fọ́nrán tí wọ́n fi léde kìí ṣe èyí tí wọ́n ti tọwọ́ bọ̀.

Baba Ijesha nile ẹjọ lonii
Àkọlé àwòrán, Baba Ijesha nile ẹjọ lonii

Ajẹ́rìí Bàbá Ijesha sọ fún ilé ẹjọ́ pé òun ò gbà pé fọ́nrán tí wọ́n fi léde kìí ṣe èyí tí wọ́n ti tọwọ́ bọ̀.

Gbajúgbajà òṣèré tíátà, James Olanrewaju tí gbogbo ènìyàn sí Bàbá Ijesha ti ní òun kò gba pé àkóónú tó wà nínú fọ́nrán CCTV tí wọ́n gbé wá sílé ẹjọ́ tako òun jẹ́ òótọ́.Òní ní Baba Ijesha tún fojú ba iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé o fí agídí bá ọmọdé lòpọ̀

Àkọlé fídíò, Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha

Elẹ́rii Bàbá Ijesha tó jẹ́ onímọ̀ nípa ṣíṣe àtúnṣe àti fífi ẹ̀rọ CCTV sílé, Adeleke Lawrence sọ èyí nílé ẹjọ́ lánàá nígbà tó ń fèsì sí ìbéèrè tí agbẹjọ́rò Bàbá Ijesha, Babatunde Ogala (SAN) bèrè lọ́wọ́ rẹ̀.

Ẹ̀sùn bíbá ọmọdé ní ìbálòpọ̀ àti ẹ̀sùn márùn-ún mìíràn tó jọ mọ́ bíbá ọmọdé lájọṣèpọ̀ ni Bàbá Ijesha ń kojú ní ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹ̀sùn ìfìyàjẹni àti ìbálòpọ̀ tó wà ní Ikeja, ìpínlẹ̀ Eko.

Kíló ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ lánàá?

Òní ní Baba Ijesha tún fojú ba iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé o fí agídí bá ọmọdé lòpọ̀.

Fọ́nrán mẹ́rin tó ṣàfihàn ohun tó ṣẹlẹ̀ lórí ẹ̀sùn bíbá ọmọdé lòpọ̀ tí wọ́n fi kan Bàbá Ijesha ni Ogala bèrè fún láti wò.

Àkọlé fídíò, Oja Odan nibi ti wọn ti dáná sún afurasi meji ti wọn ba ori eeyan lọwọ wọn

Nínú oṣù kẹrin, ọdún 2021 ni gbajúgbajà adẹ́rìnínpòṣónú Princess fẹ̀sùn kan Baba Ijesha pé ó bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tó ń gbé lọ́dọ̀ òun sùn, tó sì fi àwọn fọ́nrán mẹ́rẹ́ẹ̀rin náà lédé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn fọ́nrán náà, ajẹ́rìí Baba Ijesha ní Adeleke ní kí ènìyàn tó le kó fọ́nrán tó wà lórí CCTV sí ibòmíràn, èèyàn nílò ẹ̀rọ kọ̀mpútà àti ẹ̀rọ ìkóǹkanpamọ́sí.

Àkọlé fídíò, Ìjẹ̀bú: Àgbàlàgbà ni mo máa ń ṣe nínú eré tẹ́lẹ̀

Adeleke ṣàlàyé pé lásìkò tí ènìyàn bá ń ṣe èyí àṣìṣe le wáyé , tí ènìyàn sì tún le ṣe àyípadà sí àwọn àkóónú inú rẹ̀.

Ó ní ó dá òun lójú pé wọ́n ti ṣe àyípadà sí àwọn àkóónú inú fọ́nrán náà èyí ló fà á tó fi ń sáré ju bó ti yẹ lọ.

Bákan náà ló fi kun pé àmì "ins" tó wà lábẹ́ fọ́nrán náà ni àmì ìdánimọ̀ "In Shot" áàpù kan tó wà fún ṣíṣe àtúnṣe àti àyípadà fọ́nrán.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní ẹ̀rọ alágbéká fóònù tàbí camcoder ni wọ́n ló láti fi ya fọ́nrán ifọrọwanilẹnuwo ni ago olopaa kìí ṣe CCTV nítorí bí àwòrán fọ́nrán náà daa ju ti foonu lọ.

Àkọlé fídíò, Damilọla pàdánù ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ nítorí ilà kíkọ

Ṣùgbọ́n ó gbà pé àkóónú CCTV kò ṣé ṣe àyípadà sí tí wọ́n bá lò ó papọ̀ mọ́ Network Video Recording (NVR) àti (IP) gẹ́gẹ́ bí Dókítà Jide Martins tó peja ṣe sọ.

Àkọlé fídíò, 'Ǹkan tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọ̀nà tèmi yàtọ̀ lágbàáyé ni ǹkan tí mò ń lò'

Kí ló ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Nínú oṣù kẹrin, ọdún 2021 ni gbajúgbajà adẹ́rìnínpòṣónú Princess fẹ̀sùn kan Baba Ijesha pé ó bá ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tó ń gbé lọ́dọ̀ òun sùn.

Àkọlé fídíò, OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n...

Oṣù méjì ni Baba Ijesha lò ní àtìmọ́lé kí wọ́n tó gba ìdáǹdè rẹ̀ nínú oṣù kẹfà.

Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Baba Ijesha yìí fa awuyewuye lágbolé tíátà.

Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, @Others

Òní ní Baba Ijesha tún fojú ba iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé o fí agídí bá ọmọdé lòpọ̀

Òní ní Baba Ijesha tún fojú ba iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé o fí agídí bá ọmọdé lòpọ̀

Igbẹjọ gbajugbaja oserekunrin, Olanrewaju Omiyinka ti awọn ololufẹ rẹ mọ si Baba Ijesha tun ti foju ba ile ẹjọ lonii, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keji, ọdun 2022.

Lati nkan bii aago mẹwaa ni awọn oju to yẹ ti pe sib

Ohun ti Olanrewaju n jẹ ẹjọ naa le lori ni ẹsun ifipabanilopọ.

Ileẹjọ giga Ikeja High court ni igbejọ naa ti n waye bayii

Kini o n ṣẹlẹ nile ẹjọ bayii?

Gbogbo ijoko ti wa ni ikale bayii nile ẹjọ giga naa ti wọn n duro de Adajọ.

Won ti n ṣe atojọ awọn ẹri ti wọn fẹ gbe yẹwo lonii lori igbẹjọ Baba Ijesha ati Princess lori ọmọ to n gbe ọdọ Princess.

Baba Ijesha nile ẹjọ lonii