Lagos task force: Awakọ̀ dáná sun ara rẹ̀ lẹ́yìn tí 'task force' gbẹ́sẹ̀lé ọkọ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Lagos Monitoring Team
Awakọ kan ti a ko tii mọ orukọ rẹ ti dana sun ara rẹ lagbegbe Ajao Estate, niluu Eko.
Iroyin ni iṣẹlẹ naa waye lasiko ti awọn oṣiṣẹ igbimọ amuṣẹya ileeṣẹ to n ri si irinna ọkọ oju popo, task force, n mu awọn ọkọ kan nitosi papakọ ofurufu.
Awakọ naa, ti ọkọ rẹ wa lara awọn ti wọn gbẹsẹle kọ jalẹ fun awọn oṣiṣẹ igbimọ naa, amọ lẹyin ti wọn kọ lati tẹti si ohun to n sọ, o gbe epo bẹntiro, o daa le ara rẹ lori, o si fi ina si.
- Ìjọba Canada ṣetán láti gbẹ́sẹ̀ lé àkáùntì àwọn tó ń ṣẹ ìwọ́de táko abẹ́rẹ́ covid-19
- Afurasí tọkọtaya ta ẹ̀yà ara fún ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin náírà- Ọlọ́pàá
- Aregbẹsọla kìí ṣe Olọ́run, iṣẹ́ Oyetola ló máa fọhùn lọ́jọ́ ìdìbò- Ismail Omipidan
- Wo ohun méjé tó yẹ kí o mọ̀ nípa Abba Kyari, ọ̀gá ọlọ́pàá tí wọ́n fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn
- Títí di àsìkò yìí, a kò tíì mọ̀ eèyàn ti òkú náà jẹ́ ṣùgbọ́n a ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìwádìí tó yẹ Ogá Ọlọ́pàá Ogun
- Títí di àsìkò yìí, a kò tíì mọ̀ eèyàn ti òkú náà jẹ́ ṣùgbọ́n a ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìwádìí tó yẹ Ogá Ọlọ́pàá Ogun
- Ọmọ ọdún 18 dèrò àtìmọ́lé lórí ẹ̀sùn pẹ ó gún akẹgbẹ́ lọ́bẹ pa
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá dárúkọ àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin tó ń bá Abba Kyari ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé oògùn olóró
Olugbe agbegbe naa ti orukọ rẹ n jẹ Aliu sọ fun awọn akọroyin pe kii ṣe wahala kekere ni awakọ naa ati awọn oṣiṣẹ amuṣeya ọhun ba ara wọ fa.
O ni "Lasiko ti awọn 'task force' lọ mu awọn ọkọ to n na agbegbe papakọ ofurufu, wọn mu awọn ọkọ akero kan amọ awọn awakọ kan ba wọn fa wahala."
"Nigba ti wọn n ba iṣẹ wọn lọ ni ọkan lara awọn awakọ naa da epo bẹntiro si ara rẹ lori, to si ṣana si."
Ẹlomiran to n gbe lagbegbe ọhun to pe ara rẹ ni Kudirat sọ fun awọn akọroyin pe awakọ naa ko tii san owo ọkọ ọhun tan ki o to ko sọwọ awọn 'task force.'
Ki ni awọn agbofinro sọ?
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, CSP Adekunle Ajisebutu sọ pe kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ ọhun, Abiodun Alabi ti paṣẹ ki wọn bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.
O ni "Ohun ti a gbọ ni pe awọn oṣiṣẹ igbimọ amuṣẹya ileeṣẹ to n ri si irinkerindo oju popo atawọn awakọ kan ba ara wọn fa wahala lasiko ti wọn gbẹsẹle ọkọ wọn."
"Amọ ọrọ naa ko kan awọn ọlopaa rara. Ọlọpaa ko dana sun ọkọ kankan bẹẹ si ni awọn ọlọpaa to wa lagbegbe Aja Estate ko mọ nipa iṣẹlẹ naa."
Ẹwẹ, ẹnikan to gbẹnusọ fun ẹka to n ri si ọrọ ayika ni ipinlẹ Eko, Raheem Gbadeyinka sọ pe awọn oṣiṣẹ awọn naa ko mọ nipa iṣẹle ọhun.
















