Algeria yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní san N41,000 fáwọn ọ̀dọ́ tí kò rí iṣẹ́ ṣe lóṣù tó ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, AFP
Ijọba orilẹede Algeria yoo bẹrẹ si ni san owo iranwọ fawọn ọdọ ti ko ri iṣẹ ṣe lorilẹede naa.
Ijọba kede pe oun ti ṣe eto lati maa ran awọn ọdọ lọwọ latari bi airiṣẹ ṣe ti pọ ni orilẹede naa.
Aarẹ Abdelmadjid Tebboune sọ fawọn akọroyin pe pe awọn ọdọ to n wa iṣẹ ti ọjọ ori wọn bẹrẹ lati ọdun mọkandinlogun si ogoji ọdun ni yoo lẹtọọ si owo naa.
- Àwọn tọ́ọ̀gì Aregbesola ló da wàhálà sílẹ̀ l'Osun - Ọlọ́pàá
- Ẹ̀kún omi gbé èèyàn méjìdínlógójì lọ nílùú Petrópolis ní orílẹ́èdè Brazil
- Olaleye Paul rí ẹ̀wọ̀n he ní àyájọ́ olólùfẹ́ ní Ilọrin
- Wo ọkùnrin kan tó fi N1.2m gbẹ́ ibojì rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tó sì wà láàyè
- Afurasí tọkọtaya ta ẹ̀yà ara ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin náírà- Ọlọ́pàá
Ẹgbẹrun mọkanlelogoji ati abọ(N41,615) tii ṣe $100 ni ijọba kede pe awọn yoo maa fawọn to koju oṣuwọn lati maa gba owo naa.
Ijọba tun sọ pe awọn ọdọ ọhun yoo tun maa jẹ anfaani eto ilera ọfẹ titi ti wọn fi maa ri iṣẹ.
Aarẹ Tebboune ṣalaye pe Algeria ni orilẹede akọkọ yatọ ilẹ Yuroopu ti yoo kọkọ ṣeto yii.
Aarẹ Algeria ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta ni awọn ọdọ ti ko ri iṣẹ ṣe ni orilẹede naa.
- Awakọ̀ dáná sun ara rẹ̀ lórí bí àwọn 'task force' ṣe mu l'Eko
- Títí di àsìkò yìí, a kò tíì mọ̀ eèyàn ti òkú náà jẹ́ ṣùgbọ́n a ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìwádìí tó yẹ Ogá Ọlọ́pàá Ogun
- Àgbáríjọpọ̀ èèyàn sẹkúpa ọkùnrin kan lórí ẹ̀sùn pé ó dáná sun Kurani
- Olùkọ́ lu akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ọmọ ọdún kan àti oṣù méje pa ní ìpínlẹ̀ Delta, O bọ́ sí gbaga ọlọ́pàá









